Ìjọba àpapọ̀ fèsì lẹ́yìn tí Amẹríkà fún okùn físà gbígbà mọ́ ọmọ Naijiria lọ́rùn

Aworan Aarẹ Tinubu ati Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ijọba Naijiria ti sọrọ soke lẹyin igbesẹ ijọba ilẹ Amẹrika lati fun okun mọ ọrun mọ awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ maa ṣe abẹwo si ilẹ naa.

Ninu atẹjade kan ni ijọba Amẹrika ti kọkọ kede pe awọn to ba fẹ lọ ṣabẹwo si ilẹ oun lati Naijiria ko ni lanfani lati lo ju oṣu mẹta pere lọ dipo fisa ọlọdun meji tabi maru un ti wọn n fun ọmọ Naijiria tẹlẹ.

Wọn ni ọrọ yii ko kan awọn to ti ni fisa lọwọ, bikoṣe awọn to ṣẹṣẹ fẹ maa gba fisa lati akoko yii lọ.

Bẹẹ ni wọn tun ni ọrọ naa ko kan awọn to fẹ maa gbe l'Amẹrika, bikoṣe awọn to fẹ lọ ṣabẹwo, yala fun ọrọ aje tabi irinajo afẹ.

Gẹgẹ bii ijọba Amẹrika ṣe sọ, igbesẹ naa waye lati gbẹsan awọn nnkan ti ijọba Naijiria ṣe fun Amẹrika, eyii ti ko dun mọ awọn ninu.

Awọn ti ọrọ naa kan gbọngbọn ni awọn to ba fẹ gba fisa to wa ni ipin B1/B2, F ati J.

Lẹyin ikede ọhun ni ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ni Naijiria naa fi atẹjade tirẹ sita lati rọ Amẹrika pe ko yi igbesẹ naa pada.

Atẹjade ọhun, ti alukoro ileeṣẹ naa, Kimiebi Imomotimi Ebienfa fi lede sọ pe igbesẹ ijọba Amẹrika kọ ijọba Naijiria lominu latari ibaṣepọ to dan mọran to ti wa laarin ijọba orilẹede mejeji lati ọpọ ọdun sẹyin.

Atẹjade ijọba Naijiria

Oríṣun àwòrán, Ministry of Foreign Affairs, Nigeria

O ni igbesẹ ọhun lodi si ibaṣepọ aarin ijọba orilẹede mejeji ati iyi ti wọn n bu fun ara wọn latẹyinwa.

Ebienfa sọ pe "Ijọba Naijiria ri pe igbesẹ yii yoo di ẹru wuwo le awọn ọmọ Naijiria to n rinrinajo lọ Amẹrika lori, to fi mọ awọn akẹkọọ to fẹ lọ kẹkọọ gboye, awọn oniṣowo to fẹ lọ ṣowo, awọn to fẹ lọ ṣabẹwo si mọlẹbi wọn atawọn to n ṣe paṣipaarọ eto ẹkọ ati aṣa laarin orilẹede mejeji.

"Bo tilẹ jẹ a mọ pe onikaluku orilẹede lo lẹtọọ lati yan bi awọn eeyan yoo ṣe maa ṣabẹwo silẹ rẹ, pẹlu tọwọtọwọ ni Naijiri fi rọ ijọba Amẹrika lati yi igbesẹ naa pada latari irẹpọ ati ibaṣepọ aarin orilẹede mejeji."

O pari atẹjade naa pe itakurọsọ ti n lọ lọwọ ati pe ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilé okeere ṣẹtan lati yanju ọrọ naa ni itubi inubi ati lọna ti ko ni pa orilẹede mejeji lara.

Wo àwọn ẹ̀sùn tó mú Amẹ́ríkà mú àdínkù bá físà tó ń fún ọmọ Nàìjíríà sí oṣù mẹ́ta

Àwòrán ìwé ìrìnnà Nàìjíríà àti ẹni tó fẹ́ ṣe ìrìnàjò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìjọba orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti kéde àtúnṣe sí bí àwọn èèyàn láti orílẹ̀ èdè míì ṣe le ṣàbẹ̀wò sí orílẹ̀ èdè náà tó fi mọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Àtúnṣe sí ètò gbígba "físà" sí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà yìí tí wọ́n pé ní 'Visa Reciprocity Policy for Nigeria'yóò bẹ̀rẹ̀ lójú ẹsẹ̀.

Ìgbésẹ̀ tuntun yìí máa ní ipa lórí àwọn tó bá ṣe àbẹ̀wò sí Amẹ́ríkà àmọ́ kò ní ní ipá lórí àwọn tó bá fẹ́ gba físà láti máa lọ gbé Amẹ́ríkà.

Èyí túmọ̀ sí pé láti àsìkò yìí, ọmọ Nàìjíríà tó bá fẹ́ gba físà láti lọ ṣàbẹ̀wò sí Amẹ́ríkà kò ní ní àǹfàní láti wọ orílẹ̀ èdè náà ju ẹ̀ẹ̀kan péré lọ àti pé wọn kò ní ní àǹfàní láti lo ju oṣù mẹ́ta lọ.

