Àwọn ọ̀dọ́ ìlú Lafiagi ṣe ìfẹ̀hónúhàn, jo Iléeṣẹ́ NDLEA, ba ààfin ọba jẹ́ nítorí ìjínigbé tó di lemọ́

Aworan ọkọ ti awọn ọdọ dana sun niluu Lafiagi nipnlẹ Kwara

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Rogbodiyan bẹ silẹ ni ilu Lafiagi tojẹ olu ilu fun ìjọba ibilẹ Lafiagi ni ipinlẹ Kwara lọjọ Aje, lẹyin ti awọn ọdọ ilu naa ya wọ igboro ti wọn si n ba awọn nnkan jẹ.

Awọn ọdọ yii dana sun Ileesẹ ajọ ton gbogun ti asilo oogun (NDLEA), wọn ba, afin Emir ilu ọhun jẹ nigba ti wọn fọ awọn gilaasi ferese, ja iganna bẹẹ si ni wọn jo awọn moto awọn araalu tọwọ wọn ba.

Kí ni ìdí tí àwọn ọ̀dọ́ Lafiagi fi ń ba nǹkan jẹ́?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Gẹgẹ bii fidio to gbode lori ayelujara, ohun ti awọn ọdọ sọ pe o fa iwa ti wọn wu yii ni pe ijọba o se nkankan lori eto abo agbegbe naa to mẹhẹ.

Wọn ni ijinigbe, ipaniyan ati bẹẹ bẹẹ lọ ti pọ ju ni ilu naa ati agbegbe ati wi pe ijọba o gbe igbesẹ lati dẹkun awọn isẹlẹ laabi yii.

Se ni wọn n kọrin ogun, wọn si gbe patako (placards) ti wọn kọ orisirisi ọrọ to n pe fun igbesẹ pajawiri lati dẹkun itajẹsilẹ, ijinigbe ati awọn iwa ọdaran mii to n waye.

Ohun tí aráàlú sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

BBC Yoruba kan si ọkan lara awọn olugbe ilu naa, Họnọrebu Ahmed Alhassan to ti figba kan jẹ kọmisanna fun ijọba Kwara.

Alhassan sọ pe ijinigbe ati ipaniyan ti di lemọ-lemọ ninu ilu awọn ati agbegbe rẹ sugbọn iyi to tan awọn ọdọ ni suuru gan ni isẹlẹ to sẹlẹ ni bi ọjọ mẹta sẹyin ati mọju mọ arọ ọjọ Aje yii.

O sọ pe, "Ọkunrin onisowo kẹmika kan ti wọn n pe ni Alhaji Chemical lo ṣẹ ti Mecca de, sugbọn awọn ajinigbe ka mọle rẹ loru ni bi ọjọ mẹta sẹyin, ti wọn si ji gbe lọ.

"Loru mọju ọjọ Aje yii, wọn tun ya bo ilu wa, wọn si ji awọn onisowo POS meji ọtọọtọ gbe lọ ninu ile wọn lẹyin tan ka wọn mọle.

"Gbogbo wa, a o le sun mọju, nitori iro ìbọn, bi wọn ṣe n lọ lawọn fijilante n tẹle wọn, wọn si n yinbọn sirawọn.

"Isẹlẹ yi lo fa ti awọn ọdọ fi bẹ sigboro ti wọn si n ba awọn nnkan jẹ.

"Wọn ba ile ọba jẹ wọn si dana sun ofisi NDLEA to wa ni Lafiaji, wọn tun jo awọn moto tan ri.

Bi wọn ṣe n se eyi ni awọn araalu n sa kijo kijo ti ọkan gbogbo eeyan o si balẹ.

"Ni bayii, ati ba awọn ọdọ naa sọrọ awọn soja ati awọn ọlọpaa mopo naa ti wọ inu ilu lati ri pe alaafia jọba.

"Awọn fijilante naa ti wọ ilu Lafiagi wa, awọn fijilante yii le ni igba, wọn si ti tọ pa awọn ajinigbe yii lọ".

Iroyin ti a gbọ ni pe, wọn ti mọ ibuba awọn ajinigbe yii, sugbọn wọn o ti mọ bi wọn o se koju wọn nitori ìbọn bajinatu AK47 ti wọn gbe dani, eleyi to lagbara ju tawọn fijilante lọ.

Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ?

Ninu atejade ti agbẹnusọ ọlọpaa ni Kwara, arabinrin Ejire Adetoun Adeyemi fi lede ni ọjọ Aje bakan naa, o fidi isẹlẹ naa mulẹ.

Atẹjade naa sọ pe, ọga agba ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara, CP Adekimi Ojo to fi mọ Ọgagun ajọ soja ilẹ wa ati awọn mii ti sabẹwo si ilu naa ti seto abo to gbopọn fun awọn araalu.

Ninu ọrọ rẹ, CP Adekimi Ojo bẹnu atẹ lu isẹlẹ naa, o rọ awọn ọdọ lati ma ṣe suuru nitori pe ko si ohun to yẹ ko fa biba awọn nnkan ijọba jẹ.

O dupẹ lọwọ gomina ipinlẹ Kwara fun pipese awọn elo bi ọkọ, alupupu ati awọn nnkan mii ti awọn fi n sisẹ ni igberiko