Àwọn ọ̀rẹ́ mi ní kí n fi ilé ìjọba sílẹ̀ torí wọ́n lè pamí nígbà tí Yar'Adua ń ṣàìsàn, ìdí tí mo fi takú síbẹ̀ rèé - Jonathan

Aworan Goodluck Jonathan

Oríṣun àwòrán, Facebook/Goodluck Jonathan

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Fun igba akọkọ lati igba to ti kuro lori aleefa gẹgẹ bii aarẹ orilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan, ti tu kẹkẹ ọrọ silẹ lori nnkan to sẹlẹ lasiko ti Aarẹ Umaru Musa Yar'adua fi n ṣe aisan.

Aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Jonathan sọ pe oun pinnu lasiko naa lati ma fi ipo oun silẹ pẹlu gbogbo wahala to sẹlẹ nigba naa nitori nnkan ti ofin sọ.

Jonathan ni ipinnu naa debi wi pe oun ṣetan lati duro lori ẹsẹ oun koda ti ọrọ naa ba maa mu ẹmi oun lọ.

Jonathan sọ ninu ifọrọwanilẹniwo kan to ṣe pẹlu ẹgbẹ Rainbow Book Club wi pe Yar'Adua buwọlu lẹta ti yoo foun lagbara lati maa ṣe adele aarẹ.

Amọ, o ni amugbalẹgbẹ Yar'Adua kan lo gbẹsẹ le lẹta ọhun ti ko fi de ile aṣofin agba.

Iroyin kan sọ nigba naa wi pe Yar'Adua rinrin ajo lọ soke okun fun itọju ara rẹ lọdun 2009 lai sọ fun ile aṣofin lati ro Jonathan to jẹ igbakeji aarẹ lagbara pe ki o maa ṣe adele aarẹ gẹgẹ ofin ṣe la a kalẹ.

Eyi fa awuyewuye ni Naijiria lasiko naa, Jonathan ni lara awọn ilakọja to lagbara julọ ti orilẹede Naijiria koju ni akoko naa jẹ.

O tẹmi lọrun ki wọn pami sile ijọba ju ile itura lọ - Jonathan

Aarẹ Naijiria tẹlẹ sọ pe ''ibẹru-bojo gbalẹ kaakiri orilẹede Naijiria, iyapa loriṣiiriṣii bii iyapa laarin awọn eeyan ariwa ati guusu Naijiria.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bakan naa ni iyapa laarin awọn ọmọlẹyin Kristi atawọn musulumi naa wa nibẹ.''

O ni adehun kan ti ko ni akọsilẹ wa nilẹ pe ẹni to ba jẹ aarẹ lati apa ariwa yoo lo ọdun mẹjọ lori ipo aarẹ lẹyin ti Oloye Olusegun Obasanjo to lo ọdun mẹjọ gẹgẹ bi aarẹ Naijiria.

Jonathan ni loootọ loun le ṣe awọn nnkankan gẹgẹ bi igbakeji aarẹ, ṣugbọn oun ko ni le dari gbogbo ileeṣẹ ọmogun Naijiria lai di adele aarẹ.

O ni gbogbo rudurudu to n ṣẹlẹ lo mu ki ile aṣofin pada foun lagbara lati maa ṣe adele aarẹ.

Aarẹ Naijiria tẹlẹ ri sọ pe awọn ọrẹ oun kan gboun ni imọra lati kuro lori oye ki wọn ma ba pa oun.

''Mo ranti ọjọ kan ti mo si wa nipo igbakeji aarẹ tawọn ọrẹ mi kan sọ fun mi pe ki n ma sun nile ijọba mọ.

Mo ni rara wi pe ileeṣẹ ijọba ni mo maa sun, ki ẹni to ba fẹ pami wa pami sibẹ.

O tẹmi lọrun ki wọn pami sile ijọba tori awọn ọmọ Naijiria yoo mọ pe nibẹ lawọn agbenipa ti ṣeku pami.

Wọn mọ pe mi o ṣẹ si ofin lọna kankan, ṣugbọn ti mo ba lọ sun sile itura kan gẹgẹ bi imọran tawọn ọrẹ mi fun mi ni wọn maa sọ pe awọn obinrin India kan lo wa fun mi ni eso jẹ nibẹ lati pami,'' Jonathan ṣalaye

Ile aṣofin agba pada ro Jonathan lagbara ti o fi di adele aarẹ loṣu Keji ọdun 2010, o si pada di aarẹ Naijiria loṣu Karun un ọdun kan naa lẹyin ti Yar'Adua jade laye.