Ìdí rèé tí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan yóò fi gbowó ìfẹ̀yìntì ṣáájú kí wọ́n tó fẹ̀yìntì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iwadii fihan pe awọn oṣiṣẹ ijọba kan, ti wọn ko ti lo iye ọdun to yẹ ki wọn lo lẹnu iṣẹ ijọba ki wọn to fẹyinti ti n gba lara owo ifẹyinti wọn nitori bi kudiẹkudiẹ se ba eto ọrọ aje lọwọ yii.
Iwe ofin owo ifẹyinti ti ọdun 2014 faaye gba awọn oṣiṣẹ ijọba lati gba ida mẹẹdọgbọn ninu owo ifẹyinti wọn, ti wọn ba le wọn kuro lẹnu iṣẹ tabi kọwe fi iṣẹ silẹ, ti wọn si wa fun oṣu mẹrin lai ri iṣẹ mii, ti iye ọjọ ori wọn ko si ti de aadọta.
Bakan naa, ofin naa tun faaye gba awọn oṣisẹ lati gba diẹ lara owo ifẹyinti wọn fi ra ile.
Ajọ to n risi owo ifẹyinti lorilẹede Naijria ni o to 443,720 oṣiṣẹ ti wọn ti gba diẹ lara owo ifẹyinti, ti iye owo rẹ jẹ 182.19Bn lati igba ti wọn da ajọ naa silẹ ni ọdun 2004 si ọdun 2022.
Iwadii kan to jade ni ajọ to n risi owo ifẹyinti fihan pe, o le ni ẹgbẹrun mẹwaa oṣiṣẹ to ti padanu iṣẹ wọn to gba o le ni bilọnu meje naira ni oṣu mẹrin akọkọ ni ọdun 2023.
Ki ni idi ti awọn oṣiṣẹ fi n gba ida diẹ ninu owo oṣu wọn
Onimọ kan lori owo ifẹyinti lorilẹede Naijiria ti ko fẹ da orukọ rẹ sọ fun BBC pe, idi mẹta lo ma n fa a ti awọn oṣiṣẹ ti wọn ko ti pe iye ọjọ ori to yẹ ki wọn fẹyinti fi n gba diẹ lara owo ti wọn n fi pamọ.
Kudiẹkudiẹ eto ọrọ aje: Ọpọ awọn oṣiṣẹ ti wọn fi tipatipa bere ida mẹẹdọgbọn owo ifẹyinti wọn jẹ awọn to ti padanu iṣẹ wọn tabi kọwe fi iṣẹ silẹ.
Awọn to fẹ ni owo: o ni awọn oṣiṣẹ kan fẹ gba ida mẹẹdọgbọn yii nitori wọn fẹ ra ile sugbọn ti wọn yoo lo owo naa fun nnkan mi nitori kudiẹkudiẹ ọrọ aje to wa nita.
Awọn to tako ajọ to n risi owo ifẹyinti: Awọn oṣiṣe kan ti nnkan ti ajọ to n risi owo ifẹyinti n ṣe ko tẹlọrun, to si jẹ pe ti wọn ba ri aaye, wọn yoo ko owo wọn kuro. Fun idi eyi, wọn ma lo anfaani yii lati ko ida mẹẹdọgbọn ninu owo ifẹyinti wọn.
Bawo ni wọn se ma n gba owo lati ra ile gbe
Onimọ, ẹni to jẹ oṣiṣẹ ni ọkan lara ileeṣẹ to n risi owo ifẹyinti ni “Bayii, ninu eeyan mẹwaa to ma ba wa pe wọn fẹ gba ida mẹẹdọgbọn, mẹfa ninu wọn wa fun owo yii lati san owo ile.
“Ewẹ, iwadii fihan pe pupọ awọn eeyan n lo anfaani yii lati fi gba owo wọn sita lori irọ pe wọn fẹ ra ile gbe.
“ Nnkan ti wọn se ni pe wọn yoo sisẹ pọ pẹlu ileeṣẹ ifowopamọ wọn pe ko pese PMI ati ẹri pe wọn fẹ ra ile , ti wọn yoo si ko gbogbo awọn iwe ẹri wa, ti a si fun wọn ni owo naa nigba ti a ba ti ri iwe ẹri.
Mo ti gba temi naa
Oṣiṣẹ kan ti ko fẹ da orukọ rẹ sọ fun BBC pe oun naa ti gba ida mẹẹdọgbọn owo ifẹyinti rẹ.
“Mo ti gba temi, mo si mọ awọn eeyan mi ti awọn naa ti n gbe igbesẹ lati gba owo naa fi san owo ile.
“Iṣoro ibẹ ni pe ti o ba gba owo yii, o le yi ipinnu rẹ pada lati fi se nnkan mi bi okowo.”
Ki ni atubọtan awọn to gba owo ifẹyinti wọn saaju ifẹyinti?
Onimọ ni bo ti lẹ jẹ pe ofin ọdun 2014 nipa owo ifẹyinti faaye gba awọn oṣiṣẹ lati gba ida mẹẹdọgbọn ninu owo ifẹyinti wọn, o ni “o ni awọn atunbọtan fun awọn oṣiṣẹ.”
“Iṣoro nla ni ti ijọba ko ba wa nnkan se si isẹ ati wahala fun awọn oṣiṣẹ fẹyinti. O da bi pe wọn kan fi akoko sofo to ba jẹ pe wọn ti gba ọpọ owo jade ninu owo ifẹyinti wọn.”
Ki ni ọna abayọ?
Onimọ ni ọna abayọ ni ki ijọba bẹrẹ si ma mojuto nnkan ti awọn oṣiṣẹ ni awọn n fi owo yii se.
Ẹwẹ, o fikun pe ijọba ti bẹrẹ si se idanilẹkọ fun awọn oṣiṣẹ to ba fẹ gba owo wọn ati fun awọn ile ifowopamọ to ba fẹ ba wọn gba owo yii ati awọn ileeṣẹ to n risi owo ifẹyinti.
“Fun apẹẹrẹ, ti oṣiṣẹ ijọba ba gba ida mẹẹdọgbọn ninu owo ifẹyinti rẹ, ti iwadii si fihan pe ko lo owo naa fun nnkan to fẹ fi ṣe, to si jẹ pe o kan na owo naa ni. O yẹ ki ijọba fiya jẹ, ki wọn o si ma fun lowo.
“Ki ijọba tun wa fiya jẹ awọn ileeṣẹ ifowopamọ ati ileeṣẹ to n ri si owo ifẹyinti.”















