Ṣé ìjọba Amẹrika yóò tilẹ̀kùn rẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ Naijiria lẹ́yìn gbèdéke ọgọ́ta ọjọ́ tó fun?

Aarẹ Bola Tinubu ati Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Bola Tinubu ati Donald Trump
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Laipẹ yii ni ijọba Amẹrika lede kede ofin kan to ṣeeṣe ko ti ilẹkun orilẹede naa mọ awọn ọmọ Naijiria, Ghana atawọn orilẹede mẹrinlelọgbọn mii.

Pẹlu ofin naa, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan orilẹede wọnyii ni fisa lọwọ wọn, wọn ko ni le wọ Amẹrika mọ.

Igbesẹ naa ko sẹyin akitiyan lati daabo bo awọn ọmọ ilẹ Amẹrika lọwọ awọn ọta lati ilẹ okeere.

Awọn orilẹede wo ni ọrọ yii kan?

Awọn orilẹede ti ọrọ naa kan ni Naijiria, Ghana, Niger, Senegal, Republic of Benin, Burkina Faso, Cameroon, Ivory Coast, Egypt, Gabon, Tanzania, Gambia, Ethiopia, Malawi, Liberia, South Sudan, ati Angola.

Awọn to ku ni Antigua and Barbuda, Bhutan, Cambodia, Cape Verde, the Democratic Republic of Congo, Djibouti, Dominica, Kyrgyzstan, Mauritania, St. Kitts and Nevis, St. Lucia, São Tomé and Príncipe, Syria, Tonga, Tuvalu, Uganda, Vanuatu, Zambia ati Zimbabwe.

Ki ni idi ti Amẹrika fi fẹ fofin de awọn orilẹede wọnyii ati pe gbedeke wo ni Amẹrika fun wọn?

Ọgọta ọjọ pere ni gbedeke ti ijọba Amẹrika fun awọn orilẹede ti ọrọ naa kan ki wọn ṣe awọn nnkan to yẹ.

Gẹge bi ohun ti wọn sọ, awọn eeyan awọn orilẹede naa ti tẹ awọn ofin kan loju mọlẹ l'Amẹrika, bii kikọ lati pada silẹ wọn lẹyin abẹwo si Amẹrika, fifunra pe awọn kan lara wọn ni ibaṣepọ pẹlu awọn agbesunmọmi, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lẹyin gbedeke naa ni Amẹrika fun awọn ijọba awọn orilẹede ọhun ni ọgọta ọjọ pere lati jẹ ki Amẹrika mọ awọn igbesẹ ti wọn yoo gbe lati gbogun ti iṣoro eto abo ti awọn eeyan wọn n gbe ti Amẹrika atawọn ọmọ ilẹ wọn to n gbe l'Amẹrika lọna ti ko ba ofin mu.

Ajọ to n ri si iwọle-wọde l'Amẹrika, USCIS sọ pe gbedeke ọgọta ọjọ naa wa fun awọn oṣiṣẹ lati ilẹ okeere to ni fisa H-1B; E-1; E-2; E-3; L-1; H-1B1; 0-1 ati TN lati le maa gbe nilẹ naa titi ti wọn yoo fi paarọ fisa wọn si omiran.

Ki ni ijọba Naijiria n ṣe lori ọrọ yii bayii?

Asisa Naijiria ati Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Minisita ọrọ ilẹ okeere ni Naijiria, to tun jẹ alaga ẹka Mediation and Security Council ninu ajọ ECOWAS, Yusuf Tuggar ti kọminu lori ipa ti ọrọ yii ko ninu aye awọn ọmọ ilẹ Afrika atawọn ọmọ Naijiria lapapọ.

O ni awọn ti bẹrẹ iṣẹ lati ri pe awọn ṣe ọfintoto awọn araalu ti ọrọ naa kan ki wọn le yanju rẹ lai si wahala kankan.

Ọgbẹnin Alkassim Abdul Kadir, to jẹ oluranlọwọ pataki fun minisita naa sọ fun BBC pe Naijiria ti n ṣe awọn ayẹwo to yẹ ko ṣe gẹgẹ bii atẹjisẹ ilẹ Amẹrika si Naijiria.

Iha wo ni ajọ ECOWAS kọ si igbesẹ Amẹrika yii?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Tuggar, to sọrọ lorukọ ECOWAS nibi ipade wọn kan to waye niluu Abuja sọ pe ti Trump ba le fofin de awọn orilẹede to jẹ ọmọ ẹgbẹ ECOWAS, yoo ṣoro lati dokoowo pẹlu Amẹrika, eyii yoo si di idagbasoke awọn orilẹede kan ni Afrika lọwọ.

O ni "Yoo jẹ ohun to buru gbaa ti Trump ba le fofin de wa nitori a jẹ agbegbe kan ti anfani wa fun lati ṣowo."

Tuggar juwe igbesẹ ijọba Amẹrika ọhun gẹgẹ bii aṣiṣe ibaṣepọ laarin awọn orilẹede.

O sọ pe "A ni awọn ohun alumọni to ṣọwọn lagbaye bii Samarium ti a le ri nipinlẹ mi ni Bauchi."

Lẹyin naa lo ke si ijọba Amẹrika ko tun ero rẹ pa nipa igbesẹ rẹ ọhun nitori awọn ọmọ Afrika l'anfani lati lọ ibomii lati lọ ṣowo.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, anfani wa fun ijọba Amẹrika lati ba awọn orilẹede Afrika dowo pọ, amọ awọn orilẹede mii lagbaye naa ṣetan lati ba awọn eeyan Afrika dowo pọ.

Wayi o, awọn eeyan kaakiri agbaye lo ti n duro ki gbedeke ọgọta ọjọ naa pari lati mọ awọn orilẹede ti Trump yoo fofin de patapata ati awọn ti yoo fofin de fun igba diẹ.