Àṣìrí ikú tó pa afurasí tó kú sí àhámọ́ ọlọ́pàá tú síta, ayẹ̀wò sọ pé wọ́n la nǹkan mọ́ ọ lórí ni

Oríṣun àwòrán, EPA
Iwadii ti fihan pe nṣe ni wọn fi nnkan lu arakunrin sọrọsọrọ ori ayelujara kan lorilẹede Kenya to ku si ahamọ ọlọpaa lori at iwi pe o ṣeeṣe ki iku rẹ o ma ṣẹyin ikọlu naa.
Abajade iwadii oku yii tako ohun ti awọn ọlọpaa n sọ wi peAlbert Ojwang "fi ori ṣeṣe ni lẹyin to gba ori mọ ogiri atimọle ti wọn fi si".
Iku arakunrin naa ti da ọpọlọpọ hilahilo silẹ kaakiri orilẹede Kenya, pẹlu bi awọn ẹg ajafẹtọ ọmọniyan ti ṣe n fi ẹhonu pe fun igbesẹ lati rii daju pe awọn ọlọpaa jẹjọ lori ohun to ṣokunfa iku rẹ. wọn fi Ọgbẹni Ojwang si ahamọ lẹyin ti igbakeji ọga ọlọpaa kan fi ẹsun kan an pe o bao un lorukọ jẹ lori ayelujara.
"Ohun to ṣokunfa iku rẹ han kedere; ọgbẹ ori, ifunnilọrun gagaga atawọn ọgbẹ miran to lọ kaakiri agọ ara rẹ n tọka si pe wọn fi ipa lu u, " ni ọrọ ti ọga agba awọn alayẹwo oku ni ipinlẹ naa, Bernard Midia sọ.
Awọn ọlọpaa ko tii fesi lori rẹ.
Ta ni Ojwang?
Ọgbẹni Ojwang jẹ sọrọsọrọ ori ayelujara; awọn nnkan to nii ṣe pẹlu oṣelu ati ọrọ to n lọ lawujọ lo maa n gbe yẹwo lori ayelujara bii X ati Facebook. Ọjọ Ẹti ni wọn si fi panpẹ ofin mu u ni ilu Homa Bay, lẹku iwọ oorun Kenya.
Ẹni ọdun mọkanlelọgbọn naa to tun jẹ olukọni wọ gbaga ọlọpaa lẹyin ti wọn mu u fun ohun kan to fi sita loju opo X rẹ, eyi ti wọn ni o sọrọ alufansa si igbakeji ọga ọlọpaa orilẹede naa, Eliud Lagat.
Wọn gbe e lọ si olu ilu orilẹede naa, Nairobi to jẹ iwọn bii okoolelugba maili si ilu rẹ lọjọ Abamẹta.
Awọn ọlọpaa sọ pe awọn kan ba a pe o ti daku ninu atimọle ti wọn fi si pẹlu ọpọlọpọ ọgbẹ to fi ṣe ara rẹ.
Ki ni abajade ayẹwo ti wọn ṣe fun oku sọ?
Amọṣa ayẹwo kan ti wọn ṣe fun oku rẹ. eyi ti awọn akọṣẹmọṣẹ ayẹwo oku marun un ṣe ti wọn si tun gbe ayẹwo alafẹnuko kan jade ninu eyi ti wọn ti yọju rẹ sita pe, ọpọlọpọọgbẹ ori, ifunilọrun atawọn ọgbẹ miran wa lara ohun to ṣe oloogbe naa ko to ku.
Dokita Midia ni oloogbe naa ko fi ori gba ogiri gẹgẹ́ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ ninu atẹjade wọn.
O ni to ba jẹ pe bẹẹ lọrọ ri ni, apa ori rẹ yoo yatọ, wọn o si ri oju ẹjẹ kankan niwaju ori rẹ.
Baba Ojwang, Meshack Ojwang ti ke si Aarẹ William Ruto lati wa nnkan ṣe si ọrọ iku ọmọ oun.














