''Èèyàn méje ló kú níbi ìwọ́de tako olórí ìjọba Togo, Faure Gnassingbé''

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Author, Blamé Ekoué & Natasha Booty
- Role, BBC News, Lomé & London
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Awọn ẹgbẹ ajafẹtọọ ti sọ pe eeyan meje lo padanu ẹmi wọn nibi iwọde awọn to n pe fun idasilẹ awọn eeyan to n ṣẹwọn oṣelu lorilẹede Togo.
Awọn oluwọde naa n kepe Aarẹ Faure Gnassingbé orilẹede Togo lati fawọn eeyan naa lominira.
Oku eeyan meje ni wọn ri ninu odo Lomé gẹgẹ bi agbarijọpọ ẹgbẹ Le Front Citoyen Togo Debout to fẹsun iwa ipa kan awọn ẹṣọ eleto abo ṣe ṣalaye.
Ijọba Togo ti sọ pe iṣẹlẹ awọn eeyan to ku naa ko ni nnkan ṣe pẹlu iwọde to waye lọsẹ to kọja.
Koda, ijọba ti n gbero lati gbe awọn to ṣagbatẹru ifẹhonuhan naa lọ si ile ẹjọ, ijọba ni ọna lati pin iroyin ofege kaakiri ni iwọde naa jẹ.
Ijọba tun sọ pe lati ilẹ okeere lawọn kan ti n ṣe onigbọwọ ifẹhohuhan ọhun.
Ọpọ eeyan ni inu wọn ko dun ni Togo lori bi ijọba ṣe pawọn eeyan lẹnu mọ ati ayipada ti ijọba ṣe lori iwe ofin orilẹede naa eyi tawọn alatako ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii iditẹgbajọba labẹle.
Ifẹhonuhan bẹrẹ lẹyin ti wọn bura fun Gnassingbé, ẹni to ti wa nipo aarẹ Togo fun bi ogun ọdun ti ẹbi rẹ si ti n ṣejọba orilẹede naa fọdun mejidinlọgọta, gẹgẹ bii aarẹ ajọ awọn minisita ti ko ni asiko ti yoo kuro nipo naa.
Lati ọdun 2022 ni ijọba ti fofin de ifẹhonuhan ni Togo tori akoba to le ṣe fun eto abo.
Iwọde ọlọjọ mẹta tawọn ajijagbara kan ṣagbatẹru lori itakun ayelujara bẹrẹ l'Ọjọbọ ọsẹ to kọja, ki o to di rogbodiyan lọjọ Ẹtoi ati ọjọ Abamẹta ọsẹ to lọ.
Awọn ọlọpaa yin taju-taju sawọn oluwọde tawọn naa si n ju oko pada sawọn agbofinro.
Ọpọ awọn oluwọde naa koju awọn ẹṣọ eleto abo kaakiri oju popo to fi de awọn agbegbe ti ẹgbẹ alatako pọ si bii agbegbe Bè tawọn ọlọpaa ti le awọn oluwọde sa wọ inu kọrọ ti wọn ti jade wa.
Ẹwẹ, agbarijọpọ ẹgbẹ alatako mẹtalelogun ti kepe ijọba lati ṣe iwadii awọn ọlọpaa ti wọn ṣeku pawọn olufẹhonuhan.
Awọn ẹgbẹ ọhun bu ẹnu atẹ lu bawọn ọlọpaa ṣe yinbọn mawọn oluwọde ti ko si nnkan ija oloro kankan lara wọn.
Ẹgbẹ naa sọ pe ẹtọ ọmọniyan ni ṣiṣe iwọde jẹ fawọn araalu, ati pe o wa ninu iwe ofin orilẹede Togo bẹẹ.
Rogbodiyan naa ti rọlẹ lọjọ Aiku, awọn ọlọja si ti n ṣi ṣọọbu wọn pada lọja Assigamé.
Ipo tuntun ti Gnassingbé tun ṣẹṣẹ gba wa lara awọn nnkan to n bawọn araalu ninu.
Bi wọn ṣe mu olorin takasufee lorilẹede Togo, Narcisse Essowè Tchalla, ti wọn si tun ju u si atimọle naa wa lara nkan to n bawọn eeyan ninu.
Bakan naa tun lawọn agbofinro tun fọwọ ofin mu eeyan bii aadọta lasiko iwọde to waye sẹyin losu Kẹfa ọdun yii.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn eeyan naa lo ti gbominira, mẹta si tun wa ni ahamọ.















