DR Congo àti Rwanda tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn àláfíà ní Washington, ṣùgbọ́n àláfíà kò tíì jọba

Oríṣun àwòrán, Reuters
Lanaa, ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹfa ọdun 2025 ni orilẹ ede DR Congo ati Rwanda, tọwọ bọwe adehun ni Washinton, lorilẹede America, lati da ogun ọlọdun gbọọrọ aarin wọn duro.
Bo tilẹ jẹ pe adehun naa kede pe awọn ikọ ologun gbogbo yoo dawọ ija duro ni, awọn iṣẹlẹ kan ko ti i jẹ ki alaafia jọba.
Bakan naa lo jẹ pe eyi kọ ni igba akọkọ ti wọn yoo ki ọwọ bọ iwe adehun alaafia, ti nnkan ko si pada rọgbọ.
Ṣugbọn ninu ọrọ Aarẹ ilẹ America, Donald Trump, o ni adehun aṣeyọri ologo leyi.
" Lonii, rogbodiyan ati iparun dopin, gbogbo agbegbe yii bẹrẹ igbe-aye ireti ati anfaani tuntun."
Bẹẹ ni Trump ti Igbakeji rẹ; JD Vance, Akọwe ijọba; Marco Rubio ati awọn aṣoju DR Congo ati Rwanda wa pẹlu rẹ nile ijọba America, wi nibi ti wọn ti tọwọ bọwe adehun naa.
"Aṣeyọri alailẹgbẹ leyi"
Trump lo ṣafikun ọrọ bẹẹ ko too buwọ lu iwe adehun ti awọn aṣoju ilẹ Africa to wa nibẹ ti buwọ lu pẹlu.
Minisita ilẹ okeere fun Congo ati ti Rwanda naa kọwọ bọwe naa pẹlu.
Tẹ o ba gbagbe, o pẹ ti ẹkun Ila-Oorun Congo ati Rwanda ti n ja ogun.
Lọdun to kọja, ija naa tun lagbara si i.
Ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lo di alainile lori, ẹgbẹrun rẹpẹtẹ eeyan lo si padanu ẹmi wọn.
Ikọ ologun abẹle M23, gba ọpọ agbegbe ni DR Congo, titi kan Goma, to jẹ apa kan olu ilu, ati ilu Bukavu, pẹlu papakọ ofurufu meji.
Awijare awọn Congo ni pe Rwanda lo n ti awọn ọmọ ogun M23 naa lẹyin, ti wọn fi n ko ogun ja ilu.
Ṣugbọn Rwanda ni ọwọ oun ko si nibẹ. O ni awọn ọmọ ogun Rwanda wa nibẹ lati da aabo bo ilu awọn lọwọ ẹgbẹ ologun mi-in ti i ṣe FDLR ni.
Rwanda paapaa fẹsun kan Congo, pe oun lo n ti awọn FDLR lẹyin lati da rogbodiyan silẹ.
Bayii ni wọn n ti ọran mọra wọn ti ọpọ ẹmi si n bọ, ọpọ si di atipo nibudo awọn ti ogun le nilee wọn.
Nigba ti Congo ri i pe ko si ọna mi-in mọ, wọn kan si ijọba America lati ran wọn lọwọ.
Iroyin sọ pe Congo gba lati jọwọ awọn nnkan alumọni rẹ fun America lati gba iranwọ ti wọn yoo fi kojuu Rwanda.
Kí ló dé tí àlááfìa kò tí ì jọba

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty images
Pẹlu adehun alaafia ti wọn kọwe rẹ yii, awọn ti ogun le nile ni Congo ko ti i pada sile wọn.
Bẹẹ si ni awọn ikọ ologun abẹle gbogbo to n da ilu naa laamu ko ti i ko nnkan ija wọn silẹ.
Nigba to ku diẹ ki wọn tọwọ bọwe adehun alaafia lọjọ Ẹti, ikọ agbebọn ti wọn pe ni Codeco militia, kọlu ibugbe aabo awọn alainile lori lagbegbe Ituri, wọn si pa eeyan mẹwaa.
Papakọ ofurufu meji ṣi wa labẹ akoso awọn to gba a pẹlu.
Bakan naa ni adehun nipa nnkan alumọni DR Congo fun America ko ti i foju han kedere.
Nipa boya awọn ọmọ ogun Rwanda yoo kuro ni Congo, ohun ti America sọ ni pe kete ti awọn FDLR ba ti jawọ, awọn Rwanda naa yoo sinmi ija aabo ti wọn ni awọn n ja.
Bo tilẹ jẹ pe Rwanda ti sọ lọpọ igba pe awọn ọmọ ogun oun ko si ni Congo, ọpọ iroyin to ni ẹri lo n kede pe orilẹede naa lo n ro ogun ọlọtẹ, M23, lagbara lati kọlu Congo.