Ṣáájú àsìkò yìí, Amẹ́ríkà máa ń fún àwọn ọmọ Nàìjíríà ní físà láti ṣàbẹ̀wò sí orílẹ̀ èdè náà fún bíi ọdún méjì sí márùn-ún.

Láàárín ọdún náà, èèyàn le wọ Amẹ́ríkà kò sí jáde ní iye ìgbà tó bá wù ú títí tí ọjọ́ fi máa lọ lórí físà náà ṣùgbọ́n èyí ti yípadà báyìí.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ Amẹ́ríkà ní Nàìjíríà fi sójú òpó ìtàkùn ayélujára wọn lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun sọ pé gbogbo àwọn tó ti àwọn ti fún ní físà ṣáájú ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Keje ló máa wà bó ṣe wà, tí wọ́n sì máa lo ìgbà tí wọ́n fún wọn pé.

Àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ yìí ń wáyé nítorí pé ó pọn dandan láti máa ṣe àtúnṣe sí ètò ìrìnnà wọn ní gbogbo ìgbà.

Wọn fi kun pé ìgbésẹ̀ náà tún ń wáyé láti gbẹ̀san ètò físà gbígbà táwọn orílẹ̀ èdè mìíràn ń gbé kalẹ̀ fún wọn tó fi mọ́ Nàìjíríà.

Ẹ ó rántí pé ní ààrin oṣù Kẹfà ni ìṣèjọba Trump ti kéde pé àwọn fẹ́ ṣe àtúnṣe sí báwọn èèyàn ṣe ń wọ orílẹ̀ èdè náà àti pé àwọn orílẹ̀ èdè bíi mẹ́rìndínlógójì ni àtúnṣe náà máa ni ipa lé lórí.

Wọ́n ní ìgbésẹ̀ náà jẹ́ akitiyan ìjọba láti ri pé wọ́n ṣe àtúnṣe sí báwọn èèyàn ṣe ń wọ orílẹ̀ èdè náà.

Bákan náà ni wọ́n fi kun pé àwọn ń gbé ètò físà náà kalẹ̀ láti dá ààbò bo ètò ìwọlé àti ìjáde Amẹ́ríkà.

Wọ́n ní àwọn ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba Nàìjíríà láti ri dájú pé àwọn gbogbo ìlànà tí àwọn là kalẹ̀ lórí gbígba físà ni wọ́n ń tẹ̀lé.

Wọ́n fẹ̀sùn kàn pé Nàìjíríà kìí mójútó àwọn ìlànà tó yẹ lórí ètò gbígba físà àti pé ó wà lára ìdí tí àwọn fi gbé ìgbésẹ̀ náà.

Kí ni àwọn ìlànà tí Amẹ́ríkà gbé kalẹ̀ lórí gbígba físà?

Àwòrán visa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí Amẹ́ríkà gbé kalẹ̀, wọ́n ní ìlànà mẹ́ta ni ìjọba Nàìjíríà gbọ́dọ̀ tẹ̀lé kí ètò gbígba físà lè máa lọ bó ṣe yẹ.

  • Níní àwọn ìwé ìrìnnà tó péye lọ́wọ́: wọ́n ní àwọn orílẹ̀ èdè tó ń wọ Amẹ́ríkà gbọdọ̀ ṣe àrídájú rẹ̀ pé wọ́n ní àkọ́ọ́lẹ̀ àti àmì ìdánimọ̀ àwọn èèyàn tó péye lọ́wọ́.
  • Ṣíṣe àtúnṣe sí báwọn èèyàn ṣe ń kọjá ìgbà tí wọ́n fún wọn: Wọ́n gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ láti ri pé àwọn tó ń wọ Amẹ́ríkà kò máa lò ju gbèdéke àsìkò tí wọ́n fún wọn lọ.
  • Gbígbé ìmọ̀ nípa ẹni tó ń gba físà jáde: wọ́n ní wọn gbọdọ̀ máa pèsè àwọn ìròyìn tó yẹ, yálà nípa àwọn ìwà ọ̀daràn tí ẹni tó bèèrè bá ti wù sẹ́yìn láti dá ààbò bo àwọn aráàlú.

Wọ́n fi kun pé àwọn ní ìfarajìn sí ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà àti Nàìjíríà láti ọjọ́ pípẹ́ lójúnà àti mú kí orílẹ̀ èdè méjéèjì wà ní ààbò tó péye.

Àtẹ̀jáde wá kan sáárá sí àjọ tó ń rí sí ètò ìwọléjáde èrò èrò ní Nàìjíríà àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò fún iṣẹ́ takuntakun wọn láti ri pé wọ́n ṣàmúlò ìlànà tó yẹ.

Bákan náà ni wọ́n rọ àwọn arìnrìnàjò ní Nàìjíríà láti rip é wọ́n ń tẹ̀lé ohun tí físà wọn bá sọ, kí wọ́n sì ri pé àwọn ìwé ẹ̀rí tí wọ́n fi ń ṣe ìrìnàjò pé pérépéré, kí wọ́n sì ri pé ó jẹ́ ojúlówó.