Kí ló dé tí Funke Akindele ń bomi lójú lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án lórí ikú òṣèré Jumoke Aderounmu?

Oríṣun àwòrán, FUNKE AKINDELE/INSTAGRAM JUMOKE ADEROUNMU/FACEBOOK
Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà nnì, Funke Akindele ti sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn tí àwọn kan fi ń kàn-án lẹ́yìn ìpapòdà òṣèré kan tó bá a ṣeré rí, Jumoke Aderounmu.
Ìròyìn tó gba orí ayélujára lẹ́yìn tí òṣèré náà jáde láyé ni pé, àwọn ẹbí Jumoke kàn sí Funke Akindele lásìkò tó wà lórí ìdùbúlẹ̀ àárẹ̀ àmọ́ Funke Akindele kò dìde ìrànwọ́ sí wọn.
Àmọ́ nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ Instagram rẹ̀ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹrin ọdún 2024, Funke ní òun kò gbọ́ pé Jumoke wà lórí àárẹ̀ títí ti ọlọ́jọ́ fi dé ba.
Funke Akindele ní òun kò bá má fèsì sí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi ń kan òun àmọ́ ọ̀rọ̀ tí ṣnìkan sọ sí òun lọrí ayélujára lórí ikú náà ló jẹ́ kí òun fèsì.
Ó ní èèyàn kan ní òun máa fi ọwọ́ gbé ọmọ sin tí òun sì rò pé ọ̀rọ̀ náà ti pọ̀ jù fún òun lórí ohun tí òun kò mọwọ́ mẹsẹ̀ níbẹ̀.
Jumoke tó gbajúmọ̀ fún ipa tó kó nínú sinimá Jenifa’s Diary tí Funke Akindele ṣe dágbére fáyé lọ́jọ́ Kẹfà, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 lẹ́ni ogójì ọdún.
Àbúrò olóògbé, Adeola Aderounmu tó fìdí ìkú Jumoke múlẹ̀ lórí Instagram tí ọ̀pọ̀ àwọn òṣèré tó fi mọ́ Funke Akindele sì kẹ́dùn òṣèrébìnrin tó jáde láyé náà.
Àmọ́ ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn tí Funke Akindele kọ ránṣẹ́ kò tẹ́ ẹ̀gbọ́n Jumoke lọ́rùn bí ó ṣe fẹ̀sùn kan Funke Akindele pé kò fi ìfẹ́ hàn sí Jumoke nígbà tó wà láyé, tó wà lórí àárẹ̀.
Ó ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jumoke kàn sí Funke Akindele láti bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ àmọ́ tí Funke kò da lóhùn àti pé ó tún rán èèyàn kan tó ń jẹ́ Pascal sí Funke Akindele àmọ́ síbẹ̀ kò da lóhùn.
Èyí ló nú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa bu ẹnu àtẹ́ lu Funke Akindele lórí ayélujára pé kìí ran àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tó bá wà nínú ìṣòro lọ́wọ́.
Èyí sì ló fà á tí Funke náà fi jáde láti fọ ara rẹ̀ mọ́.

Oríṣun àwòrán, ADEOLA ADEROUNMU/INSTASTORY

Oríṣun àwòrán, ADEOLA ADEROUNMU/INSTASTORY
Inú mi kò dún sí gbogbo nǹkan tí mò ń rí – Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, FUNKE AKINDELE/INSTASTORY
Funke Akindele nínú fídíò kan lórí Instagram ló ti bú sẹ́kún gbargada, tó sì ṣàlàyé òun tó da òun àti Jumoke pọ̀.
Ó ní òun ń ṣe fídíò nítorí ọ̀rọ̀ náà la ẹ̀mí èèyàn lọ àti pé inú òun kò dùn nípa àwón nǹkan tí òun ń rí àti èyí tí òun gbọ́ láti ìgbà tí Jumoke ti jáde láyé.
Ó ní òun tó da òun àti Jumoke pọ̀ kò kọjá iṣẹ́, tó òun ṣe fíìmù Jenifa’s Diary àti Industreet, tí òun sì san owó rẹ̀ fun, tí oníkálukú sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.
Ó ṣàlàyé ọkàn òun kàn fà sára Jumoke lẹ́nu ọjọ́ mélòó kan, òun sì pe Jide Awobona, òṣèré tí wọ́n jọ máa ń sọ̀rọ̀ dada pé ṣe ó gbọ́ nǹkankan láti ọ̀dọ̀ Jumoke, tí Jide sì ní ó ní kí òun pé tí iṣẹ́ bá ti wà.
“Mo ní mà á pé tí iṣẹ́ bá ti wá àmọ́ mi ò ti pesè fíìmù kankan lẹ́yìn A Tribe called Judah ni mi ò ṣe ránṣẹ́ pè é.
“Mi ò gbọ́ nǹkankan pé ó ń ṣe àárẹ̀, tí mo bá mọ̀ ni mà á tì kàn si láti ṣe ìrànlọ́wọ́ kan tàbí òmíràn fun.”
Bákan náà ló fi kun pé lẹ́yìn tí òun gbọ́ pé Jumoke jáde láye , òun kàn sí àbúrò rẹ̀ tó fi ìròyìn sórí ayélujára àmọ́ kò fún òun ní èsì kankan.
Ta ni Jumoke Aderounmu?

Oríṣun àwòrán, JUMOKE ADEROUNMU/FACEBOOK
Adeola Aderounmu tó jẹ́ àbúrò Jumoke Aderounmu ló fi ìkéde ikú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ síta lórí Instagram.
Níbẹ̀ ló ti kọ àkọ́lé pé òun ní ìgbàgbọ́ pé ẹ̀gbọ́n òun ti wà ní ààyè tó da báyìí.
Jumoke tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Esther fún ipa tó kó nínú sinimá Jenifa’s Diary jáde láyé lọ́jọ́ Kẹfà, oṣù Kẹrin ọdún 2024 lẹ́ni ogójì ọdún.
Àwọn ẹbí rẹ̀ ní àwọn ti ṣe ìsìn ìkẹyìn fún Jumoke ní ilé ìjọsìn Owu Baptist Church ní agbègbè Totoro, Abeokuta, ìpínlẹ̀ Ogun.
Ní ọdún 2016 ló di ìlú mọ̀ọ́ká lẹ́yìn tó kópa nínú Jenifa’s Diary àmọ́ ó ti kópa nínú àwọn eré bíi Arugba, Alakada, Gone àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ṣáájú àkókò náà.
Ọ̀pọ̀ àwọn òṣèré bíi Mary Njoku, Adeyemi, Jide Awobona, Wunmi Toriola ló dárò ikú rẹ̀.
Ìkéde ikú Jumoke ló ń wáyé lásìkò tí àwọn èèyàn ṣì ń ṣe àfẹ́kù Sisi Quadri àti Mr Ibu tó dágbére fáyé láìpẹ́ yìí.

Oríṣun àwòrán, Funke akindele/Instastory

Oríṣun àwòrán, JIDE AWOBONA/INSTASTORY















