Kí ló dé tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC tún ń dúnkokò láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ilẹ̀ Nàìjíríà, NLC ti dúnkokò láti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì látàrí ètò ààbò tó mẹ́hẹ, ìṣẹ́ àti òṣì tó ń bá àwọn èèyàn fínra àti ọ̀wọ́gógó tó gbilẹ̀ ní Nàìjíríà.
Èyí ni ìfẹnukò àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ náà lẹ́yìn ìpàdé àpérò wọn tí wọ́n ṣe ní ìlú Abeokuta, olú ìlú ìpínlẹ̀ Ogun.
NLC ní àwọn kò ní jókòó máa wòran nígbà tí ètò ọrọ̀ ajé àti ìṣèjọba àwaarawa Nàìjíríà ń dojú délẹ̀.
Àtẹ̀jáde ìfẹnukò kan tí ààrẹ ẹgbẹ́ NLC, Joe Ajaero àti akọ̀wé rẹ̀ Emmanuel Ugboaja buwọ́lu sọ pé ẹ̀mí èèyàn tó lè ní 700,000 ló ti nù ní Nàìjíríà láàárín ọdún kan látàrí àìsí ààbò láì ṣe pé orílẹ̀ èdè wà lójú ogun.
NLC ṣèkìlọ̀ pé pẹ̀lú ètò ààbò tó ti mẹ́hẹ yìí, àwọn àgbẹ̀ kò le dáko bíi ti ìgbà kan mọ́, tí èyí sì le ṣokùnfà iyàn láàárín ìlú tí ìjọba kò bá tètè mójútó.
Wọ́n bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba pé wọn kò ṣe ìgbésẹ̀ tó láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn èèyàn.
Wọ́n wá rọ ìjọba láti kéde ìlú ò fararọ lẹ́ka ètò ààbò Nàìjíríà, kí wọ́n sì pàṣẹ fáwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti máa fi ìyà tó tọ́ jẹ àwọn ọ̀daràn tí ọwọ́ bá ti tẹ̀ tó ń hu àwọn ìwà ibi náà.
Àìsí ààbò, ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ àti àìbìkítà la ṣe ń gbèrò ìyanṣẹ́lódì - NLC
Nígbà tí BBC News Yorùbá kàn sí alága ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Ogun, Ademola Hammed-Benco, ó sọ pé àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tó ń wáyé ní Nàìjíríà ló mú àwọn pinnu pé ó ṣeéṣe kí àwọn bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì tí ìjọba kò bá tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí àwọn ìṣòro náà.
Hammed-Benco wòye pé ojoojúmọ́ ni owó oúnjẹ ń lọ sókè àti pé ètò ààbò ní Nàìjíríà kò ní ìsọ mọ́.
"Nítorí àsìkò yìí tó le danin-danin mọ́ àwọn ọmọ ìlú, àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, látorí ká pani lónìí ka pani lọ́la la ṣe gbé gbèdé ke pé tí wọn kò bá tètè ṣe àtúnṣe gẹ́gẹ́ bí ìjọba, ó ṣeéṣe ká tẹ̀síwájú láti mú ìyanṣẹ́lódì wá."
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìgbà tó ṣeéṣe kí ìyanṣẹ́lódì náà wáyé, ó ní táwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ ní Nàìjíríà bá ti fẹnukò lórí ìgbà tó máa jẹ́ ni àwọn máa fi léde.
Ó ṣàlàyé pé ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé ìwọ́de ló máa kọ́kọ́ wáyé tàbí ìyanṣẹ́lódì oníkìlọ̀ tàbí aláìní gbèdéke ni àwọn máa fi ẹnu kò lé lórí.
"Ó ṣeéṣe ká kọ́kọ́ ṣe ìwọ́de láti fi kì wọ́n nílọ̀, ó sì ṣeéṣe kó jẹ́ oní gbọnrangandan ló máa jẹ́. Ìyẹn kù sáwọn ọ̀gá lọ́wọ́, ohun tí wọ́n bá sọ la máa tẹ̀lé ní ìpínlẹ̀."
'Gbogbo ìgbà la máa ń jíròrò pẹ̀lú ìjọba'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yóò dúnkokò láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì àmọ́ tí wọn kò ní padà gùnlé ìyanṣẹ́lódì náà
Hammed-Benco tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ṣáájú káwọn tó máa gbé ìpinnu yìí síta ni àwọn ti ń kàn sáwọn ìjọba, táwọn sì ti ń báwọn jíròrò lórí gbogbo nǹkan tí àwọn ń sọ yìí.
Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́tà ni àwọn ti kọ, táwọn ti fi ránṣẹ́ sí ìjọba lórí nǹkan táwọn aráàlú ń kojú àti pé wọ́n túnbọ̀ máa tẹ̀síwájú pẹ̀lú àwọn ìgbìyànjú yìí.
"A ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ tuntun báyìí, ó sì dámi lójú pé gbogbo ohun tí a fẹnukò lé lórí ni wọ́n máa fi ránṣẹ́ sí ìjọba àpapọ̀.
"Lẹ́yìn èyí, tí ìjọba bá kọ̀ láti ṣe ojúṣe wọn, ó ṣeéṣe kí NLC lápapọ̀ fẹnukò láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì."
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yóò dúnkokò tàbí fẹnukò láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì láti fi bèèrè ohun kan lọ́wọ́ ìjọba àmọ́ tí wọn kò ní padà gùnlé ìyanṣẹ́lódì náà.
Ní oṣù Kejì ọdún 2025 ni NLC dúnkokò láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì bí ìjọba àpapọ̀ kò bá mú àyípadà bá owọ tí wọ́n fi kún owó ìpè àti dátà.
NLC ní àlékún owó ìpè àti dátà náà wáyé láì gba àwọn ìlànà tó yẹ àti pé ìjọba kò kàn sáwọn tó ṣe kókó kí wọ́n tó gbé ìgbésẹ̀ náà.
Bákan náà ni wọ́n rọ àwọn aráàlú láti má lo àwọn iléeṣẹ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ kan mọ́ látàrí ìgbésẹ̀ náà.
Lẹ́yìn-ò-rẹ̀yìn, ìyanṣẹ́lódì náà kò padà wáyé, tó sì jẹ́ pé ìjọba àpapọ̀ kò mú àyípadà bá àlékún iye owó ìpè àti dátà.















