Peter Obi ṣàlàyé onírúurú ọ̀nà tí yóò gbà mú àyípadà bá Nàíjíría

Peter Obi

Oríṣun àwòrán, Channels TV

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi ti wòye pé ẹnikẹ́ni tí yóò bá jẹ ààrẹ Nàìjíríà gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀lára, kò má jẹ̀ ẹ́ ẹni tí kò ní ní àkàsí kankan.

Obi sọ èyí nígbà tó kópa níbi ètò kan lórí ìkànnì Channels TV tó sì ní òun gbàgbọ́ pé ó yẹ kí ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ ààrẹ ṣetán láti fi ẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀ nígbà tí ẹ̀mí àwọn èèyàn rẹ̀ bá wà nínú ewu.

"Tí mo bá di ààrẹ, mà á lo àwọn ohun èlò tó bá wà ní ìkáwọ́ mi dáadáa. Mi ò ní sọ pé kí a ra ọkọ̀ òfurufú tuntun," Obi sọ bó ṣe ń fẹ̀sùn kan ìṣèjọba ààrẹ Tinubu pé wọn kò kọbi ara sí ìṣòro táwọn èèyàn ń kojú.

"Mi ò nílò ọkọ̀ òfurufú 'jet' nítorí mo lè lọ sí ibikíbi láì sí jet. Mi ò ní lo àádọ́jọ bílíọ̀nù náírà (₦150bn) láti fi ra ọkọ̀ òfurufú nígbà tí ìdá ọgọ́rin àwọn ilé ìwòsàn alábọ́dé tó wà ní orílẹ̀ èdè mi kò ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ.

"Mo ṣetán láti fi ẹ̀mí lélẹ̀ tí mo bá jẹ́ ààrẹ, tí ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn sì ń bọ́ lójú mi"

"Ọdún mẹ́rin àkọ́kọ́ mi gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra, ọkọ̀ Peugeot 406 ni mò ń gùn tó sì jẹ́ pé mi ò gun ọkọ̀ arọ́ta ìbọn dànù kankan tí mo fi parí ìṣèjọba mi. Kò sí ẹnikẹ́ni tó máa gbèrò láti ṣekúpa ẹ́, tí o bá ṣe ohun tó tọ́. Tí èèyàn bá ń ṣe ohun tí kò tọ́ ni yóò máa bẹ̀rù ikú.

"Tí àwọn èèyàn rẹ̀ bá ń kú, o gbọ́dọ̀ ṣetán láti kú. Ààrẹ náà gbọdọ̀ ṣetán láti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀."

Peter Obi tún fẹ̀sùn kan ààrẹ Bola Tinubu pé kìí ní ìmọ̀lára sí nǹkan táwọn èèyàn ń kojú. Ó ní ààrẹ Tinubu lọ sí ìpínlẹ̀ Eko fún ìsinmi ọdún ní oṣù Kejìlá ọdún 2024 nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ayẹyẹ ọdún ní Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo.

Bákan náà ló tún bu ẹnu àtẹ́ lu ààrẹ Tinubu lórí ìkọlù tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Benue pé kò ya ìjọba ìbílẹ̀ Yelwata níbi tí ìkọlù náà ti wáyé gangan nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sí Benue.

Ṣáájú ni Tinubu ti sọ pé ọ̀nà tí kò dára àti ẹ̀kún omi ni kò jẹ́ kí òun ríbi dé ìlú tí ìkọlù ọ̀hún ti wáyé.

'Mo máa díje dupò ààrẹ lọ́dún 2027'

Peter Obi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Peter Obi tún sọ àfọ̀mọ́ ọ̀rọ̀ pé òun yóò díje dupò ààrẹ Nàìjíríà lọ́dún 2027.

Èyí ló ń wáyé nígbà táwọn kan ti ń sọ pé ó ṣeéṣe pé kó jẹ́ pé igbákejì Atiku ló máa fẹ́ ṣe pẹ̀lú gbogbo àgbáríjọpọ̀ tó ń wáyé níbi tí wọ́n ti yan ẹgbẹ́ òṣèlú ADC gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọ́n máa lò láti fi ṣí ààrẹ Tinubu nídìí lọ́dún 2027.

"Mo máa díje dupò ààrẹ Nàìjíríà ní 2027 mo sì ní ìgbàgbọ́ pé mo ní gbogbo àmúyẹ láti díje."

Nígbà tó ń fèsì sí ìbéèrè pé ṣé ń gbèrò láti ṣe igbákejì Atiku Abubakar, Obi fèsì pé kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ rárá nínú èròńgbà òun àti pé òun àti ẹnikẹ́ni kò jọ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ rárá.

Bákan náà lọ sọ pé òun ṣì wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ń kópa nínú àgbáríjọ tó yan ADC gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ òṣèlú láti yọ Bola Tinubu nípò.

'Ọdún mẹ́rin péré ni mo nílò láti mú àyípadà bá Nàìjíríà'

Peter Obi tún sọ àrídájú rẹ̀ pé òun kò nílò ju ọdún mẹ́rin lọ láti mú ìṣèjọba rere bá àwọn èèyàn Nàìjíríà.

Ó ní òun máa fi àpẹẹrẹ ìjọba rere lélẹ̀ ní kété tí òun bá ti gba àkóso ìjọba àti pé ọdún méjì ti tó láti fi ṣàfihàn ìṣèjọba gidi.

"Láàárín ọdún méjì, nǹkan ti bàjẹ́ gidi. Ọdún méjì náà le mú àyípadà gidi bá orílẹ̀ èdè. Àwọn èèyàn fẹ́ rí ààrẹ tó ní ìmọ̀lára sí nǹkan tí wọ́n ń kojú."

Ṣáájú ètò ìdìbò ọdún 2027, onírúurú ìjíròrò ló ti ń wáyé pàápàá láàárín àwọn ẹgbẹ́ alátakò láti fẹnukò lórí ọ̀nà tí wọ́n fi máa gba ìjọba lọ́wọ́ ààrẹ Bola Tinubu lọ́dún 2027.

Èyí ló bí báwọn alátakò tó ṣe gbòógì bíi Atiku Abubakar, Peter Obi, David Mark, Rauf Aregbesola, Rotimi Amaechi, Nasir El Rufai àtàwọn míì tí wọ́n ṣe parapọ̀ ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá, tí wọ́n sì kéde pé àwọn ti yan ẹgbẹ́ òṣèlú ADC gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọ́n máa lò láti tako Tinubu lọ́dún 2027.