Akẹ́kọ̀ọ́ tó gba máàkì 375 rugi oyin, àjọ Jamb ṣàlàyé ìdí tí kò lè fi rí fásitì wọ̀ àti ojúṣe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lásìkò ìdánwò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn onimọ nipa eto ẹkọ kan ti sọ pe ajọ JAMB, ijọba apapọ, awọn olukọ atawọn obi lo jẹbi bi eto ẹkọ ṣe da ni Naijiria lode lonii.
Ọrọ yii lo n jẹyọ lẹyin ti ọga agba ajọ JAMB, Ọjọgbọn Ishaq Oloyede kede pe magomago ni ẹni to gba maaki to pọ julọ ninu idanwo JAMB ọdun yii, Chinedu Okeke, ṣe.
Oloyede, to sọrọ nibi ipade kan niluu Abuja, sọ pe awọn funra si akẹkọọ ọhun to gba maaki 375 lati ipinlẹ Anambra pe kii ṣe ojulowo akẹkọọ.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, akẹkọọ naa sọ pe oun fẹ lọ kọ nipa imọ Mechanical Engineering ni fasiti ijọba apapọ to wa niluu Eko, Unilag amọ akoṣilẹ nipa rẹ to wa lọdọ ajọ JAMB fi han pe o ti n kẹkọọ nipa imọ iṣegun, nile ẹkọ giga fasiti ijọba apapọ, UNN to wa niluu Nsukka.
Nigba ti BBC Yoruba kan si agbẹnusọ JAMB, Ọmọwe Fabian Benjamin, o ni ko ba ofin mu ki ẹni to ti wa nile ẹkọ giga kan tun kọ idanwo lati lọ sile ẹjọ giga miran, ko si lo ipinlẹ ọtọọtọ ninu awọn idanwo to kọ.
Benjamin ni "igbagbọ wa ni pe akẹkọọ naa jẹ ẹnikan to maa n ba awọn eeyan kọ idanwo lati pa owo, a ko si ni gba iru rẹ laaye lai.
"O ti wa nile ẹkọ giga kan tẹlẹ, eyii n tumọ si pe niṣe lo ba ẹnikan kọ idanwo JAMB ọdun yii."
Ki ni ojuṣe awọn akẹẹkọ lasiko idanwo JAMB?
Gẹgẹ bii Ọmọwe ọhun ṣe sọ, oniruru ojuṣe lo wa fun awọn akekọọ lasiko idanwo JAMB wọn, amọ eyii to ṣe koko julọ nibẹ ni pe ki wọn yẹra fun magomago idanwo.
O ni, "ṣiṣe magomago lasiko idanwo kii ṣe nipa titẹle awọn alakalẹ idanwo naa nikan, o ṣeeṣe ki eeyan tẹle awọn alakalẹ bẹẹ, ko si tun ṣe magomago ninu irufẹ indanwọ ọhun.
"Gbogbo eeyan lo mọ nnkan to tumọ si lati ṣe magomago lasiko idanwo, koda, ọmọ ọdun meji gan mọ nipa magomaago ṣiṣe."
O fi kun un pe, ojuṣe akẹkọọ ninu idanwo JAMB bẹrẹ lati igba to ba n mura fun idanwo naa, asiko idanwo ati lẹyin idanwo ọhun.
Ohun to yẹ ki akẹkọọ ṣe ṣaaju, ninu ati lẹyin idanwo JAMB
- Ki akẹkọọ tete de gbọngan idanwo pẹlu nnkan bii wakati kan ṣaaju idanwo naa – akẹkọọ funra rẹ lo gbọdọ joko ṣe idanwo, kii ṣe ẹlomiran
- Ki akẹkọọ mu iwe iforukọlsilẹ rẹ lọwọ, iyẹn "e-registration slip"
Awọn ohun ti akẹkọọ ko gbọdọ mu wa sibi idanwo:
- Ẹrọ ibaraẹnisọrọ
- Aago ọwọ to jẹ kọmputer
- Ẹrọ iṣiro
- Awọn ẹrọ to n lo Bluetooth, kamẹra ati USB drive.
- Apo apamọwọ atawọn iwe mii lati ita.
Lasiko idanwo:
Akẹkọọ ko gbọdọ ba ẹnikẹni sọrọ yatọ si igba ti alakoso idanwo naa ba gba wọn laaye lati ṣe bẹẹ ninu gbọngan idanwo ọhun
Ẹbi ijọba atawọn obi ni kudiẹkudiẹ to de ba eto ẹkọ - Onimọ
Ọgbẹni Olalekan Ọlajọbi to jẹ onimọ nipa eto ẹkọ ti di ẹbi iwa ibajẹ to gbode lasiko idanwo JAMB atawọn idanwo mii ru ijọba apapọ, awọn olukọ, atawọn obi ni Naijiria, lai yọ awọn akẹkọọ funra wọn silẹ.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, o ni, yatọ si pe ijọba atawọn obi lẹbi ti wọn, "ọpọ akẹkọọ ni ko kawe mọ, ẹrọ ayara bii aṣa ni wọn n gbe kiri."
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ijọba gbọdọ kọkọ ṣeto ti yoo mu ki iwe kika rọrun, ko si wu awọn akẹkọọ naa lati ṣe.
Ni ti awọn obi, o ni "ki ọmọ to bẹrẹ si n lọ ile ẹkọ, inu ile ni yoo ti kọkọ jade wa, nitori naa, ile ati obi ṣe pataki.
"Awọn obi lo ni iṣẹ to pọ ju lati ṣe ki awọn ọmọ wọn le kawe; wọn gbọdọ jẹ ko ye awọn ọmọ wọn pe, ẹkọ ṣe pataki fun ọjọ iwaju rere fun wọn."
Ni ti awọn olukọ, Alagba Ọlajọbi tun ṣalaye pe awọn olukọ naa tun ni ẹbi tiwọn latari pe ọpọ olukọ lonii ni ko fẹran iṣẹ olukọ, amọ pupọ ninu wọn ya si idi iṣẹ naa nitori wọn ko ri iṣẹ miran ṣe.
"Ẹwẹ, awọn olukọ kan a maa gba owo lọwọ akẹkọọ fun maaki.
"Amọ ṣa, kokari rẹ ni pe, ijọba gbọdọ wa ojutu si ọrọ yii, bẹrẹ lati iye owo to n la kalẹ fun eto ẹkọ ninu eto iṣuna rẹ lọdọdun.
"Ijọba tun gbọdọ gbe ofin kalẹ ti yoo maa fiya jẹ ẹnikẹni to ba n lo ayederu iwe ẹri tabi ba ẹlomiran kọ idanwo."
O pari ọrọ rẹ pe ọwọ obi, olukọ, paapaa ijọba ni ọrọ naa wa lati tan iṣoro to n koju eto ẹkọ ni Naijiria.















