Mi ò ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Segun Ogungbe, kò mọ ẹbí mi kankan - Wummi Ajiboye

Aworan Segun Ogungbe ati Wunmi Ajiboye

Oríṣun àwòrán, Segun Ogungbe/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja oṣere tiata, Omowummi Ajiboye, ti sọrọ sita lori ajọsepọ to wa laaarin oun ati akẹgbẹ rẹ, toun naa jẹ ilumọọka oṣere tiata, iyẹn Segun Ogungbe.

Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu Oyinmomo TV, Ajiboye ni oun ko fi igba kankan wa ninu igbeyawo pẹlu Segun Ogungbe.

O ni Segun Ogungbe ko mọ awọn mọlẹbi oun yatọ si ọrẹ aburo oun kan to mọ ni ilu Eko.

Agba oṣere ọhun, to bi ọmọ meji fun Segun Ogungbe wa rawọ ẹbẹ si awọn ololufẹ rẹ pe ki wọn ṣe pẹlẹ pẹlu rẹ nitori ko ki n ṣe eeyan buruku.

Wunmi sọ ninu ifọrọwerọ naa to ṣe wí pe nigba ti oun wa ninu igbesi aye Segun Ogungbe, nnkan dara fun un, ti nnkan si tun dara fun nigba ti oun kuro ni ile rẹ.

"Ẹ jẹ ki sọrọ yii, ko tan, emi ati Segun Ogungbe, a ko ṣe igbeyawo tabi ni erongba pe a o fẹ ara wa.

Ko mọ mọlẹbi mi, yatọ si ọrẹ aburo mi kan to n gbe ni Eko. Segun fun ara rẹ le fidi eyii mulẹ.

"Si awọn ololufẹ mi, mo bẹ yin pe kẹ ẹ ṣe pẹlẹ pẹlu mi.

Mi o ki n ṣe eeyan buruku, n ko si ba aye Segun Ogungbe jẹ.

"Nigba ti mo wa ninu aye rẹ, nnkan lọ daada fun, nigba ti mo kuro, ko yipada, nnkan si n lọ daada fun un.

"Ẹ jọwọ, ẹ jẹ ki n gbadun aye mi. Mo gba adura pe ile yin o ni bajẹ," Wunmi lo sọ bẹẹ.

Ọdun 2023 ni ipinya waye laaarin Segun Ogungbe ati Wunmi Ajiboye lẹyin ti wọn bi ọmọ meji fun ara wọn tán.

Ninu awọn oṣere tiata Yoruba, odu ni Segun Ogungbe kii ṣe aimọ fun oloko.

O ti to ọjọ mẹta ti oṣere to ṣapejuwe ara rẹ gẹgẹ bi olukọtan,oludari ati oṣere bakan naa yi ti n da bira lagbo tiata Naijiria.

Pupọ awọn ololufẹ rẹ ni ko mọ pe oṣere yi jẹ ọmọ Abeokuta lapa kan, o si tun jẹ ọmọ ipinlẹ Osun ati Eko lapa miran.