Èèyàn tó kú níbi ìwọ́de 7-7 di mọ́kànlélọ́gbọ̀n, 100 fi ara pa, 567 wà ní àhámọ́, aráàlú àti ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ̀lú fọnmú

Oríṣun àwòrán, Anthony Irungu / BBC
- Author, Ian Wafula, Basillioh Rukanga & Natasha Booty
- Role, BBC News, Nairobi & London
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Bi o tilẹ jẹ pe ileesẹ ọlọpaa nilẹ Kenya kede pe eeyan mọkanla lo ku ninu iwọde ọjọ keje, osu keje, 7-7, ti wọn tun n pe ni Saba-saba nilẹ naa.
Amọ ajọ ajafẹtọẹni lorilẹede naa ti salaye pe iye eeyan to ku nibi iwọde naa jẹ mọkanlelọgbọn.
Isẹlẹ naa ti bọ sapo ibinu araalu, ti wọn si n beere fun idajọ ododo fun iku awọn eeyan naa.
Bakan naa, ajọ to n risi ẹtọ ọmọniyan nilẹ Kenya (KNCHR) ti kede pe o le ni ọgọrun eeyan to farapa nibi iwọde naa.
O fikun pe eeyan to to ojilelẹẹgbẹta o din mẹjọ, 532, ni awọn ọlọpaa mu, ti wọn si fi wọn si ahamọ ni olu ilu ilẹ naa, Nairobi atawọn ilu nla nla miran lasiko iwọde ọhun.
Tun wẹ, ajọ isọkan agbaye ti wa kede pe isẹlẹ ipaniyan naa n kọ oun lominu, to sib u ẹnu atẹ lu ileesẹ ọlọpaa ilẹ Kenya pe o lo ohun ija agbẹmi tako awn oluwọde naa.
Se ni rogbodiyan n peleke si lorilẹede Kenya lati igba ti akroyin ori ayelujara kan, Albert Ojwang ku si ahamọ ọlọpaa losu to kọja.
Isẹlẹ naa si lo tun mu kawọn araalu tu si oju popo lati se iwọde lẹyin ọdun kan tawọn ọdọ yabo ile asofin orilẹede naa lati se iwọde tako alekun owo ori.

Oríṣun àwòrán, EPA
Iwọde lati sami iwọde ọjọ keje oṣu keje ọdun 1990, nibi ti awọn eeyan Kenya ti pe fun ọpọ ẹgbẹ oṣelu ninu ijọba awarawa, tun mu ọpọ ẹjẹ lọwọ
Saaju ni ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣalaye pe o le ni eeyan mọkanla ti wọn padanu ẹmi wọn lasiko ifẹhonuhan to n tako ijọba orilẹede Kenya, ti ọwọ si tẹ eeyan 567.
Awọn agbofinro yii ni iroyin ni wọn sina bolẹ fun awọn olufẹhonuhan, ti Dokita Aron Sikuku, niluu Nairobi si sọ fun BBC pe eeyan meji ti ibọn ba, ti wọn gbe wa si ile iwosan naa lo ti jade laye.
Ọ ni ọpọ olufẹhonuhan yapa siwaju ile iwosan , ti wọn si n kesi awọn oṣiṣẹ ilera pe ki wọn gbe oku awọn eeyan to ti jade laye.
Iwọde yii lo waye lati ṣami ayajọ ọdun karundinlogogi Saba-Saba, to tumọ si "meje-meje" tabi 7-7.
Iwọde to waye ni ọjọ keje oṣu keje ọdun 1990, nibi ti awọn eeyan Kenya ti pe fun ọpọ ẹgbẹ oṣelu ninu ijọba awarawa.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Oríṣun àwòrán, Anthony Irungu / BBC
Ileeṣẹ ọlọpaa ninu atẹjade kan ti wọn fi lede lọjọ Aje, kan sara si awọn ọmọ ologun ileeṣẹ ọlọpaa fun bi wọn ṣeeṣe iṣẹ takutakun lasiko ifẹnonuhan. Atẹjade naa ni ọlọpaa mejilelaadota ati araalu mọkanla lo farapa lasiko yii.
Ileeṣẹ to n risi ọrọ nipa ọmọniyan lorilẹede Kenya (KHRC) sọ saaju pe o le ni eeyan mẹwaa to padanu ẹmi wọn.
