Àwọn ọmọ tí kò mọ bàbá wọn di irinṣẹ́ ìbálòpọ̀, kojú ìdẹ́yẹsí àti ìgbeyàwó àṣàǹte


Esti, Aminah ati Fatma, ọmọ iya kan naa mẹta ti iya wọn da silẹ lọ. Awọn ẹbi lo tọ wọn

Oríṣun àwòrán, BBC/Hanna Samosir

Àkọlé àwòrán, Etsi, Aminah ati Fatma
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ìkìlọ̀: Àwọn ohun ti ko ba ọkàn rẹ́ wà nínú ìròyìn yìí.

Iyi ọmọ tuntun ni ko ri ile ire de si, ko ri awọn obi mejeeji ti wọn ti n reti ìbí rẹ tẹlẹ, ki wọn si fi ayọ nla ki i kaabọ si orilẹ aye.

Ṣugbọn gbogbo ọmọ kọ leyi ri bẹẹ fun, baba ti wọn bi ọmọ miran fun ko tilẹ duro gba oyun rẹ, debi ti yoo fi ifẹ han si i.

Iru nnkan bayii lo n ṣẹlẹ lorilẹede Indonesia , paapaa lagbegbe Lombok.

Awọn arinrinajo to waa ṣiṣẹ lapa ibẹ lo saba n ki awọn obinrin mọlẹ, wọn yoo fun wọn loyun, wọn yoo si ba tiwọn lọ.

Bakan naa ni awọn obinrin arinrinajo mi-in naa yoo loyun fun ajeji bii tiwọn, bi wọn ba bimọ naa tan, wọn le ba tiwọn lọ.

Orukọ ti wọn n pe awọn ọmọ bi eyi ni "awọn ọmọ arinrinajo Takari."

Awọn ọmọ naa ti ko ba ku ni kekere yoo wa maa koju idẹyẹsi nla, wọn ki I lẹnu ọrọ lawujọ awọn ọmọ ọkọ.

Bi wọn ṣe bi wọn ki I jẹ ki wọn lẹtọọ si iwe irinna lati jade niluu nirọrun.

Bẹẹ ni wọn ki i lẹtọọ si iwe kika ati itọju.

Inu ijiya yii ni wọn yoo wa, wọn yoo maa dagba sinu iṣẹ́ ati òṣì.

Bi wọn ba ti n dagba diẹ, awọn obinrin wọn yoo maa sare wọnu igbeyawo, ki wọn le maa ri ẹni gbọ bukata wọn.

Igbeyawo ọhun ki i tọjọ, ọkọ ki i mọyi wọn.

Alubami ni wọn n lu ẹlomi-in, iṣekuṣe ni wọn fi n lọ awọn mi-in, wọn n lo wọn bii irinṣẹ ibalopọ, nitori wọn o lẹni kan.

Àdánìkàngbé

Siti Aminah

Oríṣun àwòrán, BBC/Hanna Samosir

Àkọlé àwòrán, Siti Aminah

Siti Aminah, ọkan ninu awọn ọmọ naa ti ọjọ ori rẹ ko ju mẹtalelogun (23) n da ile aye rẹ ṣe.

Iya rẹ kuro ni Lombok, o gba Saudi Arabia lọ nigba ti oju n ti i .

Amina wọnu igbeyawo aladehun asiko diẹ pẹlu ọkunrin ọmọ Pakistan kan, igbeyawo ikọkọ ni.

O kọ ọ silẹ o tun fẹ ọmọ Saudi.

O loyun laaarin igbeyawo mejeeji, o si pada si Indonesia lati bimọ.

Ti Aminah tun san ni, ọmọ mẹfa ni iya rẹ fi silẹ ni Lombok, ti wọn n gbe nile ẹbi kiri.

Endang Susilowati, oluwadii lati yunifasiti kan, ṣalaye pe "ọpọ arinrinajo Indonesia maa n wa ẹni fẹ bi wọn ba de, ki wọn le maa rẹni ba ṣe.

O ni wọn yoo si pada kọ ẹni naa silẹ ni .

Iru ẹ ni wọn fi bi Amina. Wọn maa n bu u pe Arab ni, wọn a ni baba rẹ ju ẹyọkan lọ.

BBC kan si Iya Amina to tun bimọ mi-in to n jẹ Fatma, ṣugbọn o kọ lati sọrọ .

