Kí ló dé tí Bello Turji, ògbóǹtagí agbébọn tó ń da ẹkùn àríwá láàmú, ṣe fẹ́ parí ìjà pẹ̀lú ìjọba?

Oríṣun àwòrán, FB/Sheik Ahmad Gumi
Ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí ni fídíò gbajúmọ̀ agbébọn tó ti ń da ẹkùn àríwá Nàìjíríà láàmú láti ọjọ́ pípẹ́ gba orí ayélujára níbi tó ti ń pè fún ìparí aáwọ̀ láàárín òun àti ìjọba.
Lòdì sí báwọn fídíò rẹ̀ tó ti máa ń ṣe ṣáájú – níbi tó ti máa ń mú ìbọn lọ́wọ́, tó sì máa ń dínkokò mọ́ ìjọba – pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ló fi ń sọ̀rọ̀ nínú fídíò náà.
Turji, nínú fídíò náà wọ aṣọ ológun pẹ̀lú àwọn èèyàn méjì míì ọ̀kan lápa ọ̀tún tí ẹnìkejì sì wà lápá òsì rẹ̀.
Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn tí iléeṣẹ́ ológun Nàijíríà sọ pé ìwà ìgbéṣùmọ̀mí ń peléke si, tí wọ́n sì kéde láìpẹ́ yìí pé àwọn ti ṣekúpa èèyàn kan tó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Turji, Kachalla Yellow Danbokolo.
Turji jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbébọn gbòógì tí àwọn aláṣẹ Nàìjíríà ti kéde pé àwọn ń wá, tó sì ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkọlù sáwọn ìlú ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà, gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn, da ètò ọgbìn ọ̀pọ̀ ìlú fi ń ṣe ọrọ̀ ajé rú.
Kí ni Turji sọ nínú fídíò náà?
Nínú fídíò náà, tí onímọ̀ nípa ètò ààbò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Keje ló ṣe é, Turji sọ pẹ̀lú ohùn ìrẹ̀lẹ̀ pé "A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nínú ipò tí a bá ara wa nínú irú ipò báyìí.
"Àwọn tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run fẹ́ ṣe wá ní ìjàmbá ṣùgbọ́n a borí wọn, a wà ní àlááfíà."
Bákan náà ló sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rẹ́ rẹ̀ Kachallah Danbokolo táwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò pa.
Ó sọ pé òun ń kàn sí ìjọba láti jẹ́ kí àwọn máa gbé papọ̀ pẹ̀lú àlááfíà, pé ọmọ orílẹ̀ èdè yìí kan náà ni gbogbo wa, kí wọ́n máa ṣe déédéé.
Ó ní àwọn ti ṣetán láti jọ̀wọ́ gbogbo ohun ìjà ọwọ́ àwọn fún ìjọba kí wọ́n jẹ́ kí àwọn jọ máa gbé papọ̀ láì sí wàhálà kankan.
"À ń ké pe ìjọba àpapọ̀ àti ìjọba ìpínlẹ̀ Zamfara kí wọ́n wo gbogbo ìpànìyàn tó ń wáyé yìí, ó tó gẹ́.
"A ní ìrètí pé ìjọba máa fún àwọn èèyàn tí wọ́n ń tẹ ẹ̀tọ́ wọn lójú mọ́lẹ̀ ní àǹfàní kí àlááfíà lè wà, kí wọ́n lè lọ máa dá oko wọn, ṣe òwò wọn, kí gbogbo èèyàn lè máa lọ síbi tó bá wù wọ́n.
"Mo lérò pé gómìnà máa gbọ́ àgbọ́yé ìpè yìí," Turji sọ nínú fídíò náà.
Ẹ̀wẹ̀, láìpẹ́ yìí ni gómìnà ìpínlẹ̀ Zamfara, Dauda Lawal ti sọ pé òun kò ní ní àjọṣepọ̀ kankan pẹ̀lú àwọn agbébọn.
