Ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fún akọrin ẹ̀mí, Timileyin Ajayi tó pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, Salome Adaidu

Salome Adaidu ati Timileyin Ajayi

Oríṣun àwòrán, Salome Adaidu Facebook/ Caeser.T

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Nasarawa tó fi ìlú Lafia ṣe ibùjókòó ti dájú ikú fún akọrin ẹ̀mí Oluwatimileyin Ajayi, fún ẹ̀sùn ṣíṣekúpa àgùnbánirọ̀, Salome Adaidu.

Ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà ni Adájọ́ Simon Aboki tó gbọ́ ẹjọ́ náà ní kí wọ́n lọ yẹgi fún Ajayi títí ẹ̀mí fi máa bọ́ lọ́rùn rẹ̀.

Ilé ẹjọ́ náà ní àwọn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, Ajayi jẹ̀bi ṣíṣekúpa Salome Adaidu tó sì tún kun òkú rẹ̀ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́.

Ẹ̀sùn ìpànìyàn ni wọ́n fi kan Ajayi èyí tó lòdì sí abala 221 ìwé òfin ìwà ọ̀daràn tí ẹ̀ka àríwá Nàìjíríà, tó sì jẹ́ pé ikú ni ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà.

Ṣáájú ni ìyá ọmọ náà sọ fún BBC News Pidgin pé Salome ló ń ṣe ọkọ fún òun láti ìgbà tí bàbá rẹ̀ ti kú àti pé òun fẹ́ kí wọ́n ṣe ìdájọ́ òdodo lórí ikú rẹ̀.

Lásìkò tí ìgbẹ́jọ́ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, Ajayi sọ fún ilé ẹjọ́ pé òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun.

Ọwọ́ Ọlọ́run ni àkóso gbogbo rẹ̀ wà - Ẹbí Salome sọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ ilé ẹjọ́

Àkọ́bí ẹbí Adaidu, Patience Unekwuojo Adaidu sọ fún BBC News Pidgin pé òun mọ̀ pé kò sí nǹkan tó le dá ẹ̀mí àbúrò òun padà ṣùgbọ́n ohun tó dá òun lójú ni pé Timileyin náà máa jáde láyé lọ́jọ́ kan.

Patience sọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ gbé dájọ́ ikú kalẹ̀ fún Timileyin Ajayi.

Ṣáájú kí ẹjọ́ náà tó dé ilé ẹjọ́ ni Patience sọ pé Ajayi kìí ṣe ọ̀rẹ́kùnrin àbúrò òun nítorí kò sí ẹni tó mọ̀ ọ́n nínú ẹbí àwọn.

Gẹ́gẹ́ bí nǹkan tí Patience sọ, ó ní Salome láwọn èròǹgbà tó dára fún ọjọ́ iwájú rẹ̀ àti pé ọ̀gá rẹ̀ ní Nicon Insurance ṣẹ̀ṣẹ̀ fi sẹ́nu ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan lórí ayélujára èyí tó máa ń ṣe ní gbogbo ọjọ́ Àbámẹ́ta kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé.

Ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún, tó ń ṣe àgùnbánirọ̀ ní iléeṣẹ́ Nicon Insurance tó wà ní Abuja ni Salome Adaidu kó tó jáde láyé.

Òun ni ọmọ karùn-ún nínú ọmọ mẹ́fà táwọn òbí rẹ̀ bí.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Kìíní ni orúkọ Timileyin Ajayi gba orí ayélujára lẹ́yìn táwọn ọlọ́paàá ṣafihàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí afurasi tó pa Salome Adaidu, àgùnbánirọ̀ tó ń sin ilẹ̀ baba rẹ̀ ní ìlú Abuja.

Ní ọjọ́ kejìlá, oṣù Kìíní ọdún yìí ni ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ Timileyin Ajayi lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé ìjọsìn kan ní Orozo pẹ̀lú orí Salome.

Fídíò kan tó gba orí ayélujára nígbà náà ṣàfihàn báwọn èèyàn ṣe pé lé Ajayi lórí tí wọ́n sì ń bi í láwọn ìbéèrè lórí orí èèyàn tó wà lọ́wọ́ rẹ̀.

Ó sọ nínú fídíò náà pé ọ̀rẹ́bìnrin òun ni Adaidu àti pé ó ti tó ọdún kan táwọn ti jọ ń ṣeré ìfẹ́ àmọ́ àwọn ẹbí Salome jiyàn ọ̀rọ̀ náà.

Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ní ìpínlẹ̀ Nasarawa fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Timileyin ti fojú bá ilé ẹjọ́ nígbà náà àti pé Adajọ́ Simon Aboki ló ń gbọ́ ẹjọ́ náà.

Timileyin kà bòròbòrò fáwọn ọlọ́pàá nígbà náà àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lórí ìtàkùn ayélujára gbàgbọ́ pé níṣe ló ń díbọ́n.

Ìròyìn ní lásìkò tí Salome ṣe àbẹ̀wò sí ilé Ajayi tó wà ní agbègbè Papalana ní New Karshi ní ìjóba ìbílẹ̀ Karu Nasarawa ló ṣekúpa á.

Àwọn ọlọ́pàá ṣàfihàn Ajayi pẹ̀lú ọ̀bẹ àti àdá tí wọ́n ló lò láti fi gbẹ̀mí lọ́rùn ọmọbìnrin náà.