Ilé ẹjọ̀ sọ pásítọ̀ sí ẹ̀wọ̀n ọdún 53 fún fífipá bá ọọmọ rẹ̀ lò pọ̀

Oríṣun àwòrán, LAGOS GOVT/ Facebook
Adajọ Olubunmi Abike Fadipe ti ile ẹjọ to n ri si ẹsun ifipabanilopọ ni Ikeja ti ran olusọ aguntan kan, ẹni ọdun marunlelogoji lọ si ẹwọn ọdun mẹtalelọgọta fun ẹsun pe o fipa ba ọmọ rẹ, ọmọ ọdun mẹrinla lo pọ.
Ile ẹjọ kede pe Pasitọ Ndukwe Ogbu jẹbi ẹsun mẹta ti ijọba ipinlẹ Eko fi kan.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ lọjọ Aje, adajọ ni olujẹjọ naa ko ri nnkan to ṣe gẹgẹ bii ohun to buru, pe o fipa ba ọmọ rẹ lopọ, ti ko si tun tọrọ aforijin.
Olujẹjọ naa, lati ẹnu agbẹjọro rẹ, ni ki adajọ fi oju anu wo oun nitori oun ni awọn ọmọ mii ti oun n tọju ni ile.
Ọmọ ọdun mẹrinla naa ba ile ẹjọ sọrọ lori ohun to lakọja, ti dokita to ṣe ayẹwo rẹ naa si jẹri ni ile ẹjọ pẹlu.
'Baba mi wọle sinu yara mi ni ihoho, to si fipa ba mi lopọ'
Lasiko igbẹjọ, ọmọ ọdun mẹrinla sọ fun ile ẹjọ pe Baba rẹ ja wọle sinu yara rẹ ni ihoho, to si bọ asọ lara rẹ ko to di pe o fipa ba lopọ.
Ọdọmọbinrin naa ni lati igba ti oun ti wa ni ọmọ ọdun mẹrinla ni baba oun ti n fipa bao un lopọ.
O fikun pe baba oun ma n dunkoko mọ oun pe oun ko gbọdọ sọ ẹnikẹni.
Ṣugbọn, ọdọmọbinrin yii sọ fun olukọ, ẹni to ọrọ naa to ijọba leti.
O ni ọpọ igba ni baba oun ti fipa oun lopọ.
Nigba to n sọrọ, Olujẹjọ, Ọgbẹni Ogbu, sọ un ile ẹjọ pe oun ati ọmọ oun n gbe ni ile oni yara meji, ti oun ko si fi bẹ gbe ile.
O fẹsun kan ọmọ naa pe o ni aarun ọpọ ati pe o ma n gbagbe nnkan.
Ogbu fidi rẹ mulẹ pe oun padanu iyawo oun nigba ti awọn ọmọ rẹ kere, ti awọn yooku si wa pẹlu iya to bi iya wọn ni abule.















