Ìwádìí ìjìnlẹ̀ rèé nípa Ìjàpá, bó ṣe ń ní ìmọ̀lára àyíká rẹ̀, bó ṣe ń dunnú tàbí gbèrò ohun rere bí èèyàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Holly Phillips
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ijapa tiroko ti ọrọ gbogbo ki i se lori rẹ gbọn pupọ, gẹgẹ bi awọn itan ati alọ aye ọjọun ṣe sọ fun wa.
Ṣugbọn awọn oniṣẹ iwadii kan lati University of Lincoln, tun ti fidi ẹ mulẹ, pe ijapa maa n mọ ohun to ba n ṣẹlẹ bi awa ẹda eeyan.
Awọn oniwadii naa ṣalaye pe ijapa maa n dunnu, wọn si maa n ni ireti ohun rere.
Iwadii ti fi han pe awọn ijapa ti awọ ẹsẹ wọn pupa maa n pẹ gan-an ninu ohun to ba n ṣe wọn, eyi to jẹ ìṣe awọn abo ẹranko ati awọn ẹyẹ.
Agbẹnusọ yunifasiti kan fi kun un pe, iwadii yii yoo ran awọn to ba n tọju ẹranko ti wọn ba mu si igbekun lọwọ, lati mọ bi wọn yoo ṣe maa tọju wọn.
Ọjọgbọn Oliver Burnman, onimọ nipa iṣesi ẹranko ati alaafia wọn, ṣalaye pe abajade iwadii yii yoo mu iyatọ nla wa nipa bi a ṣe le mọ nipa awọn ẹranko afayafa daadaa.
'Ìjàpá fẹ́ràn láti máa wà níbi tó ti lè ronú'
Ikọ oniwadii mẹẹẹdogun kan ṣe iwadii nipa awọn ijapa ẹlẹsẹ pupa, awọn ti a mọ si 'chelonoidis carbonaria' - wọn lo ilana ayẹwo ọgbọn ori kan ti wọn saba maa n lo fun awọn ẹranko to n ṣe abiamọ ati awọn ẹyẹ.
Wọn ṣayẹwo nipa bi awọn ẹranko ṣe maa n huwa si awọn nnkan ti ko ye wọn.
Abọ iwadii naa fi han ijapa fẹran lati maa wa ni agbegbe to ti le ronu, ko si le huwa ni ibamu pẹlu agbegbe naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Ijapa le ronu daadaa, wọn ko si ni idaamu tabi ibẹru kankan"
Awọn onimọ naa tun ṣe iwadii mi-in nipa gbigbe ijapa si agbegbe ati awọn nnkan ti ko ri ri tẹlẹ.
Abọ rẹ ni pe, ijapa to le ronu daadaa nibi ayẹwo ọlọgbọn ori akọkọ ko ṣe akitiyan kankan, wọn ko si daamu tabi ni ibẹru kankan.
Agbẹbusọ kan lati University of Lincoln,ṣalaye pe iwadii yii fi han pe awọn ẹranko naa maa n pẹ ninu ohun ti wọn ba n mọ lara lasiko kan (long-term mood state)
Ofin to n ri si alaafia awọn ẹranko (Act 2022) sọ pe awọn ẹranko naa ni agbara lati mọ nnkan lara, eyi to fa a ti ofin naa fi n da aabo bo wọn.
Ọjọgbọn Anna Wilkinson, ẹni to kẹkọọ nipa ọpọlọ awọn ẹranko ni yunifasiti, ṣalaye pe, "Idi ti ofin fi wa fun aabo ati itọju awọn ẹranko naa ni pe awọn naa anfaani lati mọ ohun to ba n ṣẹlẹ si wọn nibi ti wọn ba wa.
" Pẹlu awọn ẹranko afayafa ṣe n di nnkan ti wọn n sìn nile bayii, o ṣe pataki fun wa lati maa mọ ipo ti wọn wa ati ohun to n ṣe wọn. Ka le baa mọ bi igbekun ṣe maa n ri lara wọn"














