Obìnrin aláwọ̀ dúdú àkọ́kọ́ tó fi ọ̀kadà rin ìrìnàjò káàkiri ilẹ̀ Africa

Ebaide jokoo lori ọkada rẹ

Oríṣun àwòrán, Udoh Ebaide Joy

    • Author, Parisa Andrea Qurban
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Udoh Ebaide Joy tí di obìnrin àkọ́kọ́ tó máa fi ọ̀kadà rin ìrìnàjò káàkiri ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Oṣù mẹ́ta gbáko ló gba ọmọbìnrin, ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n náà láti rin ìrìnàjò pẹ̀lú ọ̀kadà láti orílẹ̀ èdè Kenya sí ìpínlẹ̀ Eko. Ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án kìlómítà ni ìrìnàjò náà.

“Ó wù mí láti ṣe nǹkan tó dá yàtọ̀ fúnra mi, Ebaide sọ. Ó ní òun fẹ́ràn láti máa pe ara òun níjà.

Ebaide bá BBC sọ̀rọ̀ nípa ìrìnàjò rẹ̀ náà.

Ìrírí tó fun ní ìwúrí láti ṣe ìrìnàjò

 Ebaide ń wa ọ̀kadà

Oríṣun àwòrán, Udoh Ebaide Joy

Àkọlé àwòrán, Oṣù mẹ́ta ló gba Ebaide láti ṣe ìrìnàjò kìlómítà ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án

Ó ṣàlàyé pé ìpèníjà kan tí òun ní ní nǹkan bíi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn ló jẹ́ kí òun gbèrò láti rin ìrìnàjò náà.

Nígbà tó wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún ló ní ìjàm̀bá okọ̀ èyí tó ṣe àkóbá fún ọ̀pá ẹ̀yìn rẹ̀. Lẹ́yìn náà ló wà lórí kẹ̀kẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù.

“Èyí ló mú mi pinnu láti gbé ìgbé ayé tó wù mí,” Ebaide ṣàlàyé fún BBC. Ó ní ìrìnàjò káàkiri jẹ́ ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó wù òun.

Lẹ́yìn tó ṣe iṣẹ́ abẹ ló tó ní àlàáfíà, tó sì pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé tí òun bá ti kúrò nílé ìwòsàn ni òun yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àwọn nǹkan tó wu òun.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí ni Ebaide ra ọ̀kadà 250CC tó fún ní orúkọ Rory tó sì lọ kọ́ bí wọ́n ṣe ń gùn ún ní Nairobi.

Lílọ káàkiri Áfíríkà

BBC illustration showing the route taken by Ebadie. She started from Mombasa in Kenya and travelled through Uganda, Rwanda, Tanzania, Zambia, Angola, Congo, Cameroon before reaching Lagos in Nigeria

Ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù Kẹta, Ebaide bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ láti Kenya gba Uganda, Rwanda, Tanzania, Zambia, Angola, Congo, Cameroon wá sí Nàìjíríà.

Ó rin ìrìnàjò rẹ̀ gba àárín ìlú àtàwọn inú igbó kìjikìji níbi tí kò ti rí èèyàn kankan.

“Mo dúró ní àwọn ìlú kan láti mọ̀ nípa àṣà àti ìṣe wọn.

“Kìí ṣe ojoojúmọ̀ ni mo fi wà lórí ọ̀kadà, àmọ́ mo ri dájú pé mò ń rin ìrìnàjò fún ọ̀ọ́dúnrún kìlómítà ní ojoojúmọ̀.”

Àwòrán Ebaide tó ń rẹ́rìn-ín

Oríṣun àwòrán, Udoh Ebaide Joy

Ní orílẹ̀ èdè Uganda ni ó ti jẹ́ àwọn oúnjẹ tí kò le gbàgbé láyé rẹ̀.

Ó ní inú ìletò kan tó wà nínú igbó ni òun ti jẹ oúnjẹ náà.

Ohun kan tó ń ṣe ìrántí Kenya fún ni bí wọ́n ṣe kó èèyàn mọ́ra sí.

Fún Rwanda ní tirẹ̀, àwọn òkè àti bí ó ṣe nílò láti máa yí káàkiri ni àwọn nǹkan tó ń ṣe ìrántí rẹ̀ fún.

Ebaide ní Rwanda ni òun ti ríbi yí sọ́tùn-ún sósì léyìí tí àwọn tó máa ń wà ọ̀kadà máa ń nífẹ̀ẹ́ sí.

