Ta làwọn agbébọn tó ṣekúpa èèyàn tó lé ní mẹ́wàá l'Anambra

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko din ni eeyan mẹwaa ti awọn afurasi agbebọn kan ṣekupa ni ipinlẹ Anambra ni ẹkun ila oorun Gusu orilẹede Naijiria.
Iṣẹlẹ yii waye niluu Ogboli ni guusu ijọba ibilẹ Orumba nipinlẹ naa lasiko ti awọn eeyan kan ko arawọn jọ lati ṣe ipade ọmọ ilu kan nibẹ.
Ọpọ awọn eeyan ti ibọn ba ni wọn jẹ ọmọ ipinlẹ Ebonyi.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Tochukwu Ikenga, ninu atẹjade kan to fi lede ṣalaye pe awọn agbebọn de ibudo ipade pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ SUV, ti wọn si sina ibọn fun awọn eeyan to wa nibi ipade ọhun.
Digbadigba ni wọn gbe awọn eeyan yii lọ si ile iwosan, to si jẹ pe ibẹ ni eeyan mẹwaa ti padanu ẹmi wọn. Wọn ti gbe oku awon eeyan yii lọ si ile igbeokupamọ si .
Ohun to fa ikọlu naa ṣi ṣokunkun si awọn eeyan atawọn alaṣẹ nibẹ, bẹẹni a ko tii le fi idi rẹ mulẹ pẹlu.
Awọn agbofinro ti wa ni ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, ti wọn si ti gboyanju iwaddi lati ṣawari awọn agbebọn.
Iṣẹlẹ iṣekupani lati ọwọ awọn agbebọn ti n peleke sii, ti ọpọ eeyan si ti padanu ẹmi wọn ni ọpọ igba nipinlẹ Anambra.
Ni ọsẹ to kọja nipinlẹ Anambra, awọn agbebọn yii ṣekupa eeyan meji, ji eeyan meji gbe, ti ọpọ eeyan si tun farapa yanayana lẹyin ti wọn kọlu agbegbe Oko.
Bakan naa nipinlẹ Enugu, awọn agbebọn yawọ ilu Eha-Amufu ni ijọba ibilẹ Isiuzo , ti wọn si ṣekupa eeyan mọkanla.
Iṣẹlẹ yii waye lọjọ Aje, ọjọ Kẹrinledinlogun oṣu kẹfa ọdun 2025, lasiko ti awọn araalu n sun lọwọ.
Eyi ki n ṣe igba akọkọ ti irufẹ iṣẹlẹ naa yoo waye ni ilu Eha-Amufu..
Olugbe agbegbe naa, Ifeanyi Ogenyi, sọ fun BBC bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, to si jẹ ko di mimọ pe awọn daradaran ti kuro ninu igbo ti wọn wa tẹlẹ, ti wọn si n wa sinu ilu lati ṣekupa awọn araalu.















