Ìgbẹ́jọ́ Abdulrahman Bello gbọ̀nà míràn yọ n'Ilorin, ó yí òun padà lórí ẹni tó pa Hafsot Bello

"Emi kọ ni mo pa Hafsot Yetunde Lawal, iya ti awọn ọlọpaa fi jẹ mi, lo jẹ ki n parọ pe emi ni mo pa a."
Eyi ni oun ti afurasi akọkọ to n jẹjọọ lori iku ọdọmọbinrin, Hafsot Lawal, ti wọn ba oku rẹ ninu ile Alfa ọhun niluu Ilorin, sọ.
Igbẹjọ Abdulrahamn Bello, afurasi to pa Hafsot Yetunde Lawal, ati awọn mẹrin mii ti wọn ti jọ fi ẹsun kan, tẹsiwaju nile ẹjọ giga ijọba ipinlẹ Kwara lonii.
Akẹkọọ ile ẹkọ giga olukọni to wa niluu Ilorin ni oloogbe Hafsot, ko to o pade iku ojiji ninu oṣu Keji, ọdun 2025.
Taa lo pe Hafsot Lawal?
Akọroyin BBC to wa nibi igbẹjọ naa sọ pe afurasi akọkọ, Abdulrahman, sọ fun ile ẹjọ pe iṣẹ alfa to n kọ ọmọ ni kehu ati awọn nnkan mii ti alfa n ṣe ni iṣẹ oojọ oun.
Afurasi naa sọ pe ọjọ kẹwa, oṣu Keji ọdun 2025 ni oloogbe Hasfot Yetunde Lawal to jẹ ololufẹ oun wa si ile oun, lẹyin ọpọlọpọ ọjọ to ti ma n ṣeleri lati wa oun wa.
O ni bo se de si ọdọ oun, o sọ fun oun pe ebi n pa oun, oun si lọ bara burẹdi ati fanta, bi oun se ra a de, oloogbe naa ni oun ni aisan ọgbẹnu oun o le mu fanta.
"Mo jade pada lọ ra irẹsi fun un, ti a si jọ jẹun ninu ile, gẹgẹ bi ololufẹ meji ti ifẹ si wa laarin awọn."
Lẹyin ounjẹ lo ni awọn wọ yara lọ, ti awọn si jọ ni Ibalopọ ninu yara. O ni, nibi ti awọn ti n jọ ni ajọṣepọ lọwọ ni ko ti gbadun mọ.
Oun si sare wo inu bagi rẹ lati fun ni inhaler nitori o ni aisan ikọ semi-semi, ti wọn n pe ni asthma, ti oun si tun sare wa oogun lọ fun.
O fikun pe, igba ti oun o fi ra inhaler ti wọn ma n fin simu de, oku rẹ ni oun ba ninu ile.
"Bi mo ṣe ba oku rẹ ninu ile ni ẹru ba mi."
Afurasi naa tẹsiwaju pe oloogbe naa tiṣaaju mu oun lọ ba awọn obi rẹ ṣugbọn awọn obi rẹ ni awọn ko le fẹra nitori oun ko kawee.
"Awọn nnkan wọn yii lo mu ki jinijini bo mi, ti mo si lọ ra ọti lile lati mu, lẹyin naa ni mo kun oku rẹ wẹlẹwẹlẹ."
Abdurahman ni bi oun ṣe mu ọti lile naa tan, ni ero kan sọ si oun lọkan pe ki oun kun oku rẹ wẹlẹwẹlẹ nitori oun ko le dáa gbe, ẹru awọn obi rẹ si n ba oun.
Eyi lo si mu ki oun kun Hasfot Yetunde Lawal wẹlẹwẹlẹ ti oun si salọ ile mọlẹbi oun ni agbegbe Isal- koto niluu Ilọrin nibi ti awọn ọlọpaa ti wa mu oun.
Ṣaaju ni afurasi naa ti kọkọ sọ ni igbẹjọ to kọja pe, lasiko ti oun ati oloogbe n ni ibalopọ lọwọ, ni oun fun un lọrun pa.
Ṣé ó wù ọ́ láti mọ bí ìgbẹ́jọ́ yìí ṣe n tẹ̀síwájú? Darapọ̀ mọ́ Whatsapp channel wa
Awọn ọlọpaa fi ipa mu mi kọ nnkan to yatọ
O ni, irọlẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinla oṣu Keji, ọdun 2025 ni awọn ọlọpaa beere bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ, ti oun si salaye fun wọn, ti wọn si ju oun si ahamọ.
Ọgbẹni Abdulrahman ṣalaye pe nigba to di oru ọjọ naa ni wọn mu oun jade kuro ni ahamọ, wọn si mu oun wọ yara kan lọ, ibẹ ni wọn ti bẹrẹ si lu oun pe ti oun ko ba fọwọsowọpọ, awọn yoo pa oun.
