Gbogbo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àwọn tó kórajọ sínú ADC, ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò f'ọ́dún 2027

Bí wọ́n ṣe fa ọwọ́ David Mark sókè gẹ́gẹ́ bí alága tuntun fún ADC
Àkọlé àwòrán, Bí wọ́n ṣe fa ọwọ́ David Mark sókè gẹ́gẹ́ bí alága tuntun fún ADC
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ní Ọjọ́rú, ọjọ́ kejì, oṣù Keje ni àgbáríjọpọ̀ àwọn alátakò kéde pé àwọn ti yan ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress (ADC) gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọn yóò ṣàmúlò.

Ẹ ó rántí pé láti bíi oṣù mẹ́ta sẹ́yìn ni olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar ti kéde pé òun àtàwọn kan tó jẹ́ alátakò Tinubu ti ń korá jọ láti wá ọ̀nà tí wọ́n fi máa yẹ àgá mọ́ Tinubu nídìí lọ́dún 2027.

Lára àwọn tó wà nínú àgbáríjọ yìí ni Atiku Abubakar, Peter Obi, David Mark, Rauf Aregbesola, Rotimi Amaechi, Nasir El-Rufai àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn ni awuyewuye ti ń lọ lórí ẹgbẹ́ òṣèlú táwọn alátakò náà máa yàn láàyò kí wọ́n tó kéde pé ADC ni àwọn máa lò lásìkò ètò ìdìbò tó ń bọ̀ tí àwọn fi máa tako Tinubu.

Nígbà tí wọ́n kéde ẹgbẹ́ òṣèlú náà ni wọ́n yan David Mark àti Rauf Aregbesola gẹ́gẹ́ bí alága àti akọ̀wé fìdí ẹ ná, tí wọ́n sì gba ipò lọ́wọ́ àwọn alákòóso ẹgbẹ́ tẹ́lẹ̀.

Kí ni òfin sọ nípa yíyan àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́?

Lẹ́yìn tí àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú ADC gbé àkóso ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ fún David Mark àti Rauf Aregbesola ni àwọn èèyàn ń bèèrè pé ṣé ó ṣeéṣe kí ẹgbẹ́ òṣèlú yan èèyàn sípò àwọn aláṣẹ.

Onímọ̀ nípa òṣèlú ní Nàìjíríà, Dókítà Gbade Ojo sọ fún BBC pé kò sí ohun tó burú fún ẹgbẹ́ òṣèlú láti wá ọ̀nà láti gbilẹ̀, kí wọ́n hàn lágbo òṣèlú.

Gbade Ojo ní fúnra àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ ADC ni wọ́n juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn èèyàn tuntun láti gba àkóso ẹgbẹ́ wọn kí wọ́n le rọ́wọ́ mú níbi ètò ìdìbò tó ń bọ̀.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Iyì ẹgbẹ́ òṣèlú ni kó wà ní ìjọba, ẹgbẹ́ òṣèlú tí kò bá lè gba ìjọba, tí kò gba ìpínlẹ̀ kankan kìí ṣe ẹgbẹ́ òṣèlú.

"Bí wọ́n ṣ juwọ́ sílẹ̀ fún wọn kò ní ipa aburú kankan fún ẹgbẹ́ wọn, ẹgbẹ́ wọn máa tún gbajúmọ̀ si ni."

Ó wòye pé tó bá jẹ́ pé wọ́n finú fẹ́dọ̀ gbé àkóso ẹgbẹ́ lé àwọn èèyàn tuntun náà lọ́wọ́, láì sí ohun tó le fa ẹjọ́ lórí rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ó ní wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ láti jẹ́ kí ẹgbẹ́ wọn fi ní òkìkí si ní.

Ó fi kun pé gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe là á kalẹ̀, lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe àpérò ẹgbẹ́ ni yíyan àwọn èèyàn sípò aláṣẹ máa ń wáyé àti pé àwọn tí wọ́n yàn sípò yìí kàn wà gẹ́gẹ́ bíi fìdí ẹ́ lásán ṣáájú kí wọ́n tó ṣe àpérò ni.

"Níbi àpérò wọn ni wọ́n ti máa dìbò fáwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ tuntun, òfin fi ààyè kí àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ fipò sílẹ̀ nígbà tó bá wù wọ́n, tí wọ́n sì máa yan àwọn míì sípò wọn ṣáájú àpérò míì."

