Wo àwọn àbá rere tí Ààré Tinubu dá ní Saint Lucia fún Naijiria

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency
Aarẹ Bola Tinubu ti pe fun awọn anfaani kan fun orilẹede Naijiria lati ilẹ okeere, paapaa orilẹede Saint Lucia, to wa lọwọlọwọ.
Ọkan lara awọn nkan ti Aarẹ Tinubu tẹnumọ ni Saint Lucia, ni pe ki awọn eeyan to ba ni iwe irinna ajọ Organisation of Eastern Caribbean States (OECS), maa wọ awọn ilu naa lai gba fisa.
Aarẹ sọrọ yii lasiko to n ṣepade pataki kan pẹlu awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin Saint Lucia, eyi to waye ni William Jefferson Clinton Ballroom, Sandals Grande, Gros Islet.
Tinubu ṣalaye bo ṣe je pataki to fun awọn orilẹede lati maa ba ara wọn ṣe.
O ni ki awọn ajọ OECS gbe aba oun yii yẹwo, ki awọn ọmọ Naijiria to ni iwe irinna ibẹ si maa wọle nirọrun lai nilo fisa.
" Tọwọtọwọ ni mo fi rọ wa pe ka jọ maa fun ara wa lanfaani lati wọle-jade, mo rọ wa ki awọn alabojuto lati awọn orilẹede mi-in naa le jẹ anfaani yii, ki ajọṣepọ wa le dan mọọnran si i."
Tinubu lo sọ bẹẹ.
Bakan naa ni Aarẹ Tinubu tun pe fun idasilẹ ajọ apapọ kan ti wọn yoo le maa kan si, ti yoo wa fun ki ẹnu kò labala oṣelu, ti yoo si mu ifọwọsowọpọ wa laarin Naijiria ati awọn ile Carribean ti i ṣe OECS.
"Mo n fi da yin loju pe Naijiria ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu OECS, ka jọ ṣowo pọ, ka jọ ṣe lẹka idokowo, eto ẹkọ, ilera, aṣa, gbigba ayipada ti oju ọjọ ba mu wa ati bẹẹ bẹẹ lọ."
Bẹẹ ni Aarẹ Bola Tinubu wi.
'A máa fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ OECS ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ kíkún'
Bakan naa ni Aarẹ Tinubu sọ pe oun yoo fun awọn akẹkọọ OECS ni ẹkọ ọfẹ kíkún.
O ni eyi wa fun lati mu so okun aṣa Naijiria le pẹlu awọn Carribean.
Tinubu tun pe fun awọn akanṣe ẹkọ laaarin awọn fasiti Naijiria ati OECS.
O ni yoo dara bi ẹkọ nipa Technical Aid Corps (TAC) to n waye ni Naijiria ba le de awọn orilẹede OECS naa.
"Iru ajọṣepọ bẹẹ yoo ro ẹka imọ ẹrọ wa lagbara, yoo si jẹ ki ajọṣe ọlọdun pipẹ wa laaarin wa nipa eto ẹkọ."
Bẹẹ ni Aarẹ Tinubu ṣalaye.
Lori ọrọ aje, Tinubu rọ awọn ajọ OECS lati gba ti Naijiria ro.
O ni ki wọn wo Naijiria gẹgẹ bi ilu to wa loke tente nibi ọja tita nilẹ Africa.
" A le jọ ṣe pọ lati jere lẹka idokowo, ipese iṣẹ ati awọn eto mi-in ti yoo jẹ anfaani fun awọn eeyan wa."
Bayii ni Aarẹ kadi awọn ipe naa nilẹ.
Ki awọn nnkan wọnyi wa si imuṣẹ ni afojusun awọn ọmọ Naijiria ṣaa.
Kí ni ìrìnàjò Tinubu sí Saint Lucia, 'orílẹ̀èdè tí oríirun rẹ̀ jẹ́ Naijiria', dá lé lóri?

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency
Ẹnu to n kun irinajo Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu, si orilẹede Saint Lucia lati ọjọ Abamẹta to kọja to ti kuro ni Naijira, ko ti i dakẹ rara.
