Wo àwọn ọ̀nà t'óbìnrin kò gbọdọ̀ gbà káàkiri ilẹ̀ Ijebu nítorí ọdún Agẹmọ tó gbòde

Aworan Agẹmọ

Oríṣun àwòrán, University of Ifa/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lonii ni ọdun Agẹmọ, egungun ti obinrin ko gbọdọ foju ri gberasọ kaakiri gbogbo ilẹ Ijebu nipinlẹ Ogun.

Ikilọ si ti lọ sọdọ awọn obinrin wi pe ki wọn ma gba awọn ọna tawọn Agemo yoo gba kọja lonii ati ọla Ọjọru ọjọ keji, oṣu Keje.

Ni aago kan ọsan ọjọ Iṣẹgun ọjọ kinni, oṣu Keje ni ọdun naa gberasọ.

Fasiti OOU Ago Iwoye kilọ fawọn akẹkọọbinrin lori ọdun Agẹmọ

Igbimọ alaṣẹ ile ẹkọ giga fasiti OOU, Ago Iwoye, ni ipinlẹ Ogun ti rọ awọn akẹkọọbinrin ile ẹkọ naa lati ma gba awọn oju ọna ti eegun Alagemo yoo gba kọja.

Fasiti naa sọrọ yii ninu atẹjade kan ti o fi sita lọjọ Aje ọgbọnjọ, oṣu Keje.

Ninu atẹajde ọhun eyi ti Ọgbẹni Kunle Olayeni to jẹ igbakeji akọwe ẹka ọrọ to n lọ buwọlu ni ile ẹkọ naa ti sọ pe ikilọ yii ṣe pataki tori eewọ ni fun obinrin lati ri eegun Agẹmọ.

''Eyi ni lati sọ fun gbogbo akẹkọọ atawọn oṣiṣẹbinrin Fasiti OOU, Ago Iwoye, wi pe ọdun Agemo ti 2025 yii yoo waye laarin ọjọ Iṣẹgun ọjọ kinni si ọjo keji oṣu Keje yii kaakiri ilẹ Ijẹbu.

"Gẹgẹ bi alakalẹ aṣa ati iṣe awọn Ijebu, obinrin ko gbọdọ foju ri Agẹmọ.

Idi niyi ti a fi rọ gbogbo akẹkọọbinrin atawọn oṣiṣẹbinrin ile ẹkọ giga fasiti OOU, Ago iwoye, wi pe ki wọn ma gba awọn ọna tawọn Alagẹmọ maa n tọ yii."

Wọnyii lawọn ọna ti Agẹmọ yoo gba kaakiri ilẹ Ijẹbu tawọn obinrin o gbọdọ gba

Epe si Ijebu-Ode

Isiwo si Ijebu-Ode

Ijebu Imusin si Ijebu-Ode

Ago-Iwoye – Oru si Ijebu-Ode

Ago-Iwoye si Pepsi Junction si Imodi-Imosan,

Okun-Owa si Agoro/Imodi-Imosan

Odogbolu si Ijebu-Ode.

Ohun to yẹ ki o mọ nipa ọdun Agẹmọ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọdun Agẹmọ jẹ ọdun egungun to maa n waye kaakiri ilẹ Yoruba, amọ, ọdun wọpọ laarin awọn Ijebu nipinlẹ Ogun.

Wọn maa n ṣe irubọ lasiko ọdun yii ni iranti Ooṣa Agẹmọ lati le bu ọla fun un.

Ooṣa Agẹmọ yii lawọn Ijebu gbagbọ pe o maa n daabo bo awọn ọmọde ti wọn jẹ

ọjọ ọla ilẹ Ijẹbu.

Ọdun Agẹmọ fara jọ ẹsin ibilẹ nilẹ Afirika to pe fun kawọn eeyan kan ma rin lasiko ti ọdun naa ba n lọ lọwọ.

Ninu oṣu Keje ọdun ni ọdun Agẹmọ maa n ṣaba waye, ọdun naa si maa n bọ si asiko ti agbado maa n jade si nilẹ Ijẹbu.

Ọjọ meje ni ọdun yii fi maa n waye, o si maa n bẹrẹ lẹyin ti ipade laarin Kabiyesi Awujalẹ ilẹ Ijẹbu atawọn Oloye Alagẹmọ mẹrindinlogun ti wọn n pe ni Olofa ba ti waye tan.

Ọdun Oro pẹlu ilu Gbẹdu lo n maa n ṣaaju ọdun Agẹmọ lọdọọdun, eyi si maa n waye fun ọjọ meje gbako.

Lẹyin naa lawọn Agẹmọ mẹrindinlogun kaakiri ilẹ Ijẹbu yoo lọ si ojubọ niluu Imosan.

Oriṣiiriṣii nnkan bii iyẹ ati iwo agbo lo maa n wa lori awọn Agẹmọ.

Eewọ ni fawọn obinrin lati foju gan-an ni awọn agẹmọ loju ọna wọn si ilu Imosan.

Awọn Agẹmọ maa n duro loju ọna, wọn si maa gbadura fawọn araalu to ba fun wọn lẹbun.

Awọn Agẹmọ tun maa n gba ẹbun ti Kabiyesi Awujale fi ranṣẹ ti wọn ba de Imosan.

Ọjọ mẹta ni wọn maa n lo lojubọ niluu Imosan lati ṣe oriṣiiriṣii etutu ki inu Oriṣa Agẹmọ le yọ si araalu.

Lọjọ to kẹyin ni Imosan lawọn Agẹmọ maa n jo ti gbogbo eeyan to fi mawọn obinrin naa si maa n wa nibẹ.

Lati ibẹ lawọn Agẹmọ yoo ti lọ si Ijebu Ode lati ṣe etutu to kẹyin lasiko ọdun Agẹmọ.

Ọdun Agẹmọ maa pari nigba ti olori wọn ti wọn n pe ni ''Tami Onire'' ba jo niwaju Kabiyesi Awujale, lẹyin naa lawọn Agẹmọ yoku naa yoo bọ sijo.