Èyí ni ìdájọ́ tuntun tí ilé ejọ̀ gbé kalẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Naira Marley, Sam Larry àti Mohbad

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko to n jokoo niluu Ikeja ti wọgile ẹjọ ti Arakunrin Joseph, baba oloogbe olorin takasufe, Ilerioluwa Aloba. ẹni ti ọpọ mọ si Mohbad, pe tako igbesẹ ile ẹjọ lati tu Naira Marley, Sam Larry ati awọn yooku to jẹ afurasi ti ijọba mu lori iku Mohbad silẹ.

Adajọ Taiwo Olatokun, ninu idajọ rẹ lọjọru, Ọjọ Kẹta oṣu keje ọdun 2025 ni igbesẹ ile ẹjọ lati tu awọn afurasi naa silẹ lo wa nibamu pẹlu ofin orilẹede Naijiria.

Eyi lo fa idi ti ile ẹjọ fi wọgile ipe, ti wọn si ni ko ni ẹsẹ ni ilẹ rara.

Joseph Aloba, ẹni to wa ni ile ẹjọ pẹlu awọn eeyan mii ti wọn jẹ ololufẹ Mohbad, ni inu wọn ko dun si igbesẹ ati idajọ ile ẹjọ.

Nigba to n sọrọ ni ile ẹjọ, agbẹjọro olupẹjọ, Wahab Shittu ni oni baara oun ṣetan lati morile ile ẹjọ kotẹmilọrun lati tako igbẹjọ.

Ki gan an ni idajọ ile ẹjọ to tu Naira Marley, Sam Larry silẹ sọ?

Ile ẹjọ majisireeti to wa ni agbegbe Yaba nipinlẹ Eko, ti gbe idajọ kalẹ lori ipa ti Naira Marley, Sam Larry ati Primeboy, ko ninu iku Mohbad.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ni Onidajọ Ejiro Kubenje gbe idajọ naa kalẹ "ni ibamu pẹlu imọran ati alakalẹ lati ẹka eto idajọ nipinlẹ Eko.

Onidajo Kubenje sọ pe gbajugbaja akọrin takasufe, Abdulazeez Fashola, ti ọpọ mọ si Naira Marley, ko lọwọ si iku to pa Aloba IleriOluwa, ti awọn eeyan tun mọ si Mohbad, ti ko si ni ẹjọ lati jẹ lori iṣẹlẹ ọhun.

Yatọ si Naira Marley, ile ẹjọ tun da Balogun Samson eletu, ti ọpọ si Sam Larry, Owodunni Ibrahim, to tun n jẹ Primeboy, to fi mọ mọnija Mohbad nigba kan, Opere Babatunde, silẹ.

Ṣugbọn ṣa, ile ẹjọ ni wọn yoo foju nọọsi to tọju Mohbad, Feyisayo Ogedengbe, ati ẹnikan lara awọn ọrẹ Mohbad, Ayobami Sadiq, fun ẹsun ailakasi ati fifi ọwọ yẹpẹrẹ mu nnkan.

O ni eyi wa ni ibamu pẹlu abala 251 (e) ofin iwa ọdaran ti wọn gbe kalẹ nipinlẹ Eko lọdun 2015.

Ki lo ṣẹlẹ saaju?

Ninu oṣu keji ọdun yii, Ile ẹjọ Magistrati to gbe idajọ kalẹ lori igbẹjọ gbajugbaja olorin to ti di oloogbe, Ilerioluwa Aloba, ẹni ti ọpọ mọ si Mohbad ṣalaye pe oloogbe naa ti wọgile ẹjọ to pe tako ọga rẹ, Abdulazeez Fashola, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Naira Marley ni ileeṣẹ ọlọpaa Ilasan to wa ni agbegbe Lekki ni ọjọ kẹjọ oṣu kẹwaa ọdun 2022 saaju ko to jade laye.

Eyi jẹ ọkan lara awọn idi pataki ti ile ẹjọ Magistrati to n jokoo ni agbegbe Yaba fi da Naira Marley ati awọn yooku lare pe ko lọwọ ninu iku Mohbad.

Ile ẹjọ tun tun da agbe orin larugẹ, Samson Balogun Eletu, ti wọn n pe ni Sam Larry, mọnija Mohbad tẹlẹ, Babatunde Opere ati Ibrahim Owodunni ti wọn n pe ni Primeboy lare pe wọn ko lọwọ ninu iku oloogbe naa.

Ta a ni Mohbad?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 1996 ni wọn bi Ilerioluwa Oladimeji Aloba.

Orukọ ti ọpọ eeyan mọ olorin naa si kaakiri agbaye ni Mohbad.

O jẹ olorin takasufe, o tun maa n kọ orin silẹ funra rẹ tabi fun awọn olorin miran bii tirẹ.

Abẹ asia ileeṣẹ Naira Marley, iyẹn Marlian Records lo wa tẹlẹ ko to kuro labẹ asia ileeṣẹ naa lọdun 2022.

Lara awọn orin rẹ to milẹ titi julọ ni Ponmo, Feel Good, ati KPK 'Ko Por Ke,' eyii to gbe jade pẹlu Rexxie, ti wọn si fa kalẹ gẹgẹ bii ọkan lara awọn orin to ta lẹnu julọ fun ami ẹyẹ Headies lọdun 2022.

Ọdun 2020 lo kọkọ gbe awo orin rẹ 'Light EP' jade lẹyin orin rẹ 'Ponmo'to milẹ titi, eyii to ṣe pẹlu Naira Marly ati Lil Kesh.

Lọdun 2021, o wa lara awọn olorin ti awọn eeyan gbọ julọ lori Audiomack ni ẹka orin Afrobeat.

O wa loke tente tabili TurnTable lọdun 2021, o tun gbiyanju bakan naa lọdun 2022.

Ninu oṣu keji ọdun 2023, ajọ to n gbogun ti egboogi oloro ni Naijiria, NDLEA, mu oun, Zinoleesky atawọn olorin mii lẹyin ti wọn ka oogun oloro igbo mọ wọn lọwọ nile kan to wa lagbegbe Lekki, niluu Eko.