Ọpọ eeyan lo n beere pe ki ni aarẹ n wa kiri lasiko yii ti nnkan ko fararọ lorilẹede Naijiria.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe nibo gan-an lo n jẹ Saint Lucia labẹ ọrun, ni awọn mii n beere pe ṣe dandan ni ki Tinubu maa tẹkọ leti kiri ni gbogbo igba ni.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Ẹti to kọja ni agbẹnusọ Tinubu lori eto iroyin, Bayo Onanuga, fi atẹjade to kede irinajo aarẹ naa lede.
Ninu atẹjade naa ni wọn ti sọ pe Tinubu yoo lọ si Saint Lucia, ọkan lara awọn orilẹede agbegbe Carribean to jẹ ẹka kan lara ilẹ Gẹẹsi, ṣugbọn ti wọn ni afijọ ilẹ Africa.
Atẹjade naa kede pe Aarẹ Tinubu n lọ si ilu kekere naa lati tubọ so okun ọrẹ to wa laaarin orilẹede naa pẹlu Naijiria duro daadaa.
O ni bi aarẹ ba kuro ni Saint Lucia, yoo fẹsẹ kan ya ni Brazil lati kopa ninu ipade BRICS, ẹlẹẹkẹtadinlogun iru ẹ ti yoo waye ni Rio de Janeiro.
Ṣugbọn alaye yii ko jọ pe o ta leti awọn eeyan ti ko faramọ bi Aarẹ Tinubu ṣe tun tẹkọ leti yii.
Kaluku lo n sọ pe irinajo Aarẹ Tinubu ti n pọju, pẹlu bi ijinigbe, ipaniyan, ebi, ọwọngogo ọja ṣe n ba awọn ọmọ Naijiria finra.
A ko ṣai ri awọn to sọ pe ara aarẹ ko ya lo mu ko rin irinajo yii, wọn ni Tinubu fẹẹ dọgbọn lọọ gba itọju ni.
Àlàyé láti ọ́fíìsì Ààrẹ

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency
Lara awọn eeyan to bu ẹnu atẹ lu irinajo aarẹ si Saint Lucia ni Peter Obi, oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹẹ Labour ni 2023.
Obi sọ pe asiko yii kọ lo yẹ ki Tinubu tirafu bii ẹni to n lọọ lo isinmi ọlude.
O ni o ya oun lẹnu gidi gbọ pe aarẹ le fi Naijiria silẹ lasiko yii, ko lọọ sinmi.
Ṣugbọn lati tan imọlẹ si ohun ti Tinubu lọọ ṣe niluu oke okun naa gan-an, agbẹnusọ rẹ, Bayo Onanuga, ṣalaye ninu atẹjade to pe ni 'Idi ti Aarẹ Tinubu ṣe lọ si Saint Lucia, pe:
" Nitori ọrọ awọn ọmọ Naijiria kan to kun fun arekereke ati irọ ti wọn n pa kiri nipa irinajo Aarẹ Tinubu si Saint Lucia, o yẹ ka ṣalaye idi irinajo naa gan-an.
"Lakọkọ, irinajo aarẹ si Saint Lucia dun mọ ijọba ibẹ ninu, o si ṣina fun ajọṣẹpọ to le mu èrè wa fun orilẹede mejeeji ni."
Ni Sẹnturi kọkandinlogun (19th century,) awọn eeyan Naijiria kan de si Saint Lucia, wọn si fi ẹsin ati aṣa ilẹ wa lọlẹ nibẹ titi doni."
O fi kun un pe latigba naa ni awọn eeyan ibẹ ti n foju sọna lati ba Naijiria ṣe, ki wọn si so okun ajọṣepọ aarin wọn le si i.
Agbẹnusọ aarẹ tẹsiwaju pe inu awọn ọmọ Saint Lucia dun pupọ lati gba Tinubu lalejo.
O ni ilu naa gẹgẹ bi awọn orilẹede Carribean to ku, ni orirun wọn jẹ ti Africa, paapaa julọ, Naijiria.
Irinajo yii gẹgẹ bo ṣe wi, wa fun ọna ti Naijiria yoo fi ba Saint Lucia da ọrẹ ti yoo mu anfaani wa.
O ni o tun wa fun ijọba tiwa-n-tiwa, pẹlu idagbasoke lati oke okun wa si ilẹẹ tiwa.
Níbo ni wọ́n ń pè ní Saint Lucia?