"Wọn si gbe iwe mi siwaju mi, eyi to yatọ si eyi ti mo ti ṣaaju kọ silẹ, wọn si ni ki n maa da kọ si iwe miran.
O ni oun ṣakiyesi pe wọn ti fi nnkan mi kun ọrọ ẹnu oun ti oun ti kọkọ kọ silẹ, ati pe nigba ti lilu pọ ni ohun sọ pe ohun yoo se ohun ti wọn ba fẹ.
O fikun ọrọ rẹ pe lọjọ kerindinlogun osu keji, wọn mu oun jade lati ahamọ, wọn si gbe baagi kan siwaju ohun lati maa tu ohun to wa ninu rẹ jade.
O salaye siwaju si pe ọjọ kerindinlogun, osu Keji ni awon eleto abo ọtẹlẹmuyẹ DSS wa ko awọn kuro ni ọgba ẹwọn to w ani Okekura.
Awọn marun ni wọn ko, ṣugbọn oun nikan ni wọn fi si yara ọtọ, awọn si lo osu kan ati ọjọ mẹta lọdọ wọn.
O ni awọn ẹṣọ alabo ni ti oun ko ba fọwọsowọpọ, aṣẹ ti wa lati oke pe ki wọn o pa oun.
Wọn bi oun leere pe taa ni oun ta ẹya ara oloogbe fun, oun si ni oun ko ni ẹnikankan ti oun ta fun.
O salaye pe eẹmeji lọsẹ ni wọn ma n lu oun bi kiku bi yiye, oun kọ ni oun pa Hafsot oun nifẹ rẹ pupọ.
O ni nigba ti lilu pọ ni ohun fi sọ pe lootọ ni oun pa ọmọbinrin naa.
Ni ipari ọrọ rẹ, Abdurahman Bello sọ pe awọn mẹrin yooku ti wọn jọ mu awọn, ko mọ nkankan nipa iku oloogbe.
Agbẹjọro ijọba beere awọn ibeere lọwọ afurasi
Ninu ọrọ rẹ, agbẹjọro fun ijọba ipinlẹ Kwara, Ayọọla Akande, sọ pe awọn ẹri to wa ni iwaju ile ẹjọ fidirẹ mulẹ pe Abdurahman Bello lo pa oloogbe Hafsot, to si rọ ile ẹjọ lati gba gbogbo ẹri wọn yii wọ le.
O ni Lara awọn ẹri ni ada,aake ati ọbẹ ti awọn ọlọpaa b anile rẹ.
Bakan naa lo beere pe njẹ Abdurahman Bello pe dokita lati wo boya Yetunde ti ku lootọ tabi o ṣi wa laye, ko to o yọ ọbẹ ti oku rẹ. ati pe eeyan melo loti ku loju rẹ ri.
Bakan naa lo tun beere lọwọ rẹ pe njẹ o mọ ibi ti ẹni to pe ni ololufẹ rẹ ti n ṣiṣẹ, amọ iyalẹnu lo jẹ pe afurasi naa ko le dahun ibeere ọhun.
Lara awọn ibeere ti agbẹjọro tun bi afurasi naa ni pe ki ni idi ti ko fi lọ ọ fi ọrọ to awọn ọlọpaa leti nigba to ba ọmọbinrin naa to ti 'ku', eyi ti Abdulrahman fesi pe, agọ ọlọpaa jina sile oun ni oun ko fi lọ.
Ẹwẹ, ko ri idahun si ibeere ti agbẹjọro ijọba bi I pe, ki lo de ti ko da ọwọ oloogbe mejeeji, ati ẹjẹ rẹ ti wọn ba ninu ile rẹ lẹyin ọjọ marun un.
Agbẹjọro bi Abdurahman Bello lere pe igba ti baba ọmọ naa bi ọ lere lagọ ọlọpaa pe ibo ni Hasfot wa ki lo sọ, Abdurahman ni oun sọ pe ohun o mọn ibi ti Hasfot wa.
Ni ipari ibeere rẹ, agbẹjọro ijọba sọ pe Abdurahman Bello mọọmọ pa Hafsot Yetunde Lawal ni, to si fi ọwọ ati ẹjẹ rẹ pamọ sinu ile lati fi sẹ nnkan, amọ ti afurasi naa sọ pe ọrọ ko ri bẹẹ.
Awọn mii to tun n jẹjọ ni Abdulwasiu Hammed , Suleiman Muhideen , Usman Muhammed ati ẹni karun wọn.
Lẹyin gbogbo ibeere ati awijare agbẹjọro ijọba, adajọ gba gbogbo ẹri ti wọn ko wa sile ẹjọ wọle, to si sun igbẹjọ miran si ọjọ keji, oṣu Keje, ọdun 2025.












