Wo ìlànà tuntun tí Canada kéde fún àwọn tó fẹ́ jápa wọ orílẹ̀èdè nàá lọ́dún 2025 sí 2026

Aworan to n sọ nipa irinajo lọ si Canada

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ajọ IRCC to n ri si ọrọ awọn eeyan to fẹ japa tabi di ọmo oniluu lorilẹede Canada lọdun 2025 si 2026 ti gbe alakalẹ ti wọn gbọdọ tẹle jade.

Ajọ to n ri si bawọn ara ilu okeere ṣe n wọle si Canada ti pinnu lati wa ojutuu si awọn iṣoro ileegbe ti ko to ati iṣoro nnkan amayedẹrun fawọn to ba fẹ japa lọ si orilẹede naa.

Ti ẹ o ba gbagbe, ijọba orilẹede Canada ti sọ ṣaaju pe bi ọpọ eeyan to n wọle si orilẹede naa n ṣakoba fun ọrọ aje, bakan naa lo tun n ṣakoba fun nnkan amayedẹrun ni Canada.

Amọ, alakalẹ tuntun ti ijọba fẹẹ ṣe yii ni ṣe pẹlu gbigba fisa, didi ọmọ oniluu ati gbigba iwe irinna to fi mọ ọrọ lori awọn akẹkọọ lati ilẹ okeere.

Minisita to n ri si ọrọ bawọn eeyan ti n wa si Canada lati ilẹ okeere, awọn ogunlende ati bawọn eeyan ṣe n di ọmọ oniluu, Lena Metlege Diab, sọ pe loootọ ni bawọn eeyan ṣe n wa si Canada lati ilẹ okeere dara fun ọrọ aje orilẹede naa, amọ, o fidi rẹ mulẹ pe o ṣe pataki lati mu adinku ba iye eeyan to wa ni Canada.

Lena sọ pe adinku yoo ba iye awọn to n wa ni Canada fun igba diẹ, ati pe ijọba yoo wa ojutuu si iṣoro aito awọn oṣiṣẹ.

''Ọpọ eeyan to ṣẹsẹ de Canada lo n gbero lati gbe igbe aye to dara ju eyi ti wọn n gbe tẹlẹ lọ.

''Nnkan to dara ni eyi jẹ loootọ fun orilẹede Canada, amọ, a o gbọdọ ṣe nnkan ti yoo ṣakoba fun orilẹede wa.

''A fẹ mu adinku ba awọn eeyan to n gbe Canada fun diẹ, a ko fẹ ki wọn ju ida 5% gbogbo eeyan to wa lorilẹede yii lọ.

''A fẹ sọ awọn to ni fisa lati ṣiṣẹ fun igba diẹ ni Canada di ọmo oniluu,'' Diab ṣalaye.

Minisita tun sọ pe Canada ko fẹ ki awọn eeyan ilẹ okeere to n di ọmo oniluu ju ida 1% gbogbo eeyan to wa ni orilẹede naa lọdọọdun lọ titi di ọdun 2027 and siwaju sii.

Alakalẹ lori awọn awọn alejo, akẹkọọ lati ilẹ okeere atawọn oṣiṣẹ ni Canada

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ajọ IRCC sọ pe awọn yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ajọ mii lati ri i daju pe awọn eeyan to n wọle si Canada koju oṣunwọn ki wọn to wọle.

Ajọ naa ni awọn yoo maa ṣe ayẹwo fisa awọn alejo, awọn oṣiṣẹ, awọn arinrin-ajo afẹ, awọn olokowo atawọn akẹkọọ lati ilẹ okeere to fẹ wa si Canada ba gba fini fini.

Lọdun 2023 nikan, fisa 6,645,353 ni Canada fawọn alejo, awọn akẹkọọ lati ilẹ okeere atawọn oṣiṣẹ.

Ṣugbọn ijọba Canada ko ni gba eeyan to to iye yii mọ, adinku yoo ba iye eeyan ti wọn fẹ fun ni fisa lọtẹ yii.

Ijọba ni bo tilẹ jẹ pe awọn to n ṣabẹwo si Canada fun igba diẹ ni ipa to dara lori ọrọ aje Canada, ṣugbọn o n ṣe ipalara fun ileegbe.

