Àṣeyọrí ńlá ni sísan N70,000 owó oṣù òṣìṣẹ́ fún ìjọba Tinubu - Wale Edun

Aworan Wale Edun ati Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Minisita fun eto iṣuna lorilẹede Naijiria, Wale Edun ti kan sara si Aarẹ Bola Tinubu fun bi o ṣe ṣe aṣeyọri pẹlu ijiroro lori owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ.

Edun ṣapejuwe igbesẹ naa gẹgẹ bii aṣeyọri nla fun iṣejọba Aarẹ Bola Tinubu, to si ni pe o fi ni lọkan balẹ pe atunṣe yoo de ba eto ọrọ aje laipẹ, ti gbogbo araalu yoo si kuro ninu isẹ.

Minisita feto isuna sọ eyi nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ aadọrin ọdun idasilẹ ileẹkọ girama Loyola College nilu Ibadan, eyi to waye niluu Eko lopin ọsẹ.

O ṣalaye pe ijiroro nipa owo oṣu tuntun fun awọn oṣisẹ lo ti wa fun igba pipẹ, to si jẹ pe isẹ nla ni ijọba se lati ri pe awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ faramọ adehun naa.

"Otitọ ni pe ipenija ọrọ aje wa ni Naijiria amọ mo gbagbọ pe ijọba Tinubu yoo wa ojutu si"

“Mo ni lati kan saara si Aarẹ fun ipa to ko ninu ijororo ati awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣisẹ.”

Edun ni o ti otitọ ni pe ipenija ọrọ aje wa lorilẹede Naijria sugbọn o ni oun gbagbọ ninu iṣejọba Bola Tinubu lati pe atunṣe si ipenija naa.

O ni ijọba ti bẹrẹ si ma gba awọn igbesẹ nla ti yoo wa ojutu si awọn iṣoro yii

Bẹẹ ba gbagbe apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC ti fẹnuko pẹlu ijọba apapọ lori owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.

Ni ọsan Ọjọbọ ọjọ kejidinlogun oṣu Keje yii ni oludamọran aarẹ Bola Tinuba lori ọrọ iroyin ati ọgbọn inu, Bayo Onanuga kede pe aarẹ ti buwọlu ẹgbẹrun un lọna aadọrin naira(N70,000) gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.

Ninu atẹjade ti Onanuga fi sita, o ṣalaye pe Aarẹ Tinubu ṣeleri lati maa ṣe ẹkunwo owo oṣu awọn oṣiṣẹ lọdun mẹta mẹta.

Ṣaaju ipade Ọjọbọ pẹlu Tinubu, N250,000 ni aarẹ NLC, Joe Ajaero ati akẹgbẹ rẹ ti TUC, Festus Usifo sọ pe awọn fẹ gba.