Adájọ́ kẹ́de ọjọ́ ìdájọ́ fún Abdulraman Bello àtàwọn míràn tí wọ́n fi ẹ̀sùn ṣíṣekúpa akẹ́kọ̀ọ́ obìnrin kàn ní Ilorin

Aworan Bello, Hafsot, ati abawọle ile ẹjọ giga ilu Ilọrin.

Oríṣun àwòrán, other/ BBC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Igbẹjọ Abdulraman Bello ati awọn afurasi mẹrin miran ti wọn fẹsun ipaniyan kan tẹsiwaju loni ọjọru ọjọ keji oṣu keje ọdun yíì.

Abdulraman Bello ati awọn mẹrin ni wọn n jẹjọ ni ile ẹjọ giga ipinlẹ kwara ni ilu Ilọrin.ipinle Kwara.

Níbi igbejọ to kọja ni Abdulraman Bello ati awọn mẹrin naa ti wi awijare wọn ni ile ẹjọ.

Ibi igbẹjọ naa ni Abdulraman Bello ti ni oun kọ loun pa Hasfot Lawal.

Eyi ni ohun to sẹlẹ lonii ni Ile ẹjọ.

Awọn eeyan ni ile ẹjọ.

Igbejọ bẹrẹ lago mẹsan kọja isẹju diẹ labẹ adajọ Christiana Ajayi ti ile ẹjọ giga ipinlẹ kwara.

Kọmisona feto idajọ to tun se amofin agba ipinlẹ kwara,Senior Ibrahim loko awọn agbẹjọro ijọba ipinlẹ Kwara sodi .

Chukwudi Maduka ni agbẹjọro olujẹjọ kinni, A S Oseni ati Suleiman Alamonyọ soju olujẹjọ kẹta, M A Yusuf jẹ agbẹjọro olujẹjọ kẹrin.

Lẹyin afihan awọn agbẹjọro, awọn agbẹjọro olujẹjọ keji, ikẹta ati ikẹrin , pẹlu agbẹjọro olujẹjọ karun rọ adajọ lati tu awọn olujẹjọ keji, ikẹta, ikẹrin ati ikarun silẹ. niwon igba ti wọn o ti ri ẹri kankan pe wọn lọwọ si ẹsun ipaniyan.

Aworan awọn eeyan ni ile ẹjọ.

Awọn agbẹjọro naa ni gbogbo ẹri ti awọn ọlọpaa ati ajọ eleto abo ọtẹlẹmuyẹ (DSS) mu wa si ile ẹjọ fihan pe, awọn mẹrin to ku ko lọwọ si iṣẹlẹ ipaniyan ti Abdulraman Bello hu ní wa.

Pẹlu afikun pe, Abdulraman Bello funrarẹ ti sọ niwaju ile ẹjọ pe awọn mẹrin to ku ko mọ kankan nípa ikú Hasfot Yetunde Lawal.

Agbẹjọro Abdulraman Bello naa rọ ile ẹjọ lati sagbeyẹwo awọn akọsilẹ ati ọrọ ti Abdulraman Bello sọ ni ile ẹjọ , agbẹjọro ijọba si tako .

Agbẹjọro ijọba ni gbogbo awọn ti awọn fẹsun kan naa si ni awọn fẹsun kan.

Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro, adajọ kede pe ọjọ kokanlelọgbọn osu keje ni idajọ yoo wáye.