Alhaja Kaola, gbajúmọ̀ oníwáàsí dèrò ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Ilorin, ohun tí a mọ̀ nípa ẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́ láàrín òun àti Akeugbagold rèé

Oríṣun àwòrán, Kaola/Akeugbagold/ Facebook
Ọjọ Aje ọsẹ yii ni ile ẹjọ Majisreeti kan niluu Ilorin, ipinlẹ Kwara, paṣẹ pe ki wọn lọọ fi gbajumọ aafaa obinrin ilẹ Ibadan, Alaaja Kafilat Kaola, pamọ si ọgba ẹwọn Oke-Kura.
Eyi ko ṣẹyin ẹsun ibanilorukọjẹ ti gbajugbaja aafaa nni, Alaaji Taofeek Akeugbagold, fi kan an.
Iroyin sọ pe laipẹ yii ni Alhaja Kaola to tun jẹ agbohunsafẹfẹ, sọ awọn ọrọ ibajẹ nipa Akeugbagold.
Ninu ọrọ naa ni a gbọ pe Kaola ti kilọ fun awọn eeyan to ba n wa imọ, paapaa imọ nipa ẹsin Islam, lati ṣọra fun Akeugbagold.
Obinrin to tun maa n ko awọn eeyan lọ lọ si Meka fun iṣẹ Haji yii, kilọ pe ẹlẹbọ ati oloogun ni Akeugbagold, o ni ki wọn ṣọra fun un.
Ninu awọn ẹsun mi-in ti iroyin sọ pe Kaola fi kan Akeugbagold ni bo ṣe sọ pe aafaa naa maa n fi oogun fẹ awọn obinrin to ba waa ṣe nnkan lọdọ rẹ.
Ṣugbọn Akeugbagold ti awọn eeyan tun mọ si Wazeere Muslimeen ipinlẹ Oyo, dahun nigba naa pe arabu lasan ni gbogbo ohun ti Kaola sọ nipa oun.
Lẹyin naa lo pe Alaaja Kaola lẹjọ ibanilorukọjẹ.
Ọrọ dé kóòtù
Lasiko igbẹjọ naa to waye lọjọ Aje, ni Upper Area Court, Ganmo, ipinlẹ Kwara, agbẹjọrọ Alaaja Kaola, rọ kootu lati fun onibaara rẹ ni anfaani beeli.
Lọọya naa sọ pe eeyan nla ni Alaaja Kafila Kaola, ko si le sa lọ lori ẹsun yii rara.
Fun idi eyi, o ni ki kootu fi aaye silẹ fun un lati maa gba ile waa jẹjọ rẹ.
Ṣugbọn agbẹjọro olupẹjọ, Ajasa Ademola, tako ohun ti lọọya Kaola n beere lọwọ Adajọ.
Agbẹjọro Akeugbagold sọ fun kootu pe ki i ṣe igba akọkọ ree ti Kaola yoo maa jẹ iru ẹjọ yii.
Lati gbe awijare rẹ lẹsẹ, Lọọya Ajasa, fi fidio kan le kootu lọwọ, eyi to ni o ṣafihan Kaola nibi to ti n sọrọ abuku si lọọya ati Adajọ, lori ẹjọ kan to wa nilẹ tẹlẹ.
Agbẹjọro Alaaji Akeugbagold, sọ pe iwa ti Alaaja Kaola hu ninu fidio naa fi han pe ko yẹ lẹni to yẹ ki wọn fun ni anfaani lati maa gba ile waa jẹjọ rara.
Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro mejeeji, Adajọ paṣẹ pe ki wọn lọọ fi Kaola pamọ si ọgba ẹwọn Oke Kura, titi di igba mi-in ti igbẹjọ yoo tun waye.
Igbẹjọ mi-in di ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keje, ọdun 2025.
Ninu fidio kan ti Alaaji Akeugbagold ṣe lori ọrọ yii, o ṣalaye pe gbogbo irọ ti Kaola pa mọ oun ni ko ri i daju pe o yipada.
O ni Kaola pe oun ni agbesunmọmi, oun ko le rin irinajo lọ soke okun mọ nitori ọrọ naa, koun too ṣẹṣẹ ṣe atunṣe awọn iwe oun.
Bakan naa lo ni Alaaja Kaola ati ọkọ rẹ n jẹ oun ni owo to le ni miliọnu mejila naira, Akeugbagold ni ki Kaola da owo naa pada, nitori ọkọ rẹ ti sa lọ.
Alaaji Akeugbagold loun ko ni nnkan kan lati gba ninu ki ọmọlakeji wọ ẹwọn.
O ni o daa ki ẹni to pa irọ tete sọ pe oun ko sọ bẹẹ mọ, pe irọ ni.
Ki ija too de, ọrẹ nla ni Alaaja Kafila Kaola ati Alhaaji Taofeek Akeugbagold.
Ta a ni Alaaja Kafilat Kaola?

Oríṣun àwòrán, Kafilat Kaola/ Facebook
Gbajugbaja ni Alaaja Kafilat Kaola, paapaa niluu Ibadan to fi ṣe ibugbe.
Mama naa ni awọn ileeṣẹ ọlọkan -o-jọkan ati ileewe to n dari, eyi to mu ki o ni ajọṣe pẹlu ọpọ eeyan.
Ọpọ igba ni ẹnu ti kun Alaaja Kaola lori awọn ẹsun ọlọkan-o-jọkan, igba kan si wa ti wọn ni fọnran ibalopọ rẹ lu sita.
Yatọ si Akeugbagold ti wọn jọ n fa ọrọ lasiko yii, Saheed Shittu ti oun naa jẹ aafaa ti ni gbolohun aṣọ fun igba pipẹ ri pẹlu Alaaja Kaola.
Ṣugbọn ọpọ eeyan lo tun nifẹẹ Kaola, nitori oore nla ti wọn lo maa n ṣe kiri fun awọn eeyan.














