Wo ìgbésẹ̀ tí ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè gbé lábẹ́ òfin láti dènà ayípadà orúkọ ilé ẹ̀kọ́ wọn

Aworan geeti Poly Ibadan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ọkan lara awọn nnkan ti iran Yoruba gbagbọ ni wi pe orukọ ọmọ ni ijanu ọmọ.

Yatọ si orukọ ti gbogbo eeyan ni gẹgẹ bi ami idanimọ, gbogbo nnkan to n bẹ laye lo ni orukọ, tofimọ awọn ile ẹkọ giga ti a ti n kẹkọọ.

Iye ọdun ti a ba si fi mọ orukọ kan mọ eeyan tabi ile ẹkọ giga kan ni yoo sọ boya awuyewuye yoo rọ mọ igbesẹ lati yi orukọ naa pada.

Awọn aṣamọ yii lo difa fun ile ẹkọ giga gbogboniṣe Poly Ibadan ti ijọba ipinlẹ Ọyọ kede wi pe ayipada yoo ba orukọ ile ẹkọ naa lẹyin nnkan bii ọdun mejilelaadọta ti wọn ti daa silẹ.

Ọkanojọkan ariwo, iwọde ati ifẹhonuhan lo ti waye lẹyin ikede naa, gẹgẹ bi awọn to n kẹkọọ lọwọ ati awọn to ti kẹkọọ jade l'ọpọlọpọ ọdun sẹyin nile ẹkọ giga naa ṣe n rawọ ẹbẹ si Gomina Ṣeyi Makinde pe ko yi ipinnu rẹ pada.

Ọrọ yii lo mu ki a tọ Amofin lọ lati mọ awọn igbesẹ ofin ti ẹgbẹ awọn akẹkọọ le gbe ti ayipada orukọ ile ẹkọ wọn ko ba tẹ wọn lọrun.

A kan si gbajugbaju akọni niwaju adajọ, Amọfin Niyi Akintọla lati tan imọlẹ si awọn igbesẹ ofin ti ẹgbẹ awọn akẹkọọ naa le gbe.

Alaye ti Akintọla ṣe fun akọroyin wa ni pe ẹgbẹ awọn akẹkọọ naa le gba ile ẹjọ lọ bi ayipada orukọ ile ẹkọ wọn ko ba rẹ wọn lọrun.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Amofin naa ni gbogbo ọmọ Naijiria ti o ba kẹẹfin pe ẹnikan fẹ tẹ oju ẹtọ oun mọlẹ lo ni anfani lati lọ fi ẹjọ sun nile ẹjọ, ṣugbọn ẹni to ro ẹjọ kọ ni yoo daa. O ni ile ẹjọ nikan lo le sọ boya ẹni to wa fi ẹjọ sun yoo pada sile pẹlu idalare.

Nigba ti a beere fun ariwisi Amofin Akintọla lori awọn awuyewuye to ṣuyọ nitori ayipada orukọ ile ẹkọ giga gbogboniṣe Poly Ibadan ati bi awọn eeyan ṣe n lo Fasiti ilu Eko gẹgẹ bii apẹrẹ wi pe ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni agbara lati mu ki Gomina Makinde yi ipinnu rẹ pada gẹgẹ bi wọn ṣe mu ki aarẹ Goodluck Jonathan yi erongba rẹ pada l'ọdun meloo kan sẹyin, Akintọla ni awọn akẹkọọ UNILAG ko girigiri ba aarẹ Jonathan, ninu ibẹrubojo lo si fi yọwọ ninu ayipada orukọ ile ẹkọ naa.

Akintọla ni bi o ba jẹ pe oun ni Ṣeyi Mankinde ni, oun ko ni yi ipinnu oun pada lori ayipada orukọ Poly Ibadan, nitori Oloogbe Ọmọlolu Olunlọyọ ti wọn fi orukọ tuntun naa bu ọla fun fi ara jiya fun aṣeyọri ile ẹkọ giga naa.

O ni ijọba yi orukọ fasiti Ile-Ifẹ pada si 'Ọbafẹmi Awolọwọ University' ẹnikẹni ko ri nnkan ṣe si i nitori pe adinku tabi irẹsilẹ ko ba ojulowo ẹto ẹkọ ti awọn akẹkọọ n kọ nile ẹkọ giga naa.

O ni, "ojo ti ẹru n ba ni aarẹ Jonathan to fẹ yi orukọ fasiti Eko si MKO Abiọla. Nigba ti wọn yi orukọ fasiti Ile-Ifẹ pada si Ọbafẹmi Awolowo, ọpọlọpọ lo fi ẹhonu han. Awa yii gan ko ba fasiti Ifẹ ni Ọbafẹmi Awolowo. Ojulowo ẹkọ ti awọn eeyan n kọ ni fasiti Ifẹ ṣi wa bakan naa titi di oni."

O fi kun ọrọ rẹ wi pe aini ẹkọ nipa itan Naijiria lo mu ki awọn ọmọ isin ti ọpọ mọ si "Gen-Z" maa ṣe iwọde nitori ayipada orukọ ile ẹkọ wọn.

A kan si alakaso ẹgbẹ awọn akẹkọọjade ni Poly Ibadan, 'The Polytechnic Ibadan Alumni Association' Ọjọgbọn Akinloye Lawal lati mọ boya wọn gbero ati fi ẹsẹ ofin tọ ayipada orukọ ile ẹkọ naa, alaye ti Lawal ṣe fun akọroyin wa ni pe Gomina Ṣeyi Makinde ki i ṣe ẹni ti awọn le gbe lọ si ile ẹjọ, ọwọ ẹbẹ naa ni awọn o ra si i.

