Lẹ́yìn táwọn agbébọn pa bàbá àti ọmọ tán ní ìjọba ìbílẹ̀ Patigi, wọ́n tún ń bèèrè fún ₦200m, tàbí kí wọ́n padà wá

Oríṣun àwòrán, Other
Lẹyin ti awọn agbebọn ya wọ ilu Lile ni ijọba ibilẹ Patigi, ni ipinlẹ Kwara ti wọn si pa awọn eniyan meji, wọn ransẹ pada si ilu naa ki wọn san owo N200,000,000 tabi ki awọn tun ya bo ilu naa fun igba keji lati pa gbogbo ilu ọhun run.
Eleyii waye lẹyin ọjọ mẹrin ti wọn pa onisowo kan ti wọn n pe ni Alhaji Kpotun ati ọmọ rẹ, ti wọn si se aburo rẹ leṣe yana yana.
Bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé
BBC Yoruba kan si alaga ijoba ibilẹ Patigi, Họnọrebu Adams Saidu Rufai, lori ago, o si fidi isẹlẹ naa mulẹ.
Họnọrebu Adams sọ pe loootọ ni ọrọ naa pe wọn ti kan si ẹbi onisowo naa wi pe awọn n pada bọ ti wọn o ba tete san owo to to N400,000,000.
Alaga ijọba ibilẹ naa sọ fun BBC Yoruba pe "igba ti awọn agbebọn naa wa lakọọkọ, ipinnu wọn ni lati ji onisowo naa gbe lọ, sugbọn, o kọ lati tẹle wọn.
Bi awọn agbebọn naa se de, wọn to bi ogun si ọgbọn niye sugbọn awọn perete lo yọju, awọn yoku si farasin.
Wọn ni ki onisowo naa tẹle awọn lẹrọ sugbọn o ba wọn faa pe oun o ni i lọ.''
Alaga ijọba ibilẹ Patigi ni "Ori eyi ni wọn wa ti o fi kigbe sita fun iranlọwọ, aburo rẹ jade si i, awọn mejeeji si jọ waako pẹlu awọn agbebọn.
Nigba to de aarin kan, ipa awọn mejeeji pin nitori wọn pọ ju wọn lọ wọn si ti fẹ maa gbe ẹgbọn lọ.
Eyi lo mu ki aburo ke si ọmọ ẹgbọn rẹ onisowo to wa ninu ile wi pe ko gbe ibọn oun jade, ibi ti o ti n gbe ibọn bọ, ni awọn agbebọn yoku to sa pamọ ti yinbọn fun un lati ẹyin.
Igba ti Alhaji Kpotun ri pe wọn ti pa ọmọ oun lo ba yari kanlẹ, pe lai, oun o ni tẹle wọn lọ.
Eyi lo fa a ti wọn fi yinbọn pa oun naa, wọn si tun ṣe aburo rẹ lese, lẹyin naa ni gbogbo wọn sa lọ pẹlu ẹrọ ibanisọrọ oloogbe naa.''
Họnọrebu Adams ni ẹrọ ibanisọrọ yii ni wọn wa fi n pe awọn ẹbi wi pe awọn n pada bọ ti ilu ba kọ lati san N400,000,000 awọn o si pa gbogbo ilu run.
Alaga ijọba ibilẹ Patigi ni awọn agbebọn naa sọ pe awọn ti n ba onisowo naa sọrọ tipẹ pe ko fun awọn lowo sugbọn o n se agidi titi tawọn fi wa.
Họnọrebu Adams ni awọn o wa lati pa onisowo ọhun sugbon awọn wa ji i gbe ni lati le bere fun owo, sugbọn agidi to n se ti ko tẹle awọn lo jẹ ki awọn pa a ti awọn si mu ẹrọ ibanisọrọ rẹ lọ.
Ìgbésẹ̀ ìjọba ìbílẹ̀ Patigi
Alaga kansu ijọba ibilẹ Patigi ti sọ pe awọn o tii san owo kankan sugbọn awọn ti wa ni igbaradi, awọn si ti ko awọn ẹsọ alaabo sinu ilu naa ati agbegbe rẹ bamu lati da aabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu.
O ni tọsan toru si ni awọn agbofinro fi n sisẹ lati dẹkun ijinigbe atii ipaniyan ni ilu ọhun ati agbegbe rẹ.















