"Àwọn agbébọn ya wọ ìpàdé ọmọ onílùú, pa èèyàn mẹ́wàá, àmọ́ a móríbọ́ torí wọ́n rò pé gbogbo wa ti kú"

Awọn eeyan ti ori ko yọ ninu iṣẹlẹ iṣekupani nibi ti eeyan mẹwaa lati ipinlẹ Ebonyi ti padanu ẹmi wọn ba BBC sọrọ.
Iṣẹlẹ yii waye niluu Ogboli ni guusu ijọba ibilẹ Orumba nipinlẹ naa, lasiko ti awọn eeyan kan ko ara wọn jọ lati ṣe ipade ọmọ ilu kan nibẹ.
Alaga idagbasoke ipinlẹ Ebonyi, Augustine ṣalaye fun BBC bi ori ṣe ko wọn yọ ati bi awọn agbebọn ṣe ṣekupa eeyan mọkanla, lasiko ipade naa to waye ni Ogboji nipinlẹ Anambra.
Odom sọ fun BBC pe ni lasiko ti awọn fẹ sa kuro nibi ipade naa ni awọn agbebọn yawọ ibi ti ipade ti n waye ninu ọkọ Sienna.
"Nigba ti awọn agbebọn yii de, ohun akọkọ ti wọn se ni pe, wọn gba ohun akọsilẹ wọn ati owo ti wọn dajọ nibi ipade naa."
"Lẹyin ti wọn wo akọsilẹ wa, wọn beere pe ta ni alaga ẹgbẹ wa, ti ẹni kẹni ko si le sọrọ.
"Won mu ọkan lara wa, ti wọn si bẹrẹ si ni ma lu ko to di pe o na wọ si mi pe emi ni olori."
Augustine Odom ni oun sọ fun wọn pe oun ki n ṣe olori, ti wọn si ni ki gbogbo doju bolẹ.
"Wọn bẹrẹ sini ma pariwo pe a n ṣe ipade lori wọn.
"Ohun ti ma gbọ ni pe, 'Ẹ pa gbogbo wọn', ti wọn si sina bolẹ, ọkan ninu wọn wa fi ọwọ kan wa lati mọ boya gbogbo wa ti ku ni tootọ.
"Wọn kuro ni agbegbe naa ni igba ti wọn ro pe a ti ku, ṣugbọn awọn eeyan wa doola ẹmi wa nigba to ya."
Ọkunrin miiran ti ori ko yọ, Elon Hyacinth, ba BBC sọrọ lori ohun ti oju rẹ ri.
Elon ni oun ti ṣaaju awọn yooku kuro nigba oun gboro ibọn kete ti oun kuro nibẹ.
Hyacinth ni, "Mo pe eeyan meji ninu ẹgbẹ wa, ti mo si sọ fun wọn pe nnkan ṣe mi. Wọn ni ki ma lọ."
"Bi mo ṣe n kuro, mi o ti gbe ẹsẹ meji, ti mo fi gboro ibọn. Mo pe awọn to wa nibi ipade ṣugbọn won ko gbe ipe wọn.
"Ko pẹ ni mo gbọ iroyin pe awọn agbebọn ṣekupa awọn eeyan wa. Nigba ti mo de si ibẹ, mo ri oku eeyan mọkanla ni ilẹ."
"Awọn to farapa yanayana ni wọn ti gbe lọ si ile iwosan."
Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ?

Oríṣun àwòrán, Anambra Police Command
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Anambra ti kede pe ọwọ ti tẹ ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Sunday Mbanu lori ẹsun iṣekupani eeyan mẹwaa ti wọn jẹ ọmọ ipinlẹ Ebonyi nipinlẹ Anambra.
Sunday Mbanu ni wọn fẹsun kan o siṣẹ papọ pẹlu awọn agbebọn to kọlu awọn oloogbe naa lasiko ipade to ṣekupaa awọn eeyan mẹwaa.
Ọlọpaa ni Sunday Mbanu n ṣe iranlọwọ fun wọn lori iwadii ati lati le mu awọn agbebọn naa.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Tochukwu Ikenga fi lede, o ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyi to b ani lọkan jẹ pupọ.
Ikenga ni awọn agbebọn naa yawọ ibi ipade naa pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ meji, ti wọn si sina bolẹ fun araalu.
O ni ọpọ eeyan lo padanu ẹmi wọn, ti ọpọ si tun farapa yanayana lasiko ikọlu naa.
"Awọn ti wọn farapa ni wọn ti wa ni ile iwosan, ti eeyan mẹwaa si ti padanu ẹmi wọn.
O fikun ohun to fa ikọlu ni ko ti yẹ wọn, ti ẹnikẹni ko si ti sọrọ pe awọn ni awọn wa nidi ikọlu naa.
Ki ijọba ipinlẹ Ebonyi sọ lori iṣẹlẹ yii?
Ijọba ipinlẹ Ebonyi ti bu ẹnu atẹlu iṣẹlẹ to ṣekupa ọmọ ipinlẹ naa mẹwaa ni Ogboji nijọba ibilẹ Guusu Orumba nipinlẹ Anambra.
Gomina ipinlẹ naa, Francis Ogbonna Nwifuru, ti wa pe fun idajọ ododo ati pe ki ọwọ si tẹ awọn agbebọn to ṣe iṣẹ laabi yii.
O ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ eyi to gba omije loju ẹni, to si jẹ ikọlu si alaafia araalu.
"Ohun to wọpọ laarin awọn eeyan wa ni ki a jọkoo fun ijiroro alaafia. Mo bu ẹnu atẹlu ohun to waye yii."
Gomina Nwifuru sọ eyi ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ Monday Uzor, fi lede lọjọ Isẹ gun lọjọ Kinni oṣu Kẹjọ ọdun 2025.
Gomin ani oun ati akẹgbẹ rẹ, Gomina Charles Chukwuma Soludo ti ipinlẹ Anambra, ti pinnu pọ layi ṣe iwadii lati ṣawari awọn agbebọn yii, ki wọn si fi oju wọn jo ofin.
O ni ti eyi ko ba waye, o ṣeeṣe ko ba ajọsepọ ipinlẹ mejeeji jẹ.
Ijọba ipinlẹ Anambra sọrọ sita
Ijọba ipinlẹ Anambra ti ni oun n saa gbogbo ikapa rẹ lati ran ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ ṣawari awọn agbebọn to ṣekupa awọn eeyan ipinlẹ Ebonyi.
Kọminsana fun eto iroyin nipinlẹ naa, Law Mefor, lo sọ eyi fun BBC nigba ti a kan si lọjọ Keji oṣu Keje ọdun 2025.
O ni ko si nnkan to jẹ mọ pe ikọlu naa waye nitori ipinlẹ Anambra korira awọn ipinlẹ Ebonyi ati ipinlẹ Anambra lo gba alejo awọn ipinlẹ Ebonyi ju lorilẹede Naijiria.
"Anambra da b ilu oyinbo fun awọn eeyan ipinlẹ Ebonyi to n gbe nibi bayii. Wọn n gbe pẹlu wa, ti wọn si n ṣe daada.," Mefor ṣalaye.