Ninu iwadi to fi lede, ileeṣẹ naa fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa pe wọn lo agbara wọn lati kọlu araalu to n wọde.
"Ọlọpaa kọlu awọn araalu lai wọ aṣọ, ko da wọn ko gbe ọkọ ọlọpaa wa lọjọ Aje, ti wọn siṣẹ papọ pẹlu awọn ẹgbẹ janduku kan ni Nairobi, Kajiado, Nakuru, Kiambu, ati Eldoret", o sọ. Ileeṣẹ ọlọpaa ti wọgile ẹsun naa pe irọ to jina si otitọ ni.
O fikun pe ẹri wa pe eeyan meji ni wọn ti ji gbe, ti eeyan mọkandinlọgbọnsi farapa, ti ọwọ si tẹ eeyan mẹtadinlogogi kaakiri ilu lorilẹede Kenya.
Ọpọ awọn araalu ati arin irin-ajo ni wọn ko le jade kuro ni ilu nitori bi ileeṣẹ ṣe gbe igi dena ni awọn ẹnu ibode, ti awọn araalu ko si ni anfani lati jade labi kuro ni olu ilu naa.
Oju opopona ti awọn ileeṣẹ ijọba, ile aarẹ ati ile igbimọ aṣofin Kenya nig be igi dena rẹ.
Bakan naa ni awọn ile ẹkọ rọ awọn akẹkọọ wọn pe ki wọn duro ni ile.
Humphrey Gumbishi, awakọ bọọsi ni oun bẹrẹ irinajo oun ni irọlẹ ọjọ iku ko to mọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe den ani owurọ.
"A bẹrẹ irinajo ni ago mẹjọ abọ ni alẹ… A fẹ ki ijọba ba awọn GenZ sọrọ, ki wọn si fopin si rogbodiyan yii," o sọ fun BBC.
Ninu atẹjade ti ọlọpaa fi lede lọjọ Aiku, ileeṣẹ ọlọpaa ni ẹtọ ilu ni awọn n ṣe, ti wọn si n da bobo araalu ati dukia wọn.
Iwọde ọjọ Aje ti awọn Gen-Z gbe kalẹ, ni wọn fi n pe fun ijọba rere, idajọ ododo fun awọn eeyan ti ọlọpaa kọlu.
Ni ọjọ karundinlọgbọn oṣu kẹfa, o le ni eeyan mọkandinlogun to padanu ẹmi wọn, ti ọpọ si ja sọọbu awọn eeyan, ba ile jẹ lasiko ti iwọde ti wọn gbe kalẹ lati ṣe iranti awọn eeyan to ku lasiko iwọde owo ori.
Raila Odinga pe ijiroro lori atunṣe ọlọpaa Kenya
Olootu ijọba Kenya tẹlẹ, Raila Odinga ti pe fun atunṣe ileeṣẹ ọlọpaa, lati mu ajọsepọ laarin wọn ati araalu danmọran.
O sọ eyi lasiko ifọrọwerọ kan to waye ni ile itura kan ni Nairobi, o pe fun ijiroro kiakia lati mu atunṣe ba ileeṣẹ ọlọpaa nitori oludabobo araalu ni ọlọpaa jẹ, ti araalu si gbọdọ fọkan tan wọn.
"A ni awọn kọlọrọsi ẹda ninu ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn yinbọn fun araalu, ohun ti wọn jogun lọwọ ijọba amunisin.
Raila jẹ ọkan ninu akọni iwọde ọjọ Keje oṣu keje- ti awọn n pe ni Saba Saba – to tako iṣejọba Aarẹ Daniel arap Moi, iṣejọba ẹgbẹ oṣelu kan, to si n pe fun ọpọ egbẹ oṣelu.
Saaju ni Raila ni ki awọn oluwọde kora wọn jọ si Kamukunji ni Nairobi lọjọ Aje fun ayẹyẹ ọdun karundinlogogi ti iwọde naa waye. Ẹwẹ, awọn ọlọpaa gbe igi dena gbogbo ọna to wọn olu ilu naa.
Raila fikun pe ọhun pato ti iwọde n bere fun lonii ni ijọba rere, to n pe ilọsiwaju ọrọ Aje, idọgbaa ati opin si gbogbo iwa ibajẹ to wọpọ ninu ẹka ijọba.















