Kí ló mú eégún mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ dèrò ẹ̀wọ̀n láìrò tẹ́lẹ̀? Àlàyé rèé

Ile ẹjọ Majisireeti kan ti ju eegun mẹta ọtọọtọ si ọgba ẹwọn lori ẹsun fifi ẹgba lu awọn araalu, ti ọpọ si farapa lasiko ọdun eegun Oriokpa nipinlẹ Enug.
Awọn afurasi eegun ọhun, Emeka Eze ọmọ ọdun mẹtalelọgbọn, Omeke Uchechukwu ọmọ ọdun mejilelogun, ati Malachi Nnaemeka toun jẹ ọmo ọgbọn ọdun ni ọwọ awọn agbofinro tẹ lọjọ Isẹgun to kọja, ọjọ Kẹrinlelogun oṣu kẹfa ọdun yii nipinlẹ Enugu.
Ileeṣẹ ọlọpaa lo wọ awọn afurasi yii lọ si ile ẹjọ, ti wọn si ka ẹsun mẹta si wọn lẹsẹ pe wọn gbimọ pọ lati se awọn eeyan ni ijamba, ti wọn si tun gba owo lọwọ wọn.
Ninu atẹjade to fi lede, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Enugu, Daniel Ndukwe, ni ọpọ eeyan ni awọn afurasi yii lu lẹgba, ti wọn si farapa pupọ lasiko ọdun eegun Oriokpa.
Ndukwe ni ile ẹjọ ti sun igbẹjọ siwaju di ọjọ Kọkanlelọgbọn, oṣu Keje ọdun yii, ṣugbọn awọn afurasi naa si ma gba atẹgun lọgba ẹwọn titi di akoko naa.
"Kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Enugu ti pa a lasẹ pe ki a ṣawari awọn eeyan yooku ti wọn ṣalọ lẹyin ti wọn ṣiṣẹ bi wọn tan," Ndukwe ṣalaye.
Ni ọjọ Kejilelogun ni fọnran kan lu sita lori ayelujara, eyi to ṣafihan awọn eegun ọhun ni ọna Aku niluu Nsukka ti wọn n ko ẹgba bo awọn araalu.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọkunrin kan dero ile iwosan lẹyin ti wọn ko ọpọlọpọ ẹgba bo o.














