Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa gbajúmọ̀ olóòtú eré Nollywood Kayode Peters tó jáde láyé ní Canada

Oríṣun àwòrán, Kayode Peters/Instagram
Ọjọ ti a ba ku la a dere, eeyan o ṣunwọn laaye, gbajumọ olootu ati adari ere Nollywood, Kayode Peters Adewumi, ti ọpọ eeyan mọ si Kayode Peters ti jade laye.
Ẹbi Adewumi lo kede iku gbajumọ olooto ere naa ninu atẹjade kan ti wọn fi sita loju opo Instagram rẹ.
Ninu atẹjade naa ni ẹbi oloogbe ti sọ pe kayode jade laye lẹyin to ti ṣe aisan fun igba pipẹ niluu Toronto lorilẹede Canada.
Gẹgẹ bi ẹbi Adewumi ṣe ṣalaye lori Instagram, lọjọ Satide ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹfa yii ni Kayode Peters dagbere faye.
Ẹbi Adewumi sọ ninu atẹajade ti wọn fi sita pe ''pẹlu ibanujẹ ọkan ni a fi kede iku Kayode Peters Adewumi ẹni to dagbere faye laarọ ọjọ Abamẹta, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹfa yii niluu Toronto ni Canada.
KP ja fita fita, o si ṣẹgun aisan to ti n ṣe e fun ọjọ pipẹ titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ laarọ ọjọ Satide.
KP jẹ ọmọ wa ti fẹran, ọkọ, baba ati ọrẹ, ogbontarigi olooto ere, oṣere ati adari ere ti awọn iṣẹ to ṣe jẹ koriya fun ọpọ eeyan.
Yatọ si pe Eledua fun lẹbun to fi pegede lẹnu iṣẹ, awọn eeyan tun mọ KP gẹgẹ bi alaanu ati ẹni to ni ẹmi ififuni.
Bi a ṣe n ṣọfọ KP lọwọ, a rọ gbogbo eeyan lati ṣe gaaya fun ẹbi wa lasiko yii.
A o kede asiko ti eto isinku rẹ yoo waye laipẹ bi ọkan wa ba ti le diẹ.
Ẹ ṣe e fun ibanikẹdun yin ati atilẹyin ti ẹ n ṣe fun wa.''
Ẹbi oloogbe ni Kayode Peters ko ipa ribi ribi ninu aye ọpọ eeyan nigba aye rẹ, eyi ni yoo si jẹ ki ọpọ eeyan maa ṣafẹri rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ta a ni Kayode Peters gbajumọ olootu ere Nollywood to jade laye?
A bi Kayode Peters si ilu Ibadan ni ipinlẹ Oyo lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹsan lọdun 1975.
Ede Gẹẹsi ni Kayode kẹkọọ gboye ninu rẹ ni ile ẹkọ giga fasiti UNILAG niluu Eko.
Lati igba to ti wa ni ile ẹkọ giga fasiti UNILAG naa lo ti bẹrẹ sii kopa ninu ere siṣe.
Kayode Peters di ilumọọka ninu ere didari nigba to dari ere ẹfẹ Papa Ajasco tawọn eeyan maa n wo lori ẹrọ amohunmaworan.
Lẹyin naa ni o ṣe olootu gbajugbaja ere Flatmates ninu eyi tawọn adẹrinpoṣonu bii Basketmouth ati Okey Bakassi ti kopa.
Onigbagbọ ọmọ lẹyin Kristi ni Kayode Peters jẹ ni gbogbo ọjọ aye rẹ.
Kayode Peters ṣe igbeyawo pẹlu gbajugbaja arinrin-oge ati oṣere ori itage, Tayo Sobola.
Edumare si fawọn ọmọ to dara jinki idile wọn.
Kayode ati iyawo rẹ Tayo kii ṣe oni afẹfẹyẹyẹ, iṣẹ wọn ni wọn gbaju mọ.