Ebaide dúró sí àárín ọ̀kadà méjì

Oríṣun àwòrán, Udoh Ebaide Joy

Àkọlé àwòrán, During her long journey, she only had one flat tyre

Dídá wa ọ̀kadà

 Ebaide dúró níwájú ọ̀kadà rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Udoh Ebaide Joy

Àkọlé àwòrán, Ebaide lo ẹ̀rọ ayélujára láti mọ àwọn ilé oúnjẹ àti ilé ìtura tó lè sùn

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú ọ̀nà ni òun gbé ọ̀kadà náà rìn síbẹ̀ ọ̀kadà òun kò fún òun ní ìyọnu títí òun fi parí ìrìnàjò náà.

Ó ní ẹ̀ẹ̀kan péré ni táyà rẹ̀ jò lójú ọ̀nà àti pé ọ̀kadà òun kò jepo rárá.

Ó sọ pé orílẹ̀ èdè DR Congo ni wáyà kan ti jóná nínú ọ̀kadà àmọ́ òun kò ní ìṣòro kankan tí òun fi dé Nàìjíríà.

Lásìkò ìrìnàjò rẹ̀, ó rí àwọn ohun mèremère bíi omi Victoria Falls tó wà ní odò Zambezi.

Àwòrán Ebaide

Oríṣun àwòrán, Udoh Ebaide Joy

Ebaide sọnù ní àwọn ibìkan bí ó ṣe ní dídá ṣe ìrìnàjò nínú igbó níbi tí òun kò ti gbọ́ èdè wọn jẹ́ ohun tó máa ń kó ìbẹ̀rù bá òun.

“Ẹ̀rù máa ń bà mí. Mo máa ń rìn díẹ̀ díẹ̀ tí mo bá ti dé àwọn ọ̀nà tó tẹ̀ nítorí mi ò mọ nǹkan tí mà á rí níwájú.”

Ó sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun mú àtíbàbà dání láti máa fi sùn ni ojú ona ṣùgbọ́n láti ìgbà tí òun ti dé Kampala ni òun ti bẹ̀rẹ̀ sí ní sún ilé ìtura nítorí àti jìnà sí ewu.

Lásìkò tí ìrìnàjò rẹ̀ ń lọ lọ́wọ́ ló fi ohun èlò àti fi máa sùn ránṣẹ́ sílé láti dín ẹ̀rù rẹ̀ kù.

“Aṣọ, kọ̀m̀pútà àtàwọn nǹkan tí mo nílò jùlọ ni mo máa ń gbé dání tí mo bá ń lọ sí ìrìnàjò.”

Ó ní òun kàn sí àwọn tó máa ń gun ọ̀kadà bíi ti òun tí wọ́n júwe ọ̀nà fún òun – èyí tó ní ó mú ìrìnàjò náà rọrùn fún òun.

Ó ṣàlàyé pé máàpù àti ìkànnì ayélujára ni òun lò láti fi mọ ọ̀nà àtàwọn ibi tí òun ti máa rí oúnjẹ jẹ.

Ebaide dúró sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀kadà rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Udoh Ebaide Joy

Àkọlé àwòrán, Inú Ebaide dùn láti mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn àti láti rí àwọn ibi tó rẹwà

Ìrìnàjò mìíràn

Ebaide ní òun kò ní ìrírí aburú kankan nínú ìrìnàjò náà. Ó ní ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ mọ̀ nípa ọmọbìnrin tó ń gun ọ̀kadà kiri.

Gbogbo bí ìrìnàjò Ebaide ṣe ń lọ ló ń fi sórí ayélujára.

Nígbà tó dé sí Eko, ijó àti ẹ̀yẹ ni wọ́n fi pàdé rẹ̀.

“Mi ò rí ẹkún mi pa mọ́ra nígbà tí wọ́n wá fi ijó pàdé mi, inú mi dùn púpọ̀.

Ó ní ìrìnàjò náà ti kọ́ òun pé kò sí ìpèníjà tí òun kò lè kojú àti pé lásìkò ìrìnàjò náà ni òun gbádùn ayé òun jùlọ.

Bákan náà ló ní òun ti ń múra láti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò mìíràn láti Nàìjíríà lọ sí orílẹ̀ èdè Morocco.

Ó ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹjọ ni ìrìnàjò lọ sí Morocco náà yóò bẹ̀rẹ̀.