Ajọ kan ti ki i ṣe tijọba, Rudat Center, lo n gbiyanju ni Lombok lati ri I pe awọn ọmọ yii lẹtọọ si iwe kika ati eto ilera.

Ìgbéyàwó ọmọdé

Etsi ree, ọmọ ọdun mejidinlogun ni bayii, o ti bimọ kan

Oríṣun àwòrán, BBC/Hanna Samosir

Àkọlé àwòrán, Etsi ree, ọmọ ọdun mejidinlogun ni bayii, o ti ṣegbeyawo ikọkọ, o si ti bimọ kan.

Rudat Center ṣalaye pe idẹyẹsi ti awọn ọmọ alaini baba yii n koju maa n jẹ ki wọn wa ninu ewu.

Ọkan lara awọn ewu naa ni didi iyawo lọọdẹ ọkọ lọjọ ori ti ko to nnkan.

Orilẹede Indonesia lo wa nipo kẹrin ninu awọn orilẹede ti wọn ti n fi ọmọde lọkọ lagbaaye .

Apa ibi ti wọn n pe ni Nusa Tenggara, ni ẹkun-un Iwọ-Oorun ilu naa lo si pọ si ju.

Ni ti Fatma, ọmọ ọdun mẹẹẹdogun (15) lo wa to ti ba ọkọ lọ.

Gẹgẹ bi awọn akọṣẹmọṣẹ lori igbeyawo ọmọde ṣe wi, wọn ni ki eeyan tete wọnu igbeyawo bayii ko tan iṣoro.

Fatma ṣegbeyawo ti ko ni akọsilẹ labẹ ofin lẹẹmẹta, o si bimọ meji .

Oyún oge

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oyun oge, oyun wẹẹrẹ ni awọn ọmọde to n rele ọkọ kia naa n ni latari bi wọn ṣe n ni ibalopọ.

Ajọ United Nations Population Fund (UNFPA), sọ pe awọn ọmọde oloyun naa wa ninu ewu ẹjẹ riru, abisinwin ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bakan naa ni awọn ọmọ ikoko ti wọn n bi naa wa ninu ewu ki wọn waye lai to ọjọ, wọn le kere bii ọmọ ẹyẹ, wọn si le ku lojiji.

Aminah bi tiẹ nigba ti oyun rẹ wa loṣu mẹrin, ọmọ naa si pada ku.

Ọmọ ọdun mọkandinlogun (19) lo wa to fi wọ Saudi Arabia lọna aitọ, to n ba wọn ṣiṣẹ olowo pọọku.

Ọmọbinrin naa ṣalaye iriri rẹ, o ni bii koun pa ara oun lo maa n ri.

"Wọn lu wa, wọn ṣe wa baṣubaṣu titi ti mo fi n ronu pe abi mo ti fẹẹ ya were ni.

"Mo pada wale lai ri nnkan kan de ba, owo ti mo fi n ranṣẹ sile ti lọ"

Bẹẹ ni Amina wi.

Rudat Center gbe eyi lẹsẹ pẹlu alaye pe ebi n pa awọn to wa nile pẹlu.

O ni bi ọmọde to n ṣiṣẹ abuku nilẹ okeere ba fowo ranṣẹ pe ki wọn ba oun fi pamọ sile digba toun yoo pada de, niṣe ni wọn n na an.

Zurhan Afriadi to ṣoju Rudat Center lo ṣalaye bẹẹ.

'Àyípadà rere ti ń dé'

Pẹlu iranlọwọ awọn ajọ ti ki i ṣe tijọba yii, ayipada rere ti n de.

Lọdun to kọja, ijọba ṣeto bi awọn ọmọ yii yoo fi le lọ sileewe, ti wọn yoo si le gba itọju fun wọn ni Lombok.

Ṣugbọn eyi ko ṣẹgun idẹyẹsi ati abuku to maa n kan wọn

Esti ni ikẹta awọn ọmọ yii, ọmọ ọdun mẹrinla lo wa to ti wọle ọkọ. Ko lọ sileewe, o bimọ kan fun ọkọ rẹ.

Iṣẹ ni Esti n ṣe to fi n gbọ bukata ara rẹ ati ti ọmọ kan ṣoṣo to bi, ọmọ ọkunrin.

Bi ayipada ṣe n wa ni awọn ọmọ ti wọn bi lai rẹni gba wọn yii naa n bimọ si iru ipo ti awọn obi wọn bi wọn si.

Irti Aminah, Fatma ati Esti ni pe yoo daa lọjọ kan.