'Lẹ́yìn tí ọmọbìnrin mi ọmọ ọdún márùn-ún gba bisikíìtì jẹ lọ́wọ́ ọlọ́jà kan ló kú'

Aworan oloogbe

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Baba ọkan ninu ọdọmọbinrin meji to jade laye lẹyin ti wọn jẹ bisikiti ibilẹ kan lorilẹede Cameroon ti pe fun iwadii ati ayẹwo lori ohun pato to ṣekupa ọmọ rẹ obinrin.

Ọgbẹni Belmond, to jẹ ontaja ni ibanujẹ ọkan ba lẹyin ti ọpọ ọmọde jẹ bisikiti ti ọmọ rẹ jẹ ṣugbọn ọmọ rẹ Makeda, ọmọ ọdun marun un ati ọmọ mi nikan lo jade laye lẹyin to jẹ bisikiti ọhun.

"N ko si nibẹ ṣugbọn awọn eeyan ni o jẹ bisikiti. Ko ki n ṣe awọn ọmọ yii nikan ni wọn jẹ bisikiti yii ṣugbọn awọn meji nikan lo padanu ẹmi wọn, kilode?

O ni iwadii nikan lo le tan imọlẹ si iṣẹlẹ yii lati mọ ohun pato to ṣekupa oloogbe naa.

Ki lo ṣẹlẹ?

Baba Oloogbe

Oríṣun àwòrán, Others

Ni ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa ọdun 2025, ọmọ meji ti wọn jẹ obinrin padanu ẹmi wọn, ti ọpọ ọmọ mii si dero ile iwosan ni Douala lorilẹede Cameroon lẹyin ti wọn jẹ bisikiti ibilẹ kan to gbajumọ.

Awọn alaṣẹ ni ilu naa sọ pe awọn ọmọde yii ti wọn jẹ ọmọ ọdun kan si mẹrindinlogun ni wọn bẹrẹ sini dubulẹ aisan lẹyin ti wọn jẹ bisikiti.

"Awọn ọmọde yii jẹ bisikiti galattes, ti wọn ke pe inu n ro awọn. Eeyan meji ti padanu ẹmi wọn bayii ni ile iwosan New Bell," Gomina Littoral Region ṣalaye.

O fikun pe o le ni ọgọrun un ọmọde to wa ni ile iwosan bayii, ti wọn n gba itọju.

Olori ile iwosan Laquintinie fi da awọn araalu loju pe awọn yoo ṣe itọju awọn ọmọ naa, ki wọn fọkan wọn balẹ.

Dokita Marie Solange Ndom Ebongue to ba awọn akọroyin sọrọ ni awọn ti bẹrẹ sini ṣe iwadii lori irufẹ ohun to inu riro naa.

" Ni ile iwosan Laquintinie, ọmọde 105 ni a gba. Ko si ẹnikẹni to ku ninu wọn. Gbogbo awọn ti a tọju ti lọ si ile wọn. A ti ṣe iwadii lati mọ ohun pato to fa eyii," o ṣalaye.

Dokita Marie Solange Ndom Ebongue

Oríṣun àwòrán, Others