Kí ni Cryptocurrency, tí EFCC ń kígbe pé àwọn olóṣèlú kan ń lò láti kó owó ìlú lọ sókè òkun?

Alaga ajọ EFFC, Ola Olukoyede ti pariwo sita pe awọn oloṣelu kan n kowo ti wọn fi ọna eburu gba sinu apo owo crypto lati ma le fun awọn gbofinro ni anfani lati ṣawari wọn.
Olukoyede ni iwadi ajọ EFCC ṣafihan bi awọn oloṣelu ati oṣiṣẹ ijọba ṣe n lo crypto lati ji owo ilu pamọ.
O sọ eyi lasiko to n sọrọ nibi apero kan Africa Anti-Corruption Day lọjọbọ, to waye niluu Abuja, Lagos ati ibadan.
Olukoyede kilọ pe lilo crypto bi ori ayelujara ṣe ti mu ọpọ ayipada ba sisan owo lagbaye, bẹẹni o tun jẹ ọna fun awọn kọlọrọsi ẹda kan lati ko owo ilu pamọ.

Oríṣun àwòrán, Others
O ni, "Ẹrọ ayelujara n tan ka kaakri agbaye.
Bẹẹ ba gbagbe, ni ọdun 2021, Ileẹkọ aladani kan ni Kano ti sọ pe awọn ti bẹrẹ si ni gba ki akẹkọọ maa fi Crypto san owo.
Ọga ile ẹkọ naa Sabi'u Musa sọ fun BBC pe awọn gbe igbesẹ nitọri bi ọpọ eeyan ṣe n tẹwọgba owo oju opo ayelujara yii.
Arakunrin Sabi'u fi igbesẹ tuntun yii to awọn akọroyin leti to si ni ileẹkọ New Oxford Science Academy to wa ni Chiranchi finufẹdọ fẹ ṣe bẹẹ ni.
O ni awọn ko gbe igbesẹ yii lai ṣe pe awọn fi to awọn obi akẹkọọ awọn leti.
Nigba to n sọrọ nibi ipada to waye niluu Eko, Olukoyede, ẹni ti C. E. Michael Nzekwe soju fun ni Cryoto bayii, ti di ohun ija to lewu pupọ lọwọ awọn onijibiti ati awọn oloṣelu kan.
O kilọ pe lilo Crypto yii ti gboro lorilẹede Naijiria ati kaakiri agbaye pẹlu awọn oloṣelu ṣe n lo opo yii lu jibiti.
Nibi ipade naa to waye niluu Ibadan, Hauwa Ringin, ẹni to soju Alaga EFCC nibi ipade ọhun ni lilo crypto fun jibiti ti di ohun to n tan kaakiri ilẹ afrika to nilo amojuto.
Ki ni Crypto Currencies?
O le ti ma gbọ nipa Bitcoin fun ọpọ ọdun bayii. Koda, ọpọ awọn olowo aye bi Elon Musk lo ṣe atilẹyin fun, ti owo ẹyọ kan rẹ si le ni £34,000.
Ọkan lara ọpọ crypto currency ni Bitcoin jẹ, ti ọpọ alekun si ti ba lati igba ti wọn ti ṣe ifiọlẹ rẹ.
Awọn eeyan n Cryptocurrency bayii lati ra ọpọ nnkan bi ọkọ ati ile.
Bo ti lẹ jẹ pe ọpọ o ti ma lo, igbagbọ wa pe lọjọ kan crypto yoo gba gbogbo agbaye kan, ti wọn si rọpo owo pepa pẹlu rẹ.
Wo awọn orile-ede to fi ofin de owo Crypto
- Nigeria
Banki apapọ Naijiria pasẹ pe banki kankan ko gbọdọ ṣe katakara owo ori ayelujara, Crypto (Dogecoin, Bitcoin, ati Ethereum) mọ.
Ọpọlọpọ awuyewuye lo si ti n waye lori àṣẹ naa jakejado Naijiria.
Awọn ileesẹ iroyin kan ni Naijiria sọ pe nitori ikilọ ti ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ America, FBI, fun banki apapọ Naijiria ni wọn fi fofin de Crypto.
Ko sẹyin bi onijibiti to n lo owó Crypto lati ko ọpọlọpọ miliọnu Dọla ilẹ America ti wọn ko jọ lọna aitọ lati àwọn orilẹ-ede kan ati America, wọ Naijiria, ni banki apapọ naa se pàṣẹ.
Sugbọn ṣa, kii ṣe orilẹ-ede Naijiria nikan lo ti fi ofin de owo Crypto.