Orilẹede kekere kan ni Saint Lucia n ṣe.
Ni oṣu kẹta ọdun 2023, akọsilẹ sọ pe onka eeyan to wa nibẹ jẹ 185,886.
Ilu naa wa lara awọn ti ilẹ Gẹẹsi n dari rẹ ni Windward Islands fun ọpọlọpọ ọdun.
Ọjọ kejilelogun, oṣu Keji ọdun 1979 ni Saint Lucia gba ominira.
Nipa nnkan alumọni ati ẹwa, Saint Lucia ko ṣee fọwọrọ sẹyin, aabo to le kenka wa nibẹ pẹlu, bẹẹ ni wọn ni oju ọjọ to jiire.
Saint Lucia ki I ṣe ilu ẹlẹsin kan. Ida mẹfa ninu awọn eeyan ibẹ ko ṣe ẹsin kankan, ida aadọjọ (150) si irinwo (400) lo jẹ ẹlẹsin Islam, nigba ti awọn eeyan ti iye wọn to aadọta le ni igba (250) jẹ ọmọ ijọ ṣọọṣi Jesus Christ of Latter-day Saints.
Ida mẹsan-an la si gbọ pe wọn jẹ ọmọ ijọ Aguda (Catholic).
Ede Gẹẹsi ni wọn n sọ nibẹ bii ede ajumọlo, bo tilẹ jẹ pe awọn kan a maa sọ ede Faranse.
Ni ti ọrọ aje, Saint Lucia ki i ṣe ilu ọlọrọ nla, bii akọsilẹ ṣe wi, bẹẹ ni wọn ko tọrọ jẹ pẹlu.
O rẹwa pẹlu awọn oke ati omi to n ti oke jabọ, bakan naa lo si ni awọn ibudo igbafẹ to wọ oju gan-an. O ni ilẹ to daa fun nnkan ọgbin pẹlu.
Owo dola ti i ṣe 'East Carribean dollar' ni wọn n na.
Ilu to ṣi n dagba ni Saint Lucia, gẹgẹ bi ajọ ayanilowo agbaye, IMF, ṣe sọ.
Awọn otoṣi wa nibẹ gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe wi, bo tilẹ jẹ pe iṣẹ ati oṣi ibẹ dinku bi wọn ṣe sọ.
Iye igba ti Aarẹ Tinubu ti rin irinajo kuro ni Naijiria ni 2025
Ninu oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 yii, Peter Obi, kede pe ninu ọjọ 580 ti aarẹ Tinubu ti lo nipo aarẹ nigba naa, ọgọsan-an ọjọ (180), lo fi rin irinajo, ti ko si duro ni ọfiisi ti ilu yan an si.
Bo tilẹ jẹ pe irinajo aarẹ ni 2024 ni akọsilẹ to pọ ju ti asiko yii lọ, wọnyi ni awọn igba to ti rin irinajo kuro nilẹ yii ni 2025.
Lọjọ Keje, oṣu Kin-in-ni, Aarẹ gunlẹ si Ghana.
O ṣe eyi lati ba wọn kopa ninu ayẹyẹ iburawọle aarẹ tuntun ilẹ Ghana;John Mahama.
Lọjọ kejila oṣu kin-in-ni 2025, Aarẹ Tinubu balẹ si United Arab Emirate, nibi to ba kopa ninu 'Abu Dhabi Sustainability Week.'
O balẹ si Tanzania loṣu kan naa pẹlu, lọjọ kẹrindinlogun, lati kopa ninu ipade nipa nnkan amuṣagbara.
France: Ọjọ karun-un oṣu Keji ọdun 2025 ni Aarẹ Tinubu gbera lọ si France, nibi to ti pade Aarẹ ibẹ, Emmanuel Macron.
Lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji, Tinubu balẹ si Ethiopia, fun ipade awọn olori ilẹAfrica (AU).
Lọjọ keji, oṣu Kẹrin, aarẹ tẹkọ leti lọ si France fun ohun ti wọn pe ni irinajo iṣẹ (work visit).
Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa, Aarẹ gunlẹ si Saint Lucia, fun isọdọtun ajọṣepọ orilẹede Carribean naa pẹlu Naijiria bi wọn ṣe sọ.














