Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Poly Ibadan ṣe ìwọ́de tako àyípadà tó bá orúkọ ilé ẹ̀kọ́ wọn

L'owurọ ọjọ Iṣẹgun ni ọgọrọ awọn akẹkọọ ile ẹkọ giga gbogboniṣe Poly Ibadan fọn si igboro ilu Ibadan lati fi ẹhonu han lori ayipada orukọ ile ẹkọ giga naa si orukọ Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ọyọ, Oloogbe Victor Ọmọlolu Olunlọyọ.
Gbogbo ẹnu ọna to wọ ile ẹkọ giga naa ni awọn akẹkọọ tipa ki wọn to wọde lọ si ọfisi Gomina ipinlẹ Ọyọ to n bẹ ni agbegbe Agodi n'Ibadan.
Bi wọn ṣe n fi ẹhonu han pẹlu ọkanojọkan orin ni wọn tun kọ oriṣiriṣi akọle lọwọ. Lara awọn nnkan ti wọn kọ ni, "Gomina to fẹran akẹkọọ, jọwọ tẹti si wa, Poly Ibadan ni a fẹ, a ko fẹ Ọmọlolu Olunlọyọ".
Nigba ti wọn ṣe ifẹhonuhan naa fun iṣẹju meloo kan niwaju ọfisi Gomina ipinlẹ Ọyọ ni igbakeji Gomina, Bayọ Lawal yọju si wọn.
Ọrọ ti Lawal ba awọn akẹkọọ naa sọ ni pe oun mo riri igbesẹ ti wọn gbe nipa ṣiṣe ifẹhọnuhan naa gẹgẹ bii ọmọluabi lai hu iwa janduku.
O ni Gomina Ṣeyi Makinde ko si nile bayii, ṣugbọn awọn o jiṣẹ fun un nigba to ba de. Igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyọ ko tii fi bẹẹ sọrọ to nnkan ti ariwo awọn akẹkọọ naa fi bo tiẹ mọlẹ.
Ọkan lara aṣoju awọn akẹkọọ naa to ba awọn oniroyin sọrọ nibi iwọde naa ṣe alaye wi pe bi igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Bayọ Lawal ṣe jade si awọn akẹkọọ to n ṣe ifẹhonuhan dun mọ awọn ninu nitori lara nnkan ti awọn fẹ naa ki ijọba mọ wi pe inu awọn ko dun si igbesẹ ti wọn gbe. O ni nnkan ti awọn n reti ni ki Gomina Ṣeyi Makinde naa wa ba awọn sọrọ nigba to ba ti ibi irinajo to lọ de.

Adele alakoso ile ẹkọ giga naa Ọmọwe Taiwo Abideen Lasisi naa ba wa sọrọ niwaju ọgba ile ẹkọ giga nibi ti awọn oṣiṣẹ kan ko ti ri ọkọ gbe wọle nitori agadagodo ti akẹkọọ naa sọ si awọn ẹnu ọna to wọ inu ọgba ile ẹkọ wọn.
Alaye ti Lasisi ṣe fun akọroyin wa ni pe ni nnkan bii aago meji oru ni awọn ẹṣọ aabo to n ṣọ ile ẹkọ giga naa ke si oun wi pe awọn akẹkọọ kan ti n gbe ẹnu ọna abawọle sile ẹkọ giga naa ti. Nigba ti yoo si fi di owurọ oni, awọn eeyan to gbe ọkọ wa ko ri aye wọle sinu ọgba ile ẹkọ naa.
Lasisi ni ijọba ipinlẹ Ọyọ ni ẹtọ lati yi orukọ ile ẹkọ naa pada si nnkan to ba wu wọn nitori pe awọn ni wọn ni ile ẹkọ giga naa.
O fi kun ọrọ rẹ wi pe inu awọn alakoso ile ẹkọ giga naa dun si igbesẹ ti ijọba ipinlẹ Ọyọ gbe nitori awọn ko ri nnkan to buru nibẹ.
Ki lo ṣẹlẹ saaju asiko yii?

Laarin ọsẹ to kọja ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde wi pe ayipada yoo ba orukọ ile ẹkọ giga gbogboniṣe Poly Ibadan, lati bu ọla fun Oloogbe Victor Ọmọlolu Olunlọyọ to Gomina tẹlẹri ni'ipinlẹ Ọyọ.
Yatọ si ipo Gomina ipinlẹ Ọyọ ti Oloogbe naa ti wa tẹlẹ ri, Olunloyo ni Giwa agba akọkọ to ṣe akoso ile ẹkọ giga naa l'ọdun 1970 ki o to tẹwọgba iṣakoso ipinlẹ Ọyọ fun oṣu meloo kan laarin ọjọ kinni oṣu kẹwaa si ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun 1983.
Lati ọjọ ti Gomina Makinde ti ṣe ikede naa ni ọkanojọkan awuyewuye ati ifẹhonuhan ti n lọ lori itakun ayelujara nitori ikede naa.
Apapọ ẹgbẹ awọn akẹkọọ tẹlẹri ati awọn to n kẹkọọ lọwọ lo si ti kọ iwe ranṣe si Gomina Makinde wi pe ko yi ero rẹ pada lori ayipada orukọ ile ẹkọ giga naa.
Ohun ti a mọ nipa ile ẹkọ giga gbogboniṣe Poly Ibadan

Ninu oṣu kẹjọ ọdun 1970 ni wọn ṣe idasilẹ ile ẹkọ giga gbogboniṣe Poly Ibadan, idasilẹ yii waye gẹgẹ bii agbega fun ile ẹkọ ti a ti n kọ nipa iṣẹ ọwọ, 'Technical College, Ibadan.'
Ọpọlọpọ atunṣẹ lo si ti waye si iwe apilẹkọ ti a fi ṣe agbekalẹ ile ẹkọ giga naa ki o le wa ni ibamu pẹlu awọn nnkan ti ijọba ipinlẹ Ọyọ lero pe yoo ṣe anfani fun ipinlẹ naa ati orilẹede agbaye l'apapọ.















