Ìbúgbàmù ṣekúpa akẹ́kọ̀ọ́ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n lásìkò ìdánwò

Oríṣun àwòrán, Ulrich Tobet
- Author, Vianney Ingasso & Damian Zane
- Role, BBC News, Bangui & London
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n tí wọ́n ń ṣe ìdánwò lọ́wọ́ ní orílẹ̀ èdè Central African Republic ti pàdánù ẹ̀mí wọn bí ìbúgbàmù ṣe wáyé lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé ẹ̀kọ́ wọn.
Adarí ilé ìwòsàn Bangui Community Hospital, Abel Assaye sọ fún BBC pé ọjọ́ kejì táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà bẹ̀rẹ̀ ìdánwò àṣekágbá wọn ni ìbúgbàmù náà wáyé.
Assaye ṣàlàyé pé ẹ̀rọ amúnáwá "transformer" ló fa ìbúgbàmù náà.
"Ariwo látàrí ìbúgbàmù àti èéfì tó ń jáde láti ibẹ̀ ló dá ìpayà sáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń ṣe ìdánwò baccalaureate ní olú ìlú orílẹ̀ èdè náà, Bangui, gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ rédíò abẹ́lé, Ndeke Luka ṣe sọ.
Ààrẹ Fuastin-Archange Touadéra ti kéde ọjọ́ láti fi dárò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.
Bákan náà ló ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó lé ní 280 tí wọ́n ṣèṣe níbi ìkọlù náà ni kí wọ́n tọ́jú lọ́fẹ̀ẹ́.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ilé ẹ̀kọ́ márùn-ún ni wọ́n ń ṣe ìdánwò baccalaureate ní Lycée Barthélémy.
Iléeṣẹ́ ètó ẹ̀kọ́ ní orílẹ̀ èdè Central African Republic sọ pé ìbúgbàmù náà wáyé lẹ́yìn tí iléeṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná gbé iná lé ẹ̀rọ amúnáwá náà èyí tó wà lábẹ́ ilé ẹ̀kọ́ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wà.
Wọ́n ní àtúnṣe iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ níbi ìsàlẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ tí ìbúgbàmù ọ̀hún ti wáyé.
Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́, Aurelien-Simplice Kongbelet-Zimgas sọ nínú àtẹ̀jáde kan pé àwọn bá òbí àwọn ọmọ tó jáde láyé kẹ́dùn àti pé àwọn gbàdúrà kí ara àwọn tó farapa padà bọ̀ sípò láìpẹ́.
Ó tún kéde pé àwọn ti ṣe ìdádúró àwọn ìdánwò tó kù tí wọ́n máa ṣe.
Akẹ́kọ̀ọ́ obìnrin kan tó móríbọ́ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá BBC sọ̀rọ̀.
"Mi ò rántí ohun tó ṣẹlẹ̀. A wà nínú yàrá tí a ti fẹ́ ṣe ìdánwò nígbà tí mo gbọ́ ariwo, mo dákú lọ bẹ́ẹ̀. Láti ìgbà náà ni ìsàlẹ̀ ikùn ti ń dùn mí, èyí tó jẹ́ kí n máa wà nínú ìrora."
Iléeṣẹ́ rédíò, Radio France Internationale náà bá akẹ́kọ̀ọ́ míì tí ẹ̀jẹ̀ bo gbogbo ojú rẹ̀ lẹ́yìn tó gba ojú fèrèsé sá jáde.
Magloire ṣàlàyé pé lásìkò táwọn ń ṣe ìdánwò "history àti geography" ni ìbúgbàmù náà wáyé.
"Báwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń gbìyànjú láti dóòlà ẹ̀mí ara wọn, ni wọ́n ń sá jáde, ọ̀pọ̀ ló rí ikú tán nítorí ẹnu ọ̀nà láti gbà kọjá kéré, tí èrò sì pọ̀ lójú ọ̀nà. Kìí ṣe gbogbo èèyàn ló le ríbi jáde," ó sọ fún RFI.
Orílẹ̀ èdè CAR ló kojú ọ̀pọ̀ ìpèníjà, tó fi mọ́ ètò ààbò, òṣèlú àti ìdúró ire ètò ọrọ̀ ajé.
Iléeṣẹ́ ológun ìjọba èyí tí àwọn ajàgùntà Russia ń ṣe àtìlẹyìn fún ń kojú àwọn agbébọn tó ń dúnkokò láti gbàjọba lọ́wọ́ Touadéra.
Àfikún ìròyìn látọwọ́ BBC Monitoring















