Ṣé lóòótọ́ ni Baba Ijesha ti gba ìtúsílẹ̀ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n?

Àwòrán Baba Ijesha nínú aṣọ funfun

Oríṣun àwòrán, Baba Ijesha/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lẹ́nu bí ọjọ́ méjì sẹ́yìn ni ìròyìn kan ti ń lọ lórí ayélujára nípa gbajúmọ̀ òṣèré tíátà nnì, Olanrewaju Omiyinka James tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Baba Ijesha.

Ìròyìn tó ń lọ ni pé òṣèré náà ti kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà.

Oṣù Keje, ọdún 2022 ni Baba Ijesha ti wa ni ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ tó n gbọ́ ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ sọ pé ó jẹ̀bi híhu ìwà tí kò tọ́ sí ọmọdé.

Èyí ló mú kí BBC News Yorùbá kàn sí ọ̀kan lára agbẹjọ́rò tó súnmọ́ Baba Ijesha láti mọ̀ bóyá lóòótọ́ ni ìròyìn náà.

Agbẹjọ́rò náà tí kò fẹ́ ká dárúkọ òun ṣàlàyé pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ní ìròyìn ọ̀hún àti pé Baba Ijesha ṣì wà ní ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n tó wà.

Ó sọ pé ọjọ́ tí wọ́n gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní ka ọdún fún Baba Ijesha àmọ́ ohun tó dá òun lójú ni pé Baba Ijesha kò ní pẹ́ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.

Ó fi kun pé pẹ̀lú ònkà ọjọ́ àti oṣù tí wọ́n ń lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, kò ní pẹ́ mọ́ tí Baba Ijesha fi máa gba ìtúsílẹ̀ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.

"Tó bá fi máa tó ìparí oṣù Kẹjọ sí oṣù Kẹsàn-án, ó máa kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ìgbà tó máa lò lẹ́wọ̀n ti fẹ́ parí."

Agbẹjọ́rò náà sọ pé kò pẹ́ kò jìnà ni Baba Ijesha máa darapọ̀ mọ́ àwọn èèyàn rẹ̀, tí yóò sì máa bá ìgbésì ayé rẹ̀ lọ.

Kí ló gbé Baba Ijesha dé ọgbà ẹ̀wọ̀n?

Baba Ijesha lọna ile ẹjọ
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹ ó rántí pé ní ọdún 2021 ni òṣèré Damilola Adekoya tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Princess fẹ̀sùn kàn pé Baba Ijesha ṣe aṣemáṣe pẹ̀lú ọmọ tí òun gbà tọ́ nígbà tí ọmọ náà wà ní ọdún mẹ́rìnlá láàárín ọdún 2013 sí 2014.

Ó ní èyí ló mú òun gbé ẹ̀rọ ayàwòrán sínú iké òun láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nígbà tí Baba Ijesha fẹ́ ṣe àbẹ̀wò sílé òun lọ́dún 2021, táwọn ọlọ́pàá sì nawọ́ gán Baba Ijesha lórí ẹ̀sùn náà.

Láti ìgbà náà ni ilé ẹjọ́ Májísíréètì Eko ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ ẹjọ́ náà kí wọ́n tó gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lọ́jọ́ Kẹrìnlá, oṣù Keje, ọdún 2022.

Ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Keje, ọdún 2022 ni Adájọ́ Oluwatoyin Taiwo ti ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko ju Baba Ijesha sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún fún ẹ̀sùn bíbá ọmọdé lòpọ̀.

Ilé ẹjọ́ náà ní Baba Ijesha jẹ̀bi ẹ̀sùn híhu ìwà tí kò bójúmu sí ọmọdé, tó sì tún bá a lòpọ̀ láàárín ọdún 2013 sí 2014.

Wọ́n ní tako òfin ìwà ọ̀daràn tí ìpínlẹ̀ Eko tọdún 2015.

Bákan náà ni wọ́n ló jẹ̀bi gbígbé ọmọbìnrin náà sórí itan rẹ̀, tó sì ń fi nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ pa á lára lọ́jọ́ Kejìlélógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2021.

Ṣùgbọ́n ilé ẹjọ́ ní kò jẹ̀bi ẹ̀sùn fífi kọ́kọ́rọ́ ọkọ̀ rẹ̀ sójú ara ọmọ náà lọ́dún 2013 àti ìgbìyànjú láti bá a lòpọ̀ lọ́jọ́ Kejìlélógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2021.

Ìdájọ́ tí wọ́n fún Baba Ijesha yìí kò dùn mọ nínú èyí tó mu gba ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn lọ.

Ó bèèrè pé kí ilé ẹjọ́ fagilé ìgbẹ́jọ́ náà àti ẹ̀wọ̀n tí wọ́n dá fún òun.

Agbẹjọ́rò Baba Ijesha nígbà náà, Kayode Olabiran sọ pé agbẹjọ́rò ìjọba kò ní ẹ̀rí láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé oníbàárà òun bá ọmọ náà lòpọ̀ àti pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ dẹ pàkúté sílẹ̀ fún Baba Ijesha ni.

Ó sọ nígbà náà pé "òṣèré ni Baba Ijesha, ìwé ìtàn tí akẹgbẹ́ rẹ̀ Damilola Adekoya pè é sí láti kópa nínú rẹ̀ ló fi ṣeré tí wọ́n sọ di ẹ̀sùn mọ lọ́wọ́."

Àmọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn náà sọ pé Baba Ijesha jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fì kàn-án tó sì nílò láti ṣẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún rẹ̀ pé pérépéré bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n wọ́gilé ẹ̀sùn mẹ́ta nínú àwọn ẹ̀sùn márùn-ún tí wọ́n fi kàn-án.