Àlàyé rèé lórí bí orí ṣe kó igbákejì ààrẹ yọ, tí wọn kò fi yọ́ kúrò lásìkò tó wà nípò gómìnà

Oríṣun àwòrán, Others
Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Kashim Shettima ni aarẹ orilẹede Naijiria nigba kan ri, Goodluck Jonathan lasiko iṣejọba rẹ fẹ yọ oun kuro nipo lasiko to jẹ gomina ipinlẹ Borno.
Shettima ni iṣejọba Jonathan ṣafihan rẹ gẹgẹ bii ọta ilu lasiko iṣejọba ọdun mẹrin.
Shettima sọ eyi nigba to sọrọ nibi ifilọlẹ iwe tuntun, OPL245: Inside Story of the $1.3 Billion Nigerian Oil Block, ti minisita fun eto idajọ nigba kan ri, Mohammed Bello Adoke, gbe kalẹ, eyi to waye ni gbọngan Shehu Musa Yar'Adua Centre.
Shettima ni ọpẹlọpẹ abẹnugan ile igbimọ aṣofin kekere nigba kan ri, Aminu Waziri Tambuwal, and Mohammed Bello Adoke to sọ fun Aarẹ Jonathan pe ko ni agbara labẹ ofin lati yọ oun kuro nipo gẹgẹ bii gomina.
"Olori ile aṣoju-sofin lo ni gboya lati sọ fun aarẹ pe ko ni agbara lati yọ mi kuro nipo Gomina, sibẹ, aarẹ ko gba"
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe oun ati Jonathan ti pari ija tipẹ, to si jẹ pe alaafia lo wa laarin wọn.
"Laarin ọdun mẹrin iṣejọba Jonathan, emi ni wọn bu ju, t imo jẹ eeyan buru, ọta araalu akọkọ.
Aarẹ nigba kan ri, Goodluck Jonathan, ẹni ti mo ti pari ija pẹlu rẹ, duro lori pe ki wọn yọ mi kuro gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Borno.
"Tambuwal, olori ile igbimọ aṣofin kekere nigba kan ri lo ni gboya lati sọ fun aarẹ pe ko ni agbara lati yọ mi kuro nipo gẹgẹ bii Gomina, ko da ko ni agbara lati yọ kanselọ adugbo. Sibẹsibẹ, aarẹ ko gba."
Shettima ni ọpọ awọn igbimọ ijọba Aarẹ lo tako igbesẹ naa, titi wọn fi jawọ ninu ero lati yọ gẹgẹ bii gomina.
O fikun pe iriri to ni lo jẹ ko ni ajọsepọ pipẹ pẹlu Adoke ati Tambuwal.
Ọpọ awọn eeyan jakanjakan lo wa nibi ayajọ ifilọlẹ iwe naa.
Ta a ni Kashim Shettima?
Kashim Ibrahim Shetima jẹ onimọ nipa eto ifowopamọ ati oloṣelu.
Oun ni ṣẹnetọ to n ṣoju gbungun ipinlẹ Borono lọwọlọwọ ni Ile Igbimọ Aṣofin Agba.
Shettima ti di ipo gomina mu lẹẹmeji nipinlẹ Borno lati ọdun 2011 si 2019.
O ni iwe eri imọ Bachelor's ati Master's Degree lati fasiti Maiduguri ati fasiti Ibadan.
Lẹyin to kawe jade ni o bẹrẹ idokowo ati iṣẹ ni ileeṣẹ ifowopamọsi, to si de ipo adari.
Ni nkan bi ọdun 2000 ni o da adari ileeṣẹ Zenith Bank ni Maiduguri ti o to kọ iwe fi ipo silẹ lati bẹrẹ iṣe ni ijọba gomina Ali Modu Sheriff ni ọdun 2007.
Lẹyin naa lo lo ọdun mẹrin ni ipo gomina ni ọdun 2011, to si dije du ipo aarẹ ni ọdun 2015.















