Ọkọ̀ òfúrufú ọmọ ogun já lulẹ̀ pẹ̀lú èèyàn mẹ́jọ inú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Munasar Mohamed
Ọkọ ofurufu ẹlikọpita ileeṣẹ ọmọ ogun Uganda kan ti ja lulẹ pẹlu eeyan mẹjọ to wa ninu rẹ.
Awọn alaṣẹ orilẹede naa sọ fun BBC pe papakọ ofurufu to wa niluu Mogadishu, to jẹ olu ilu orilẹede ọhun ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Ileeṣẹ iroyin ijọba orilẹede naa sọ pe ina ṣẹyọ lẹyin ti ọkọ ofurufu ọhun ja lulẹ ni papakọ ofurufu Aden Adde, amọ awọn oṣiṣe pajawiri ti pa ina ọhun.
Awọn aworan kan lori ayelujara ṣafihan bi eefin ṣe n ru jade ni papakọ ofurufu naa.
Farah Abdulle, to jẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ papakọ ofurufu naa sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe "A gbọ ibugbamu, lẹyin naa ni a ri ina to ṣẹyọ lara ẹlikọpita naa ti eefin si n jade lara rẹ."
Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, a ko tii le sọ ohun to ṣokunfa ijamba ọkọ ofurufu naa ati iye eeyan to ba ijamba ọhun lọ.
Olori ajọ to n ri si irinajo ofurufu orilẹdee naa, Somali Civil Aviation Authority, Ahmed Maalim, sọ fun BBC pe agbegbe Lower Shabelle, ni ariwa Mogadishu ni ọkọ ofurufu naa ti wa ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.
O ni awọn ti bẹrẹ iwadii lati ṣawari ohun pato to ṣokunfa ijamba naa.
Awọn ọmọ ogun Uganda wa lara awọn ọmọ ogun ẹgbẹ African Union to n kọju ija si awọn jagunjagun al-Shabab ti al-Qaeda n ṣatilẹyin fun.
Awọn jagunjagun al-Shabab yii lo ti n da omi alaafia Uganda ru lati nnkan bii ọdun mẹwaa o le diẹ sẹyin.
Bo tilẹ jẹ pe baluu na ja, awọn ọkọ ofurufu mii ṣi papa gbera lẹyin iṣẹlẹ ọhun.