- China
Ninu oṣu Kẹsàn-án, ọdun 2017 ni China bẹrẹ igbesẹ lati fi ofin de pasipaarọ Bitcoin lorilẹ-ede naa. Awọn ilu bi Beijing ati Shanghai lo si ti bẹrẹ.
Ofin naa jẹ ara igbesẹ ijọba China lati mu adinku ba ewu to wa fun eto owó nina lorilẹ-ede naa.
Banki apapọ China fi ikilọ sita lori itakun agbaye kan to gbe kalẹ pe awọn eeyan kan n lo owo Crypto lati hu iwa ọdaran bi katakara oogun oloro, fayawọ, kiko owo pamọ lọna aitọ, ati ikowojọ ti ko ba ofin mu.
- Iran
Awọn alasẹ orilẹ-ede Iran naa ti fi ofin de owo Crypto. Ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2018, banki apapọ Iran pàṣẹ fun awọn banki yooku lati ma a ṣe okoowo Crypto, nitori ibẹru pe awọn eeyan kan le lo imọ ẹ̀rọ naa lọna aitọ.
Wọn ni àwọn onijibiti le ma a lo lati gbọ bukaata igbesunmọmi, kiko owo pamọ lọna ti ko ba ofin mu, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Koda lọdun 2019, awọn alasẹ ni Iran gbẹsẹ le ẹgbẹrun kan irin'ṣẹ iwakusa Bitcoin, to jẹ ti ileesẹ meji to ti ko igba wọle, nitori pe ina ijọba ti wọn n lo ti pọ ju.
Ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2018, banki apapọ India kede pe ofin ti de rira tabi tita owo Crypto. Koda, oṣu mẹta ni Reserve Bank of India, fun awọn banki naa lati fi opin si okoowo naa.Eeyan bi miliọnu marun-un lo n lo owo Crypto ni India lasiko naa.
- Bangladesh
Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kejila, ọdun 2017 ni banki apapọ Bangladesh fi ofin de lilo owo Bitcoin.
Ninu atẹjade kan to fi sita lo ti sọ pe nina owo naa le fa titapa si ofin to de gbigbọ bukaata igbesunmọmi ati kiko owo pamọ lọna ti ko ba ofin mu.
India Ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2018, banki apapọ India kede pe ofin ti de rira tabi tita owo Crypto.
Koda, oṣu mẹta ni Reserve Bank of India, fun awọn banki naa lati fi opin si okoowo naa.Eeyan bi miliọnu marun-un lo n lo owo Crypto ni India lasiko naa.
- Morocco
Ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2017 ni iroyin jade pe banki apapọ ati ileesẹ to n ri si pasipaarọ owo ilẹ okeere ni Morocco ti fofin de nina owó Crypto.
Ati pe ijiya nla ni fun ẹnikẹni to ba gba owó lati ilẹ okeere tabi san owó silẹ okeere lai lo àwọn ajọ ti ijọba fi àṣẹ fun, tabi gba owo ilẹ okeere ti ko si ninu akọsilẹ Bank Al-Maghrib.
Wọn ni ewu nla ni fun awọn to n na owo naa, nitori pe owo naa ṣe e lo lati ṣe katakara oogun oloro, nkan ijagun ati owo itusilẹ fun ẹni ti wọn ba ji gbe.
- Uganda
Ọdun 2019 ni banki apapọ ati ileesẹ ijọba Uganda to n mojuto ọrọ owo nina kilọ fun awọn eeyan pe ki wọn o ma a na owo Crypto nitori pe ijọba ko tẹ́wọ́ gba a.
Ijọba sọ pe ọpọlọpọ owó Crypto ni ko ni atilẹyin ijọba tabi eto adojutofo.
Bakan naa ni ileesẹ naa sọ pe ko si aabo fun awọn to n na owo naa ni Uganda, ti ohunkohun ba sẹlẹ si owo wọn.
- Zambia
Bakan naa ni banki apapọ Zambia, kilọ fun awọn eniyan orilẹ-ede naa ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2018 lori nina owó Crypto, to si ran wọn létí pe kii ṣe owó to ṣe itẹwọgba lorilẹ-ede naa.
Lara ewu ìwà ọdaran ti banki naa sọ pe o rọ mọ nina owó naa ni kiko owó pamọ lọna ti ko tọ ọ, jibiti, ati gbigbọ bukaata awọn agbesunmọmi.
Pẹlu àṣẹ ti banki apapọ Naijiria pa yii, ọpọlọpọ miliọnu Dọla owó Crypto ni yoo ha si Naijiria, to jẹ orilẹ-ede kejì ti okoowo Bitcoin pọ si julọ l'agbaye.
Bitcoin to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọta ni awọn ọmọ Naijiria ti fi dokoowo lati ọdun 2015.















