Kí ló ṣokùnfà òfin 'o ò wọ kọ́mú, o ò ṣe ìdánwò' àti bí àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò ṣe fọwọ́ yẹ ọmú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wò ní fásitì Olabisi Onabanjo?

Àkọlé fídíò, Kí ló ṣokùnfà òfin ‘o ò wọ kọ́mú, o ò ṣe ìdánwò’ ní fásitì Olabisi Onabanjo?
Kí ló ṣokùnfà òfin 'o ò wọ kọ́mú, o ò ṣe ìdánwò' àti bí àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò ṣe fọwọ́ yẹ ọmú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wò ní fásitì Olabisi Onabanjo?

Lẹyin ti fọran fidio kan la igboro kọja eyi to ṣe afihan awọn oṣiṣẹ fasiti Ọlabisi Ọnabanjọ, OOU kan ti wọn n fọwọ kan aya awọn akẹkọọ obinrin ni fasiti naa lati mọ boya wọn wọ kọmu tabi wọn ko wọ ki wọn to wọ gbọngan idanwo, ni oniruuru ọrọ ti n jade si igbesẹ naa.

Bi awọn kan ṣe n bu ẹnu atẹ lu u lawọn miran n kan sara si igbesẹ naa gẹ̀gẹbi eyi to tọna.

BBC Yoruba ṣe abẹwo si ile ẹkọ naa lati gbọ ọrọ lẹnu awọn akẹkọọ ile ẹkọ giga fasiti ọhun.

Awọn akẹkọọ to sọrọ ṣalaye pe lootọ ni iṣlẹ naa waye, bi o tilẹ jẹ wi pe awọn ko fara mọ igbesẹ fifi ọwọ tẹ awọn akẹkọọ obinrin laya ni gbangba, sibẹ ko si akẹkọọ kankan ti wọn da pada sile nitori aiwọ kọmu lọjọ naa.

Aarẹ ẹgbẹ akẹkọọ ni ile ẹkọ giga fasiti naa pẹlu ṣalaye pe iwe ofin ati ilana fun awọn akẹkọọ, eyi ti ile ẹkọ naa gbe kalẹ fun awọn akẹkọọ ti laa kalẹ yekeyeke pe ile ẹkọ giga naa ko faaye gba iwọkuwọ aṣọ eleyi ti ko si ṣokunkun si eyikeyi awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa.