Ìjà ní ààfin! Jàǹdùkú ya wọnú ààfin, já ìlẹ̀kùn, ṣe ẹ̀ṣọ́ aláàbò léṣe, ba ọ̀pọ̀ dúkìá àti ọkọ̀ ọlọ́pàá jẹ́

Aworan Aminu Ado ati Muhammadu Sanusi

Oríṣun àwòrán, Kano State Government/Mai Katanga Photography

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Rogbodiyan nla lo waye ni aafin ilu Kano, bi awọn janduku kan, ti wọn gbagbọ pe wọn jẹ ololufẹ Emir tẹlẹ ni Kano, Ado Bayero, se kọlu aafin Rumfa ni ẹnu ọna guusu aafin.

Atẹjade kan ti aafin Emir ti ilu Kano, Emir Muhammadu Sanusi II, fi sita lo fi idi isẹlẹ naa mulẹ.

Atẹjade naa ni awọn janduku ọhun ya wọ aafin lẹyin ti wọn ja ẹnu ọna abawọle, ti wọn si ṣe ẹsọ alabo kan ni aafin lese.

Bakan naa ni wọn ni awọn tọọgi naa tun ba ọpọ ọkọ ayọkẹlẹ ileeṣẹ ọlọpaa to wa ninu aafin jẹ.

Awọn janduku yii ni wọn kọlu aafin, lasiko ti Emirtẹlẹ, Aminu Ado Bayero, n gba oju ọna to wa niwaju aafin kọja, lẹyin to ṣe abẹwo si ile oloogbe Alhaji Aminu Dantata.

Iṣẹlẹ yii ni ọpọ gbagbọ pe o jẹ itẹsiwaju ija to wa laarin Emir Muhammadu Sanusi keji ati Emir tẹlẹ, Aminu Ado Bayero.

Rogbodiyan naa lo ti bẹrẹ lati igba ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kano, ti gba agbara ati ipo lọwọ Aminu Ado Bayero gẹgẹ bii Emir Kano, ti wọn si gba ipo naa pada fun Sanusi.

Aworan Emir Sanusi

Oríṣun àwòrán, Kano State Government

Ki ni aafin Emir Sanusi sọ nipa iṣẹlẹ yii?

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ aafin Emir Sanusi, Saddam Yakasai, buwọlu fun awọn akọroyin, o fẹsun kan Emir Aminu Ado pe o lọwọ ninu ikọlu to waye ni aafin Gidan Rumfa.

Aafin ni, "Awọn janduku to wa lati ọdọ Aminu Ado Bayero, ya wọ aafin Rumfa Palace, ja ilẹkun, kọlu ẹsọ alaabo, ba ọpọ dukua jẹ, to fi mọ ọkọ aafin.

Atẹjade naa ni Emir Aminu mọọmọ gba ọna aafin naa kọja ni, lati le fun awọn eeyan rẹ ni anfani lati kọlu aafin nigba to n bọ lati ile oloogbe Aminu Alahassan Dantata to ti lọ ṣe abẹwo ibanikẹdun.

Igun Sanusi ni ki i ṣe igba akọkọ ree ti Aminu Ado Bayero yoo gba ọna yii kọja, to si ma n lo eyi lati fi tọ suuru awọn eeyan adugbo naa.

Aworan Emir Ado Aminu

Oríṣun àwòrán, Mai Katanga Photography

Emir Aminu Ado fesi

Igun Aminu Ado Bayero ti wọgile ẹsun ti wọn fi kan wọn pe wọn kọlu aafin Gidan Rumfa, aafin ti Emir Muhammadu Sanusi keji n gbe.

Igun Aminu Ado Bayero ni ki i ṣe igba akọkọ ree ti oun yoo gba ọna yii kọja, ti nnkankan ko si ṣẹlẹ ri.

Aminu Dan Agundi to fọwọsi atẹjade naa ni, "A lọ si ile Alhaji Aminu Dantata lati lọ bu ọla ikẹyin fun.

A gba ọna yii lọ si inu ilu. A gba ọna aafin Rumfa. Wọn ti lọ gba awọn janduku, bi a ṣe n kọja, ni wọn bẹrẹ si ni ma sọ oko mọ awọn eeyan.

"Bi awọn eeyan wa ṣe ri eyi, ni wọn bẹrẹ si ni ma le wọn, fọnran wa ti gbogbo wa ri," Dan Agundi ṣalaye.

"Ohun ti wọn sọ ni o jẹ irọ to jina si otitọ, ti wọn si mọ," Dan Agundi sọ fun BBC.

Ki lo ṣẹlẹ saaju?

Ni ọdun to kọja, Ijọba ipinlẹ Kano da Sanusi Lamido Sanusi pada sipo emir ilu Kano, lẹyin ti o rọ Aminu Ado Bayero loye.

Igbesẹ yii waye lẹyin ti gomina Kabir Yusuf ipinlẹ Kano buwọ́lù ofin tuntun ọdun 2024 to n ri ipo awọn lọbalọba.

Bakan naa ni ile aṣofin ipinlẹ Kano tu ikangun marun ọba jijẹ niluu Kano eyi ti ijọba ṣe agbekalẹ rẹ lọdun 2019.

Lẹyin ibuwọlu ofin tuntun naa ni gomina kede Sanusi gẹgẹ bi Emir Kano kẹrindilogun ti o ṣi rọ Ado Bayero loye.

Igbesẹ yii tumọ si pe oye ẹbi l'ọba lọba Gaya, Bichi, Karaye ati Rano ti tuka bayii.

Ni ọdun mẹrin sẹyin ni gomina ana ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje yọ Sanusi nipo emir.

Aigbọran si ijọba wa lara idi ti Ganduje lo ṣe rọ Sanusi loye