Omi tuntun rú lágbo òṣèlú Naijiria, Mark, Aregbesola di adarí ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ADC, APC ní kò séwu

Aworan David Mark ati Rauf Aregbesola

Oríṣun àwòrán, Kola Ologbondiyan/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Omi tuntun ti ru, ẹja tuntun si ti wọ ọ lagbo oṣelu orilẹede Naijiria lẹyin ti agbarijọpọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako, African Democratic Congress (ADC), yan aarẹ ile igbimọ aṣofin agba tẹlẹ ri, Sẹnẹtọ David Mark, gẹgẹ bii alaga fidihẹẹ ẹgbẹ oṣelu naa ati Rauf Aregbesola, gomina ipinlẹ Osun tẹlẹ gẹgẹ bii akọwe fidihẹẹ ẹgbẹ naa.

Lana ọjọ kinni oṣu Keje ọdun yii ni ẹgbẹ ADC ṣe ikede awọn oloye ẹgbẹ ọhun lẹyin ipade awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ naa to waye niluu Abuja.

Ireti wa wi pe nibi ipade ẹgbẹ naa ti yoo waye l'Ọjọru oni ni gbogbo ile yoo ti buwọlu iyansipo naa ti ko si ni jẹ fidihẹẹ mọ.

Akọwe iroyin ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ to tun jẹ oludamọran fun Sẹnẹtọ Mark tẹlẹri, Kola Ologbondiyan, lo fọrọ naa lede loju opo X rẹ.

O ṣalaye loju opo X rẹ pe ''ẹgbẹ oṣelu ADC ti di ẹgbẹ osẹlu agbarijọpọ awọn oloṣelu.

Ẹgbẹ ADC ti yan Sẹnẹtọ David Mark gẹgẹ bii alaga fidihẹẹ ati Rauf Aregbesola gẹgẹ bii akọwe fidihẹẹ ẹgbẹ naa.''

''Ẹgbẹ oṣelu ADC gbọdọ yatọ sawọn ẹgbẹ oṣelu yooku ni Naijiria''

Ninu ọrọ rẹ lẹyin ti wọn kede iyansipo rẹ tan, Ọgbẹni Aregbesola sọ pe ẹgbẹ oṣelu ADC gbọdọ yatọ sawọn ẹgbẹ oṣelu yooku ni Naijiria nipa nini nnkan kan gboogi tawọn eeyan yoo mọ wọn fun.

O ni ofifo agba lasan lọpọ ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria pẹlu bawọn ẹgbẹ naa ṣe n tuka tawọn ọmọ ẹgbẹ si n darapọ mọ awọn ẹgbẹ mii

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aregbesola ni ''ọpọ ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria ni ẹnikẹni ko le so nnkan ti wọn duro fun gan an.

Wọn kuro lati ẹgbẹ kan si omiran nitori agbara, kii ṣe nitori araalu, kii sii ṣe nitori ifẹ ti wọn ni si orilẹede Naijiria gan an.

Ẹgbẹ oṣelu tiwa ko gbọdọ ri bayii, kii ṣe iru ẹgbẹ bayii lemi maa wa.

A gbọdọ jẹ ẹgbẹ oṣelu ti yoo maa sọ nipa eto ẹkọ, a ni lati maa kọ ile ẹkọ.

A tun gbọdọ maa sọ nipa eto abo fun araalu, bakan naa ni ẹgbẹ ADC gbọdọ maa sọ nipa ipese iṣẹ fun araalu.

Awọn nnkan wọnyi ni ṣe pẹlu ohun ti yoo ṣe anfaani fun orilẹede Naijria.

Kii kan ṣe ọrọ eto idibo nikan ni a maa sọrọ nipa rẹ, bi ko ṣe eto iṣejọba to dara,'' Aregbesola ṣalaye.

Aregbesola ni iṣẹ pọ fawọn lati ṣe ninu ẹgbẹ ADC ni toootọ, amọ, o gbagbọ wi pe ẹgbẹ ADC le mu ayipada ọtun ba orilẹede Naijiria.

''Iṣẹ to wa niwaju wa ko rọrun rara, o si maa gba akoko pẹlu nitori iṣẹ naa nilo ifara ẹni jin.

Amọ, nnkan to ṣee ṣe ni, nitori naa ni mo fi beere fun atilẹyin yin.

Mo fẹ ki gbogbo eeyan duro ti wa bi a ti bẹrẹ irinajo ọtun yii ninu eto oṣelu Naijiria.

A fẹ lo ẹgbẹ oṣelu ADC lati da eto oṣelu pada sibi to yẹ ko wa ni Naijiria,'' Aregbesola lo sọ bẹẹ.

Oniruuru oloṣelu lati inu awọn ẹgbẹ alatako lo korajọ pọ lati da ẹgbẹ oṣelu ADC silẹ lati le koju ẹgbẹ oṣelu APC to jẹ ẹgbẹ Aarẹ Bola Tinubu ninu eto idibo gbogbogbo ọdun 2027.

Lara awọn abẹnugan to n pe fun ajọsẹpọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ni igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ, Atiku Abubakar; oludije aarẹ fẹgbẹ oṣelu LP ninu ibo aarẹ ọdun 2023, Peter Obi, gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ ri, Nasir el-Rufai; ati minisita igbokegbodo ọkọ tẹlẹ ri ni Naijiria, Rotimi Amaechi.

Loṣu Karun un to kọja lawọn adari egbẹ oṣelu alatako ni Naijiria pinnu lati lo ẹgbẹ oṣelu ADC lati koju APC ninu eto idibo ọdun 2027.

Nigba to n sọrọ lọsẹ ti kọja, Ralph Nwosu, to da ẹgbẹ naa silẹ sọ pe o ni idi tawọn fi yan Sẹnẹtọ David Mark gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ naa.

Ata akara ti ko ran ikọ lọrọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako to kora jọ pọ - Dalori

Ẹwẹ, adele alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Ali Bukar Dalori, ti sọ pe bawọn ẹgbẹ oṣelu alatako ṣe kora jọ pọ ko tun irun kankan lara ẹgbẹ naa.

Dalori to bẹrẹ iṣẹ lana ọjọ Aje ti kọkọ wa nipo igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu APC lẹkun ariwa Naijiria tẹlẹ.

Ninu ifọrọwanilẹnu to ṣe pẹlu BBC Hausa, Dalori ni ohun to ṣe pataki foun bayii ni yiyanju ikunsinu to wa laarin awọn ọmo ẹgbẹ oṣelu APC lawọn ipinlẹ ati ijọba ibilẹ kaakiri Naijiria.

''Mo maa gbiyanju lati ri wi pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ APC ti wọn ni ikunsinu si ara wọn ni mo yanju rẹ.

Mo maa jokoo pẹlu wọn lati yanju ọrọ naa tori a nilo ara wa ninu ẹgbẹ,'' Dalori lo sọ bẹẹ.

Adele alaga ẹgbẹ APC ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe ẹgbẹ ko tii mu ọjọ kan gboogi fun ipade gbogbogbo kaakiri Naijiria tori awọn ni lati bawọn agbaagba ẹgbẹ sọrọ na kawọn to mu ọjọ.