Idi niyii ti ijọba ṣe fẹ mu adinku ba iru awọn eeyan bayii lọdun 2026.

''Awọn to ba ṣẹṣẹ fẹẹ wa si Canada ni ọrọ kan to fi mọ awọn akẹkọọ lati ilẹ okeere atawọn oṣiṣẹ to lanfaani lati ṣiṣẹ ni Canada fun igba diẹ.

673,650 eeyan ti yoo wa Canada fun igba diẹ ni Canada n gbero lati gba lọdun 2025, 516,600 fun ọdun 2026, bakan naa ni wọn yoo gba 543,600 fun ọdun 2027.

Alakalẹ lori awọn to fẹ gbe Canada fun igba diẹ

Apapọ 305,900 akẹkọọ lati ilẹ okeere ni Canada yoo gba fọdun 2025, 2026 ati fun ọdun 2027.

82,000 awọn eeyan to fẹ ṣiṣẹ fun igba diẹ ni Canada yoo gba fọdun 2025, 2026 ati fun ọdun 2027.

285,750 eeyan to fẹ ṣiṣẹ labẹ eto IMP ni Canada fẹ gba fun 2025, 128,700 fun ọdun 2026 ati 155,700 fun 2027.

Alakalẹ tuntun yii yoo tun fun awọn arinrinajo lati orilẹede mẹtadinlaadọrin lanfaani lati rinrin ajo pẹlu iwe irinna ori ẹrọ kọmputa ti wọn n pe ni eTA dipo fisa.

Ijọba yoo tun ṣe ayẹwo iwe iyọnda ti wọn maa n fawọn lọkọ laya, awọn akẹkọọ atawọn oṣiṣẹ lati ilẹ okeere lati ṣiṣẹ fini fini lati ri pe Canada nilo wọn lẹka eto ilera ati ile kikọ.

Awọn ogunlende atawọn to fẹ di ọmọ oniluu

Ida 28.9% awọn oṣiṣẹ ni Canada lọdun 2023 lo jẹ awọn eeyan lati ilẹ okeere atawọn ogunlende.

Amọ, lati ọdun 2025 si 2027, ijọba yoo mu adinku ba iye eeyan ti yoo di ọmọ oniluu tori iṣoro ileegbe.

Gbogbo eeyan ti yoo di ọmọ onilu ko ni ju 380,000 lọ fun ọdun 2026 ati 365,000 fun ọdun 2027.

Awọn akẹkọọ atawọn oṣiṣẹ to ida 40% ninu awọn ti Canada sọ di ọmọ onilu lọdun 2025 yii.

Awọn eeyan to n wọle taara si Canada

Canada yoo fawọn eeyan ti wọn ti ni iriri lẹnu iṣẹ lati wọle taara si orilẹede naa, ti wọn yoo si di ọmọ oniluu lẹsẹ kẹsẹ.

Ajọ IRCC yoo mu awọn eeyan ti wọn ba gbọ èdè Faranse daadaa, awọn oṣiṣẹ eleto ilera atawọn onimọ nipa okowo ati eto ẹkọ lati sọ wọn di ọmọ oniluu.

Awọn ogunlende

Ijọba Canada yoo sẹ atunṣe lori awọn to n sa fun ogun ni orilẹede wọn lati wa fara pamọ ni Canada.

Ijọba yoo tun ṣiṣẹ lori awọn ogunlende ti ijọba n ṣe onigbọwọ wọn.

Eto yii yoo ṣe iranwọ fun ẹgbẹrun mejila ogunlende lati Afirika, ẹkun Middle-East, Asia ati ẹgbẹrun mẹrin ogunlende lati Amẹrika titi di ọdun 2028.

Iwe irinna

Ajọ IRCC yoo ṣe agbekalẹ eto kan ti yoo fawọn eeyan lanfaani lati le ṣe isọdọtun iwe irinna wọn lori kọmputa.

Ijọba yoo mu imugboro ba eto ti yoo fawọn ọmọde lanfaani lati gba iwe irinna bakan naa.

Ajọ IRCC yoo wa ojutuu si iṣoro to maa n koju awọn eeyan to ba fẹ di ọmọ oniluu ni Canada.