Ìjọba Seyi Makinde, ẹgbẹ́ òṣèlú APC tako arawọn lórí ₦63.5bn tí wọ́n fẹ́ fi tún ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ṣe
Ọrọ nipa ileigbe Gomina ti ijọba ipinlẹ Ọyọ kede rẹ wi pe yoo jẹ titunṣe pẹlu owo to le ni Billiọnu mẹtalegọta Naira.
Ọpọlọpọ awuyewuye ni ikede naa ti mu lọwọ, bẹrẹ lati ori itakun ayelujara ati ọdọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako.
BBC Yoruba kan si ijọba ipinlẹ Ọyọ lati tan imọlẹ si ariwo ti awọn eeyan n pa lori igbesẹ naa. Alaye ti Kọmisana fun eto iroyin n'ipinlẹ Ọyọ, Ọmọọba Dọtun Oyelade ṣe fun akọroyin wa ni pe ojule mọkalelogun ọtọọtọ lo nilo atunṣe njnu ọgba ile igbe naa. Oyelade ni ẹni kankan ko ke gbajare lori ọgọsan an billiọnu Naira ti Gomina Ṣeyi Makinde fi n san owo oṣu awọn oṣiṣẹ lọdọọdun ati awọn iṣẹ ribiribi mii ti ijọba n ṣe fun araalu, ṣugbọn ọrọ ile ti Gomina ati awọn alejo rẹ fẹ maa de si lo wa di ariwo.
Ibudo ibalẹ si baluu Hẹlikọputa yoo wa ninu atunṣe ti a fẹ ṣe - Ijọba ipinlẹ Ọyọ

Oríṣun àwòrán, BBC/others
Lara awọn nnkan ti ijọba ipinlẹ Ọyọ fẹ ṣe si ileigbe naa ni ibi ti ọkọ ofurufu ẹlikọputa yoo maa ba si, iyẹn 'Helipad.
Komisana fun eto iroyin n'ipinlẹ Ọyọ tun fi kun ọrọ rẹ wi pe lara awọn iredi ti owo naa fi pọ ni pe oke okun ni wọn o ti ra gbogbo ohun elo ikọle ti wọn fẹ lo si ileigbe naa, ati wi pe "gbogbo ni a mọ nnkan ti Dollar n sọ".
Bakan naa ni a ba alukoro ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ, Wale Sadare sọrọ, alaye to ṣe ni pe ko si nnkan to buru ninu atunṣe ti ijọba ipinlẹ Ọyọ fẹ ṣe, ṣugbọn owo ti wọn bu fun akanṣe iṣẹ naa ti pọ ju.
Sadare ni ọpọlọpọ eeyan ipinlẹ Ọyọ ni billiọnu mẹtalelọgọ Naira le yọ kuro ninu iṣẹ ati oṣi, bi ijọba ba na owo naa bi o ti tọ.