Fún Festus Adedayo ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kìí ṣe ohun tó burú pé ẹgbẹ́ òṣèlú ń wá ọ̀nà láti rọ́wọ́ mú níbi ètò ìdìbò tó ń bọ̀ pẹ̀lú bó ṣe fi ààyè gba àgbáríjọpọ̀ àwọn èèyàn láti darapọ̀ mọ́ ọn, ó ní ó jẹ́ ohun tí kò bójúmu pé ẹgbẹ́ òṣèlú máa fi àwọn ipò tó ṣe kókó rẹ̀ kalẹ̀ fáwọn àjòjì.

Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé àwọn àjọsọ kan ti máa wáyé lábẹ́nú kó tó di pé wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà síta, tí wọ́n sì ti jọ máa ní àwọn àdéhùn kan tí wọ́n fẹnukò lé lórí.

Ṣé ó ṣeéṣe kí ẹni tó wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kan tún máa ṣe àgbáríjọ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú míì láì fi ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ sílẹ̀?

Àwọn èèyàn lásìkò ìpàdé náà

Níbi ìpàdé tí wọ́n ti kéde ADC gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ òṣèlú táwọn alátakò fẹ́ lò láti kojú Tinubu náà ni wọ́n ti fún David Mark àti Rauf Aregbesola ní káàdì ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú náà.

Ṣáájú àsìkó yìí ni ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Osun ti ní àwọn ti lé Aregbesola kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà fún àwọn ẹ̀sùn pé ó ń ṣiṣẹ́ tako ẹgbẹ́.

Bákan náà ni David Mark ti kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ pé òun kò ṣe ẹgbẹ́ òṣèlú PDP mọ́.

Ìbéèrè tó gbẹnu ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí Peter Obi, Atiku Abubakar, Nasir El-Rufai àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n ní ẹgbẹ́ òṣèlú yàtọ̀ sí ADC tí wọ́n ti ń ṣe àgbáríjọ.

Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Gbade Ojo ṣe sọ̀, ó ní òfin tó ń rí ètò ìbò ní Nàìjíríà ìyẹn "Electoral Act" sọ ni pé tí ẹgbẹ́ òṣèlú tí èèyàn bá wà kò bá gbe èèyàn mọ́, ààyè wà láti kọ̀wé fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin kò fi ààyè gba èèyàn láti jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú méjì, èèyàn le fi iṣu síná kó máa fọgbọ́ wá ọ̀bẹ.

Ó ṣàlàyé pé àwọn tí wọ́n ń kó ara wọn jọ yìí ń gbìyànjú láti palẹ̀mọ́ sílẹ̀ de ètò ìdìbò ọdún 2027 ni.

Ó sọ pé tó bá ti ku oṣù mẹ́fà sí ètò ìdìbò, gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe là á kalẹ̀, ni àwọn èèyàn náà máa mọ odó ti wọ́n máa da ọ̀rúnlá sí.

"Àwọn tí kò ì tíì fi ẹgbẹ́ òṣèlú wọn sílẹ̀ ní oore di ìgbà tí ètò ìdìbò máa ku oṣù mẹ́fà kí wọ́n tó kọ̀wé fi ẹgbẹ́ sílẹ̀.

"Ó ní iye oṣù tí òfin sọ pé èèyàn gbọ́dọ̀ lò nínú ẹgbẹ́ tuntun kó tó le gbé àpótí ìbò.

"Tí wọ́n bá ibi tí ADC ń lọ, wọ́n máa ma kọ̀wé fipò sílẹ̀ tàbí kí wọ́n padà sínú ẹgbẹ́ tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀, wọ́n fẹ́ mọ bí ètò ṣe máa tò ní ẹgbẹ́ tuntun tí wọ́n ń lọ.

Festus Adedayo sọ pé òun ní ìgbàgbọ́ pé àwọn èèyàn náà máa kọ̀wé fipò wọn sílẹ̀ lẹ́gbẹ́ òṣèlú tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó gbégbá ìbò nítorí ó le ṣokùnfà kí wọ́n má rì í ipò tí wọ́n ń wá.

Àwọn wo ló wà nínú àgbáríjọ̀pọ̀ tuntun náà?

Àwòrán Atiku Abubakar, Peter Obi, Nasir El Rufai, Rotimi Amaechi

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar/Peter Obi/Nasir El Rufai/Rotimi Amaechi/X

  • David Mark

Ó ṣe gómìnà ológun ìpínlẹ̀ Niger láàárín ọdún 1984 sí 1986 kó tó di pé ó fi iṣẹ́ ológun sílẹ̀ lọ́dún 1993.

Ó ṣojú ẹkùn Gúúsù ìpínlẹ̀ Benue fún ọdún pípẹ́ ní ilé aṣòfin àgbà, tó sì ṣe ààrẹ ilé aṣòfin fún ọdún mẹ́jọ láàárín ọdún 2007 sí 2015 lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP.

Ní ọjọ́rú ni David Mark kéde pé òun ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ tí òun sì ti darapọ̀ mọ́ àgbáríjọpọ̀ àwọn alátakò láti gba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kalẹ̀ àti láti ri dájú pé ètò ìṣèjọba àwaarawa ń tẹ̀síwájú.

  • Rauf Aregbesola

Ọlọ́wọ́ ọ̀tún Tinubu tẹ́lẹ̀ ni Ọ̀gbẹ́ni Rauf Aregbesola báwọn èèyàn ṣe máa ń pè é.

Gbogbo ọdún mẹ́jọ tí Tinubu fi ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Eko ni Aregbesola fi ṣe kọmíṣánnà lábẹ́ rẹ̀.

Lẹ́yìn náà ló ló díje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun tó sì wọlé pẹ̀lú àtìlẹyìn Tinubu. Ọdún mẹ́jọ ni Aregbesola lò gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Osun.

Ìfaǹfà tó wáyé láàárín Adegboyega Oyetola tó ṣe gómìnà Osun lẹ́yìn Aregbesola wà lára ohun tó ṣokùnfà ìrẹ́pọ̀ tí kò sí láàárín òun àti Tinubu mọ́.

Aregbesola ni akọ̀wé fìdí ẹ́ fún ẹgbẹ́ òṣèlú ADC báyìí tó sì sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé iṣẹ́ tí àwọn gbé dání kìí ṣe iṣẹ́ kékeré rárá àmọ́ àwọn máa sa ipa láti rip é àwọn jagun náà bọ́.

  • Atiku Abubakar

Atiku Abubakar tó ti fpigbà kan jẹ́ igbákejì ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Nàìjíríà wà lára àwọn tó dá ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀ lọ́dún 2015.

Ó wà lára èèkàn gbòógì tí wọ́n dá New-PDP sílẹ̀ lọ́dún náà kí wọ́n tó darapọ̀ mọ́ APC ṣáájú ètò ìdìbò gbogbogbò àmọ́ tó padà padà sí PDP tó sì jẹ́ olùdíje sípò ààrẹ lọ́dún 2019 àti 2023.

  • Peter Obi

Olùdíje sípò ààrẹ lọ́dún 2023 lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, LP, Peter Obi wà lára àwọn tí wọ́n dá ẹgbẹ́ tuntun yìí sílẹ̀.

Peter Obi ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra fún sáà méjì láàárín ọdún 2006 sí 2014.

Lọ́dún 2019 ló díje gẹ́gẹ́ bí igbákejì ààrẹ pẹ̀lú Atiku Abubakar lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kó tó fi PDP sílẹ̀ lọ́dún 2022 bọ́ sí ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party.

  • Nasir El-Rufai

Ọ̀kan lára àwọn èèyàn Tinubu tẹ́lẹ̀ náà ni El-Rufai kó tó di pé ìjà dé sí ààrin wọn.

Ó wà lára àwọn tí ààrẹ fi orúkọ wọn ṣọwọ́ sí ilé aṣòfin àgbà fún ipò mínísítà ṣùgbọ́n tí wọn kò buwọ́lùú.

Ní oṣù Kẹta ni El-Rufai kéde pé òun ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó si darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú SDP.

El-Rufai, tó ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna f;un ọdún mẹ́jọ wà lára àwọn olóṣèlú tó mú àgbáríjọpọ̀ tuntun yìí ṣinṣin.

  • Aminu Tambuwal

Tambuwal ṣe abẹnugan ilé aṣojúṣòfin kó tó di gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto níbi tó ti ṣe sáà méjì.

Ó wà lára àwọn tó dá APC sílẹ̀ lọ́dún 2015 kó tó padà sínú ẹgbẹ́ PDP lọ́dún 2018.

Àwọn míì ni Sule Lamido, Babangida Aliyu, Sam Egwu, Liyel Imoke, Uche Secondus, Dino Melaye àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.