"A fẹ́ kí àwọn ọmọdé mọ̀ nípa Awùjalẹ̀ ni a fi kọ ìtàn rẹ̀"

Àkọlé fídíò, A fẹ́ kí àwọn ọmọdé mọ̀ nípa Awùjalẹ̀ ni a fi kọ ìtàn rẹ̀

Gbogbo wa ni a mọ ipa ti itan n ko ninu idagbasoke awọn ọdọ lawujọ.

Itan mimọ maa fun awọn ọdọ wa ni anfani lati mọ nipa orisun wọn ati ipa ti awọn eeyan kan ko lati mu idagbasoke ba agbegbe wọn.

Eyi lo mu ki awọn olukọtan kan kora wọn jọ lati kọ itan nipa Awujale ti ilẹ Ijebu, Ọba Sikiru Adetona.

Seun Oloketuyi to jẹ Olootu itan naa ba BBC sọrọ lori idi pataki ti wọn fi pinnu lati ṣe agbẹkalẹ sinima naa.

Aworan

Ninu alaye rẹ, o nnkan ti oun ri ti o fi pinnu lati ṣe sinima naa pọ sugbọn pataki ibẹ ni lati fun awọn ọmọde to fẹran lati ma wo ere sinima ni anfani lati mọ nipa itan Ilẹ Yoruba.

“Awọn ọmọ ta ni nisinyi, wọn ko mọ itan, awọn nnkan to ti sẹlẹ, pupọ ninu wọn ni wọn ko fẹran lati ma kawe ṣugbọn wọn fẹran idaraya.”

Sola Sobowale ti oun naa jẹ ọkan lara awọn oṣere to kopa ninu ere naa ni inu oun dun pupọ lati ṣe iya Ọba ninu sinima nitori eeyan nla ni oun fẹ jẹ iya rẹ.

O sapejuwe Awujale gẹgẹ bi awukọsẹ rere ti yọ ki ọpọ mọ nipa rẹ, ki wọn si kọ ọgbọn pupọ.

Antar Laniyan ni oun ka ara oun gẹgẹ bii olorire eeyan fun anfani to ni lati ṣe Awujale ninu ere sinima.

E wọ fonran yii lati mọ si nipa bi wọn ṣeeṣe agbekalẹ sinima naa.