Olóyè dèrò àhámọ́ ọlọ́pàá l'Ondo lórí ẹ̀sùn pé ó há ọmọdébìnrin mọ́lé, hu ìwà kòtọ́ pẹ̀lú rẹ

Aworan ọkunrin to dori kodo ninu ọkọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oloye kan niluu Laaagba ni ijọba ibilẹ ila oorun Ondo, Adeniyi Ifedayo, ti dero atimọle ọlọpaa lori ẹsun pe o ji ọmọdebinrin ọdun mejila gbe ti o si tun fipa ba a lopọ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Olayinka Ayanlade, lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC Yoruba.

Ohun ti a gbọ ni pe Oloye Ifedayo tan ọmọbinrin naa wọ ile rẹ, nibi ti o ti i mọ fun ọsẹ meji.

Fun ọsẹ meji yii ni a gbọ pe Oloye Ifedayo ti fipa ba ọmọde naa lopọ.

Ẹnikan to n gbe ni agbegbe ti iṣẹlẹ ọhun ti wáyé, sọ fawọn akọroyin wi pe afurasi ọlọkada kan lo gbe ọmọ naa lọ si ile oloye naa.

Ẹni to wa lagbegbe ti iṣẹlẹ ọhun ti waye fikun ọrọ rẹ pé, ẹkọ ni Oloye naa n fun ọmọbinrin ọhun mu lojoojumọ, ti o si n tun fipa ba a lopọ.

''Ọlọkada tí wọ́n fura sí pé ó ṣiṣẹ pọ pẹlu Oloye Ifedayo ti na papa bora''

Wàyí o, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ni ìpínlẹ̀ Ondo tí fi idi ìṣẹ̀lẹ̀ náà mulẹ fun BBC Yoruba.

Nígbà tó ń bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀, Agbẹnusọ fún ileeṣẹ ọlọpaa Ondo, Olayinka Ayanlade sọ pe afurasi ọlọkada to ṣiṣẹ pọ pẹlu Oloye Ifedayo ti sá lọ.

O fikun pé ileeṣẹ ọlọpaa si n wa ọlọkada yii.

''Awa ọlọpaa n sa gbogbo agbara ati ipa wa lati mu afurasi to ṣiṣẹ pọ pẹlu oloye naa.

Oloye Ifedayo ti wa ni atimọle ọlọpaa bayii, a n gbiyanju lati wa gbogbo ẹri lori iṣẹlẹ naa.

Iwadii si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa, afurasi oloye yii yoo foju ba ile ẹjọ lẹyin ti a ba ti pari iwadii ti a n ṣe lori iṣẹlẹ naa.

Afurasi ọlọkada to gbimọ pọ pẹlu Oloye Ifedayo naa yoo foju ba ile ẹjọ ti ọwọ ba ti tẹ ẹ.

Ọrọ naa ti de olu ile iṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo bayii fun iwadii fini fini lori iṣẹlẹ naa,'' Ayanlade lo sọ bẹẹ.

Ẹgbẹ akọroyin lobinrin rọ iléeṣẹ́ ọlọpaa láti máṣe fi igba kan bọ ọkan ninu lórí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ naa

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn akọroyin obinrin, NAWOJ, ẹka ti ipinlẹ Ondo ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ifipabanilopọ naa.

Alaga ati akọwe ẹgbẹ naa, Tola Gbadamosi ati Tosin Ighoteguono, ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lorukọ ẹgbẹ NAWOJ ke pe ijọba ipinlẹ Ondo atawọn ọlọpaa pe ki wọn ri pe awọn afurasi naa foju wina ofin.

Ẹgbẹ naa tun rọ ileeṣẹ ọlọpaa wi pe ki wọn máṣe fi igba kan bọ ikan ninu, ninu iwadii ti wọn n ṣe lori iṣẹlẹ naa.

Ẹgbẹ NAWOJ wa kepe awọn obi, alagbatọ atawọn eeyan lawujọ pe ki wọn gbiyanju lati maa daabo bo awọn ọmọde daadaa tori awọn oniṣẹ laabi to n huwa ipa si wọn.

Bakan naa ni ẹgbẹ ọhun tun ke pe ijọba lati fun ofin to n daabo bawọn ọmọde lagbara sii.