Àwọn èèyàn ìlú Ido-Ayegunle àti Esa Oke kọlu ara wọn lórí àlà ilẹ̀ ní Osun, ẹ̀mí bọ́, dúkìá ṣòfò, ìlú dahoro

Ilu Ido-Ayegunle
Àkọlé àwòrán, Ilu Ido-Ayegunle dahoro
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

‎Ẹmi eeyan mẹrin ati ọpọlọpọ dukia lo ṣofo ninu ija to waye laarin ilu Esa-oke ati ilu Ido-ayegunle, nipinlẹ Osun.

‎Pupọ ninu awọn ile to wa niluu Ido-ayegunlẹ ni wọn ti sọ di ahoro lẹyin ti wọn dana sun. wọn tan

‎Ti ẹ ko ba gbagbe, lati ọgbọn ọjọ, osu Kinni, ọdun 2025 yii ni wahala ti bẹrẹ nigba tijọba ipinlẹ Osun fi Ọmọọba Oluwatimilẹyin Ajayi jẹ Olojudo ti Ido Ayegunle. Awọn araalu naa fariga pe ko yẹ ki ijọba fi ẹni ti kii ṣe ọmọ ilu awọn jọba, baalẹ to si wa nibẹ tẹlẹ lo yẹ ki ijọba sọ di ọba.

‎Ilu Esa-oke tako yiyan ọba ati ẹni ti ijọba yan gẹgẹ bii ọba si iluu Ido-ayegunlẹ.

‎Awọn Oloye Esa-oke ni, Ido-ayegunlẹ ki ṣe ilu to to lati gba Ọba, nitori pe ọkan lara awọn abule to wa lara iluu Esa-oke ni Ido-ayegunlẹ jẹ.

‎Ẹni ti ijọba fun ni oye ọba Ido-ayegunle, lo wa lati ilu Ilesa ti ko si ni ẹtọ kankan lati jẹ ọba ni iluu Ido-ayegunlẹ rara, gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.

Eyi lo fa ikọlu ti awọn eeyan Ido-ayegun ṣe si iluu Esa-oke ni ọgbọn ọjọ, oṣu Kinni, ọdun 2025 yii, ti wọn si dana sun aafin ati ọkọ ayọkẹlẹ ọba Esa-oke lasiko ikọlu naa.

‎Yatọ si eeyan meji ti wọn ṣi n wa bayii, eeyan mẹrin lo ti dero ọrun, ti wọn si dana sun gbogbo ile to wa niluu naa, latari wahala ija tuntun to bẹ silẹ ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2025 yii ni ilu Ido-ayegunle nitosi Ẹsa-Oke, nipinlẹ Osun.

Ilu Ido-Ayegunle
Àkọlé àwòrán, Ilu Ido-Ayegunle dahoro

‎Gẹgẹ bi Ọbanla ilu Ido-ayegun naa, Ibironke Adebusuyi ṣe sọ, aago mẹwaa aarọ ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa to kọja lawọn janduku ti wọn sọ pe wọn wa lati ilu Ẹsa Oke ya wọ ilu Ido-Ayegunle, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn lakọlakọ.

‎Adebusuyi sọ pe awọn janduku ọhun to ọgọrun, ọkada ni wọn gun wọluu, bẹẹ ni wọn fi aṣọ bo oju wọn, ṣugbọn awọn araalu da awọn kan mọ laarin wọn.

‎Ninu wahala tuntun yii, Adebusuyi sọ siwaju pe awọn janduku naa ge ori ọkunrin kan, wọn si ge ọwọ ẹnikan.

O ni lẹyin ti wọn pa awọn eeyan mẹrẹrin ni wọn tun ju wọn sinu kanga, ti wọn si gbe okuta nla le kọnga naa lori.

‎BBC kan si ijọba Osun, ohun to sọ ree

‎Kọmiṣọna to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati awọn lọbalọba, Dosu Babatunde, ṣalaye pe ija to waye laarin iluu Esa-oke ati ilu Ido-ayegunle ni ọjọ kọkandinlogun, osu Kẹfa, ọdun yii, kii ṣe ọrọ ọlọba de lo mu ija naa wa.

‎Dosu ni ọrọ ija ilẹ lo fa ija to waye yii. O ni ọrọ ọlọba de ti wa nile ẹjọ ati pe awọn ti yan awọn igbimọ kan lori ọrọ naa ti wọn si n tẹsiwaju lori iwadi wọn.

Ki ni ọlọpaa sọ?

‎Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Osun, Abiodun Ojelabi fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe eeyan mẹrin lo padanu ẹmi wọn ninu isẹlẹ naa.

O fi kun pe ootọ ni pe wọn pa awọn kan ti wọn si ko wọn da sinu kanga, ti wọn tun ge apa ati ẹsẹ awọn miran sinu kanga bakan naa.

‎Abiodun sọ pe kọmiṣọna ọlọpaa ti ṣabẹwo si ilu naa, wahala aala ilẹ to si ti wa laarin awọn ilu mejeeji tẹlẹ lo tun ṣokunfa iṣẹlẹ naa.

Ṣugbọn iwadii n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa lati le fi oju awọn to ṣe iṣẹ labi naa lede.