Ọjọgbọn naa rọ Makinde latiṣe awokọṣe awọn ile eko giga bi i fasiti ilẹ Ibadan ati ti ilu Eko, nibi to jẹ pe oruko awọn ẹka eto ẹkọ ati awọn ileigbe akẹkọọọ nikan ni wọn n yipada lati bu ọla fun awọn eeyan to ti ṣe ohun manigbagbe l'awujọ.

Lawal ni, "igbesẹ ti a fẹ gbe ni lati parọwa si Gomina wa. Eleyii kọ ni igbesẹ akọkọ ti awọn Gomina ti gbe ri, ti awọn eeyan si maa n tọ wọn sọna, ti wọn a si gbọ.

Paapaa julọ Gomnina wa ana, Ọmọlolu Olunlọyọ. Oun gan an ni alakoso akọkọ ni Poly Ibadan ni aye ijọba ẹlẹkunjẹkun, o si gbiyanju gan an, a fẹran rẹ l'ọpọlọpọ.

Igbesẹ wa ki i ṣe ọrọ ikọrira, ṣugbọn a ko fẹ ki wọn yẹpẹrẹ orukọ Poly Ibadan ni".

Ọjọgbọn Lawal fi kun ọrọ rẹ wi pe awọn Ọjọgbọn mejila ọtọọtọ lo ti jade lati Poly Ibadan, awọn Ọmọwe ko si ni onka. Nitori idi eyii si ni wọn ko ṣe fẹ ohunkohun ti yoo tabuku iyi ti ile ẹkọ giga naa ni.

Lara awọn eeyan jankanjankan to ti kẹkọọ jade ni ile ẹkọ giga gbogboniṣe Poly Ibadan ni Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja II, Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ogun, Ọtunba Gbenga Daniel, Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ekiti, Ayọ Fayoṣe, Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ọṣun, Rauf Arẹgbẹṣọla, ọmọ ile igbimọ aṣojuṣofin tẹlẹri, Dapọ Lam Adeṣina ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Wo awọn ile ẹkọ ti ijọba yi orukọ wọn pada lorilẹede Naijiria

''Fasiti ipinlẹ Ekiti, "Ekiti State University, Ado-Ekiti", ti pa orukọ da nigba mẹrin ọtọọtọ.

O bẹrẹ pẹlu "Obafemi Awolowo University" laarin ọdun 1982 si 1985, o yipada si "Ondo State University" laarin ọdun 1985 si 1999, o tun gba orukọ tuntun, "University of Ado-Ekiti" laarin ọdun 1999 si 2011, ki o to wa di "Ekiti State University" l'ọdun 2011 titi di asiko yii.

*Fasiti Ile-Ifẹ yi orukọ pada si "Obafemi Awolowo University(OAU)" l'ọdun 1987 lati bu ọla fun Oloogbe Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ ni iranti ipa ribiribi to ninu eto ẹkọ ati idagbasoke ẹkun Iwọ-oorun.

*Fasiti ijọba apapọ, The Federal University of Agriculture, Umudike", yipada si "Michael Okpara University of Agriculture" lọjọ kẹtala ọṣu kọkanlẹ ọdun 1992.

*Fasiti ipinlẹ Ogun, "Ogun State University" yi orukọ pada si "Olabisi Onabanjo University" ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kaarun ọdun 2001.

*Fasiti ijọba apapọ, "The Federal University of Agriculture Makurdi" pa orukọ da si "Joseph Sarwuan Tarka University" l'ọdun 2019.

*Ijọba apapọ ṣe ayipada orukọ fasity ilu Abuja si "Yakubu Gowon University" lọjọ kẹrindinlogun oṣu kejila ọdun 2024.

Wonyii ni awọn ile ẹkọ giga ti ijọba gbiyanju lati yi orukọ wọn pada ṣugbọn to kuna

*Federal University, Oye Ekiti (FUOYE)

*The University of Lagos (UNILAG)

L'ọdun 2012, aarẹ Goodluck Jonathan gbero lati yi orukọ fasiti ilu eko, UNILAG pada si orukọ Oloogbe Oloye Chief Moshood Abiola (Moshood Abiola University of Lagos, MAULAG), ṣugbọn o koju atako lọdọ awọn akẹkọọ, ẹgbẹ awọn akẹkọọjade ati awọn alẹnulọrọ. Iwọde ti wọn ṣe lati ti afara 3rd Mainland Bridge pa lo mu ki ijọba yi erongba rẹ pada.

*Federal University of Technology, Akure (FUTA)

Bakan naa ni ijọna aarẹ Jonathan gbiyanju lati yi orukọ fasiti ijọba apapọ, "Federal University of Technology, Akure (FUTA)" pada si "Shehu Shagari University of Technology", ṣugbọn igbesẹ naa kuna nitori ariwo sọ wi pe ki lo so Shagari lati ipinlẹ Ṣokoto pọ mọ ile ẹkọ giga to n bẹ niluu Akure, ipinlẹ Ondo.

Nibi eto isinku Gomina ologun tẹlẹri, Oloogbe Adeyinka Adebayọ, ni igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo ti kede wi pe ayipada yoo ba orukọ fasiti ijọba apapọ, "Federal University, Oye Ekiti (FUOYE)", ṣugbọn ariwo ti awọn eeyan kan pa n'ipinlẹ Ekiti lo ki ijọba apapọ yi ipinnu rẹ pada.