Ṣíṣe ìjíròrò pẹ̀lú àwọn agbébọn wà lára àwọn nǹkan tó ń fa àríyànjiyàn ní àwọn ìpínlẹ̀ tó ń kojú ìpèníjà ààbò ní Nàìjíríà.
Kí ló dé tí Turji ń bèèrè fún ìparí aáwọ̀ láàárín òun àti ìjọba?
Onímọ̀ nípa ètò ààbò ní Nàìjíríà, Mannir Fura Girke sọ pé ìdí tí Turji fi ń bèèrè ìparí aáwọ̀ kò ṣẹ̀yìn tó ń bi pé àwọn ẹ̀ṣẹ́ ààbò ń ṣekúpa àwọn èèyàn rẹ̀.
Ó ní ó jẹ́ ohun láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé iléeṣẹ́ ológun ń ṣe àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ní àwọn ń ṣe.
Fura Girke ní Turji kò lè ṣe ìkọlù sáwọn ibi tó máa ń ṣe ìkọlù sí tẹ́lẹ̀ àti pé gbogbo àwọn tó ń ṣe ìrànwọ́ fún-un ni ìjọba ti fẹ́ pa tán.
"Tí ó ba ṣe kọjá ààyè rẹ̀, ó máa dá ara lẹ́bi, ìdí nìyí tó fi gbọdọ̀ wá ọ̀nà láti bá ìjọba jíròrò lórí ọ̀nà tí wọ́n fi máa foríjì í.
Onímọ̀ náà fi kun pé pípa Kachalla Danbokolo jẹ́ àdánù ńlá fún Turji nítorí Danbokolo burú ju Turji lọ.
Ṣé ó yẹ kí ìjíròrò wáyé láàárín Turji àti ìjọba?
Mannir Fura Girke sọ pé kò yẹ kí ìjọba gba Bello Turji gbọ́ rárá nítorí ọ̀pọ̀ ìgbà ni wan tib á jíròrò tó sì ń yẹ àdéhùn.
"Ní ọdún 2021, Sheikh Ahmad Abubakar Gumi ṣaájú àwọn tó lọ ba jíròrò àmọ́ kò so èso rere.
"Bákan náà ni ìjọba àná lábẹ́ gómìnà Bello Matawalle tib á jíròrò lọ́pọ̀ ìgbà ṣùgbọ́n tó máa yẹ àdéhùn wọn.
"Mi ò rò pé nǹkan tó bójúmu ni láti tún ba jíròrò mọ́," onímọ̀ náà sọ.
Ta ni Bello Turji?
Ní ìjọba ìbílẹ̀ Shinkafi ní ìpínlẹ̀ Zamfara tó pààlà pẹ̀lú ìjọba ìbílẹ̀ Isa ní ìpínlẹ̀ Sokoto ni wọ́n ti bí Muhammadu Bello tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Kacalla Turji.
Ẹkùn Shinkafi àtàwọn ìlú Isa pati Sabon Birni ní ìpínlẹ̀ Sokoto kò jìnà síra rárá.
Ní Shinkafi ló dàgbà sí, tí bàbá rẹ̀ sì máa ń da ẹran lọ sóko àwọn tó ń ta ẹran gẹ́gẹ́ bí Dókítà Murtala ṣe sọ.
Ìwádìí Dókítà Murtala sọ pé ọjọ́ orí Turji wà láàárín ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) sí ọdún márùndínlógójì (35).
Bàbá rẹ̀, Usman tó gbajúmọ̀ bíi Mani ti Mareke ló jẹ́ àgbà oníṣòwò nǹkan ọ̀sìn ní agbègbè náà, tó sì máa ń wá àlááfíà láàárín àwọn àgbẹ̀ àti darandaran.
Ìyá rẹ̀, tí wọ́n mọ̀ sí obìnrin Kagara – láti ẹkùn Isa – ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú abẹ́sinkáwọ́ Turji, Danbokolo.















