Kí ló fà á ti ọ̀pọ̀ àwọn alága ẹgbẹ́ òṣèlu ní Naijiria kìí fi í fara ire kúrò nípò?

Aworan awọn alaga APC ati PDP tẹlẹ ti wọn ti fipo silẹ

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọjọ Ẹti to kọja yii ni alaga apapọ fun ẹgbẹ oṣelu APC tẹlẹ, Abdullahi Umar, fi ipo naa silẹ lojiji, eyi to ti n fa ariyanjiyan latigba naa.

Gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ naa fipo alaga silẹ lẹyin to ti fẹrẹ lo to ọdun meji, iyẹn lẹyin ti Sẹnetọ Abdullahi Adamu, alaga fidihẹ-ẹ to wa nipo naa kọwe fipo kan naa silẹ.

Awọn o ṣoju mi koro kan lati ile ijọba Naijiria, sọ fun BBC pe lati ọfiisi aarẹ ni aṣẹ ti wa, pe ki Ganduje kọwe fipo naa silẹ.

Wọn ni ki i ṣe pe o wu u lati lọ lojiji rara.

" Lati Ọjọbọ ni aṣẹ ti wa pe ki Ganduje kọwe fipo silẹ, nigba to si di aarọ ọjọ Ẹti, o fiwe naa ranṣẹ sibi to yẹ pe oun ti kuro nipo alaga." Bẹẹ ni ẹnikan lara awọn o ṣoju mi koro naa wi.

Pẹlu ifiposilẹ ojiji Ganduje yii, ohun ti araalu n wi ni pe o ti di aṣa awọn oloṣelu lati maa fipo alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu siIẹ lairo tẹlẹ.

Awọn kan gba iwe lọọ rọ ọ kun nile ninu awọn alaga yii, wọn le awọn mi-in lọ patapata, wọn si paṣẹ tulaasi fun awọn alaga mi-in lati kọwe fipo silẹ.

Iwa yii ni awọn awoye oṣelu sọ pe ko ni itumọ meji, ju pe awọn kan ti wọn fẹran imọtaraẹni nikan ni wọn n paṣẹ onikumọ fun awọn alaga ẹgbẹ apapọ ẹgbẹ oṣelu lorilẹede yii.

Ọmọwe Yakubu Haruna Ja'e, ọga agba lẹka ẹkọ nipa oṣelu ni Yunifasiti ipinlẹ Kaduna, sọ fun BBC pe eyi to ṣẹlẹ yii naa ko ṣẹyin magomago ti awọn oloṣelu maa n ṣe.

O ni wọn n ṣe bẹẹ lati roko si ọdọ ara wọn nikan ni.

" Awọn olori ẹgbẹ oṣelu kan naa wa ti wọn maa n ṣe oju meji bii ọbẹ, awọn kan si wa to jẹ bi awọn oloṣelu ẹgbẹ wọn ba ti ri i pe wọn ko ṣe ohun tawọn n fẹ, wọn maa le wọn danu ni. "

Ọmọwe Yakubu Haruna Ja'e, lo ṣalaye bẹẹ.

Awọn to ti dipo alaga mu ri ni APC

Abdullahi Adamu: Ọdun kan ati oṣu diẹ ni ọkunrin naa lo nipo alaga apapọ APC to fi kuro.

Gomina ipinlẹ Nasarawa tẹlẹ naa kọwe fipo silẹ lẹyin ti ede aiyede kan waye laaarin rẹ ati Aarẹ Tinubu.

Mai Mala Buni: Loṣu Kẹfa ọdun 2020, ni wọn yan an bii alaga Fidihẹ-ẹ fun ẹgbẹ APC.

Iyansipo Mai Mala waye lẹyin rogbodiyan to koju APC pẹlu Adams Oshiomhole to jẹ alaga nigba naa.

Aroye ọlọkan-o-jọkan lo waye lori eyi, wọn si pada de kootu pẹlu.

Adams Oshiomole: Oṣu Kẹfa ọdun 2018 ni wọn yan Senato Adams Oshiomole bii alaga ẹgbẹ APC lapapọ, ṣugbọn o koju iṣoro pupọ, o si pada fipo naa silẹ lẹyin ọdun meji.

John Odigie Oyegun: Wọn yan an ni 2014 lẹyin alaga Fidihẹ-ẹ akọkọ.

Awọn to ti dipo naa mu ri ninu ẹgbẹ PDP

Iyorchia Ayu,alaga apapọ PDP nigba kan

Oríṣun àwòrán, Others

Ohun to n ṣẹlẹ ninu APC ko yọ PDP to jẹ ẹgbẹ alatako wọn naa silẹ, to ba di ti awọn olori ẹgbẹ to n fipo silẹ.

Eyi ni awọn ti wọn ti dipo alaga apapọ mu ri fun PDP naa.

Iyorchia Ayu: Wọn ni ko lọọ rọ ọ kun nile nigba ti rogbodiyan bẹ silẹ ninu ẹgbẹ.

Oṣu Kẹwaa ọdun 2021 ni gomina ipinlẹ Benue tẹlẹ naa di alaga PDP. Ṣugbọn loṣu Kẹta 2023, wọn da Iyorchia Ayu duro, wọn si yan Iliya Damagum to wa nibẹ lọwọ yii.

Uche Secondus: Ni ọjọ kẹwaa, oṣu Kejila ọdun 2017 ni wọn yan an bii olori ẹgbẹ , ṣugbọn oun naa ko oju iṣoro to gbe e de kootu.

O pada fipo silẹ pe oun o ṣe mọ.

Awọn yooku ni

Ahmed Makarfi

Ali Modu Sheriff

Bamanga Tukur

Adamu Mu'azu

Ipa wo ni iyọnipo tabi ikọwe fipo silẹ yii n ni?

Gẹgẹ bi alaye Ọmọwe Yakubu Haruna Ja'e, iyọnipo tabi ikọwefipo silẹ maa n mu ifasẹyin ba ijọba awaarawa ni Naijiria ni.

"Nitori rogbodiyan abẹnu yoo maa koju wọn lọpọ igba, awọn kan yoo maa le bi wọn a ṣe ri nnkan pọnla , ki wọn si le maa fi awọn yooku ṣe ero ẹyin."

Bakan naa lo ni ẹgbẹ to ba n koju iṣoro yii ko ni i ri aaye yanju ohun to yẹ ninu ẹgbẹ.